Wo nkan márùn-ún tó yẹ kóo mọ̀ nípa oṣù Ramadan

Aworan olujọsin musulumi

Oríṣun àwòrán, Anadolu Agency

Gbogbo wa la mọ pe ọgbọn ọjọ gbako ni awẹ Ramadan fi ma n waye, eyi to mu ki eto jijẹ ati mimu jẹ pataki ninu osu naa.

Kii kan ṣe ounjẹ lasan, o sẹ koko lati jẹ ounjẹ ati mu omi lọna to yẹ, to si ba agọ ara mu, ki okun le wa fun awẹ gbigba.

BBC Yoruba ṣe akojọpọ awọn nnkan marun un to ṣ pataki lati mọ lasiko oṣu oloore yii fun awọn Musulumi.

Àwọn iròyin tì ẹ lè ní ìfẹ̀ síí:

Kii kan ṣe ounjẹ lasan, o sẹ koko lati jẹ ounjẹ ati mu omi lọna to yẹ, to si ba agọ ara mu, ki okun le wa fun awẹ gbigba.

1. Oriṣi ounjẹ meji ni jijẹ lasiko awẹ Ramadan, lojoojumọ.

Awọn ounjẹ naa ni wọn n pe ni Suhoor (Yoruba n pe ni Saari), ati Iftar (Iṣinu) ni irọlẹ. Ounjẹ fun Suhoor gbọdọ jẹ eyi to le fun ọ ni okun lati owurọ di irọlẹ ti iṣinu yoo waye.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

2. Awọn nkan to le mu ki eyan ja awẹ rẹ

Lasiko awẹ Ramadan, dandan ni fun awọn Musulumi lati yago fun jijẹ ati minu, to fi mọ awọn nkan faaji lati aarọ di irọlẹ. Ṣugbọn ṣa, eeyan le ja awẹ rẹ nitori awọn idi kan.

Gẹgẹ bi akọsilẹ ninu Kuraani, awọn to ba ni aisan to si nilo ki wọn o lo oogun, awọn arugbo, awọn to wa lẹnu irinajo, alaboyun, obinrin to n fun ọmọ ni ọyan, to fi mọ awọn ọmọde ti ko tii balaga, le yàn lati ma gba awẹ – paapaa to ba le ni ipa ti ko dara lori ilera wọn.

Bakan naa ni obinrin le ja awẹ rẹ ti nkan oṣu rẹ ba bẹrẹ.

Awọn ti ọrọ kan si le pada gba awọn ọjọ awẹ ti wọn padanu lọjọ iwaju.

3. Ilana ti awọn Musulumi n gba ṣinu yatọ ni orilẹ-ede kọọkan

Ni awọn ibi kan, aṣa wọn ni lati ṣinu ni ile olori ẹbi wọn, tabi ẹni to dagba ju ninu ẹbi.

Ounjẹ ni wọn ni awọn kan fi ma n ṣinu. Ṣugbọn, ni awọn orilẹ-ede bi UAE, ounjẹ onipele mẹta tabi ju bẹ lọ ni wọn fi n ṣinu.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

4. Oṣu Ramadan gbajumọ gẹgẹ bi oṣu ọlọrẹ

Lasiko yii, ọpọ Musulumi lo ma n ṣe iṣẹ aanu ati itanilọrẹ bi fifun awọn ti ko ni, ni ounjẹ ati owo.

Igbesẹ yii, Zakat, jẹ ọkan lara opo marun-un to gbe ẹsin Islam duro.

5. Ọdun itunu awẹ, Eid, lo ma n gbẹyin Ramadan

Eid al-Fitr, to tumọ si itunu awẹ, tabi ase iṣinu awẹ, ma n waye fun ọjọ mẹta to kẹhin awẹ Ramadan.

Ni kete ti wọn ba ti ri oṣu tuntun loju ọrun ni itunu awẹ ma n bẹrẹ.

Eyi to mu ki ọjọ itunu yatọ lati orilẹ-ede kan, si orilẹ-ede miran ni agbaye, botilẹ jẹ pe kii ju ọjọ kan si meji to ma n wa larin wọn.