Afenifere ń gbèrò láti dá ẹgbẹ́ òṣèlú sílẹ̀, àgbà Yoòbá kan ní àbùkù ni yóò gbẹ̀yìn rẹ̀

Ayo Adebanjo ati Kunle Olajide

Oríṣun àwòrán, Ayo Adebanjo and Kunle Olajide

Ẹgbẹ́ Afenifere ilẹ̀ Yorùbá ti kéde èròńgbà rẹ̀ láti dá ẹgbẹ́ òṣèlú sílẹ̀ ṣaájú ètò ìdìbò gbogbogboò ọdún 2023.

Ẹgbẹ́ náà sọ èyí ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun, níbi ìpàdé ẹgbẹ́ náà tó wáyé ní Sanya Ogbo, Ìjẹ̀bú-Òde, ìpínlẹ̀ Ogun.

Nígbà tó ń bá àwọn akòròyìn sọ̀rọ̀ lẹ́yìn ìpàdé náà, adelé adarí ẹgbẹ́ Afenifere, ni Olóyè Ayo Adebanjo ti kede idasilẹ ẹgbẹ oselu tuntun naa.

Amọ kò tíì fi orúkọ tí wọn yóò pe ẹgbẹ́ òṣèlú náà léde.

Ki lo de ti Afenifere fẹ da ẹgbẹ oselu silẹ?

Nigba to nsalaye idi ti wọn se fẹ gbe igbesẹ naa, Adebanjo ní àwọn kò rí ìwúrí kankan lọ́wọ́ yíì láti kópa níbi ètò ìdìbò gbogbogboò.

O ni àyàfi tí àtúnṣe bá wáyé lórí ìwé òfin, tí wọ́n sì ṣe àtúntò orílẹ̀ èdè yíì nikan ni ọna abayọ.

“A ṣì máa fẹnukò lórí bóyá a máa kópa tàbí a kò ní kópa níbi ètò ìdìbò tó ń bọ̀. Ṣùgbọ́n a ti ń kó ẹgbẹ́ jọ. A kò ní ṣe àtìlẹyìn fún ẹnikẹ́ni”

“Mi ò ní ìgbàgbọ́ nínú ètò ìdìbò tó ń bọ̀ àyàfi tí àyípadà bá bá ìwé òfin.”

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ẹ tu Sunday Igboho silẹ ni ọgba ẹwọn Cotonou, kii se ọdaran:

Bakan naa, ẹgbẹ́ Afenifere ti rọ ìjọba àpapọ̀ láti jíròrò pẹ̀lú ìjọba orílẹ̀ èdè Benin Republic láti wá ọ̀nà tí Sunday Adeyemo tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn mọ̀ sí Sunday Igboho, yóò fi kúrò ní àhámọ́ tó lẹ́yẹ ò sọkà

Afenifere ni Sunday Igboho kìí ṣe ọ̀daràn, nitori naa lo se yẹ ki wn tu silẹ.

O ni o tun yẹ kí ìjọba san bílíọ̀nù márùn ún tí ilé ẹjọ́ kan ní ìlú Ibadan ti pasẹ ṣaájú pe ki ijọba san fun Igboho lori ìkọlù tí wọ́n ṣe sí ilé rẹ̀ .

Bákan náà ló fi kun pé ìjà ìlú ni Sunday Igboho àti Nnamdi Kanu ń jà tì kò sì yẹ kí ìjọba máa ṣe wọ́n gẹ́gẹ́ bí ọ̀daràn.

Awọn koko ọrọ miran ti ẹgbẹ Afenifere tun fẹnuko le lori nibi ipade wọn ree:

  • Afenifere ní ìgbàgbọ́ pé àtúntò orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ṣì ṣeéṣe kí ètò ìdìbò ọdún 2023 tó wáyé.
  • Ki ìjọba ṣe àmúlò àbọ̀ àpérò ọdún 2014 àti àbájáde ìgbìmọ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú APC ti Mallam El-Rufai tọdún 2018.”
  • A fẹ ki Ààrẹ Muhammadu Buhari ṣe ìdásílẹ̀ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ lójúnà à ti wá ojútùú sí ètò ààbò tó ti mẹ́hẹ ní orílẹ̀ èdè yìí.
  • Ipa tí Amotekun pẹ̀lú àjọ̀ṣepọ̀ àjọ ọlọ́pàá ń kó kò kéré rárá léyìí tó fojúhaǹ pé ìdásílẹ̀ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ yóò so èso rere fún ètò ààbò orílẹ̀ èdè yìí.
  • Wọ́n rọ ìjọba àpapọ̀ láti gba àwọn ìpínlẹ̀ láàyè láti ṣe ìdásílẹ̀ àwọn ọlọ́pàá ìpínlẹ̀, kí wọ́n sì fún wọn ní gbogbo agbára láti ṣiṣẹ́ fún ra wọn.
  • Kí ìjọba àpapọ̀ ró àwọn ológun lágbára nípa owó àti ohun èlò tí wọ́n nílò láti lè kojú àwọn agbéṣùmọ̀mí kí ètò ààbò tó mẹ́he ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà le padà bọ̀ sípò.
  • Ètò ààbò tó mẹ́hẹ ló ṣokùnfà àìrajaja ètò ọrọ̀ ajé ní orílẹ̀ èdè yìí, fún ìdí èyí, ìjọba gbọ́dọ̀ jí gìrì sí ojúṣe rẹ̀.
  • Kí ìjọba ṣe àgbédìde àwọn ilé ìfọpo tó wà nílẹ̀ tàbí kọ́ tuntun dípò gbígbèrò láti yọ ìkúnpá orí epo bẹntiróòlù.
  • Ìjọba nílò láti ṣe àtúntò orílẹ̀ èdè Nàìjíríà kí ètò ìdìbò ọdún 2023 tó wáyé nípa ṣíṣe àmúlò ìjábọ̀ àpérò ọdún 2014 (CONFAB) àti àbájáde ìgbìmọ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú APC ti Mallam El-Rufai tọdún 2018.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Idasilẹ ẹgbẹ oselu yoo ko abuku ba Afenifere, atọna lo yẹ ko jẹ fáwọn olóṣèlú – Kunle Olajide

Èèkan kan nínú ẹgbẹ́ Afenifere, Dókítà Kunle Olajide ti ní kò yẹ kí Afenifere máa dá sí òṣèlú bíkòṣe láti máa jẹ́ atọ́nà fún àwọn olóṣèlú.

Dókítà Olajide fi èrò yìí hàn nígbà tó ń bá BBC Yoruba sọ̀rọ̀ lórí ìròyìn tó gbòde pé ẹgbẹ́ Afenifere ń gbèrò láti dá ẹgbẹ́ òṣèlú sílẹ̀ ṣaájú ètò ìdìbò ọdún 2023.

Olajide, ẹni to ni oun ko si nibi ipade ti wọn ti se ipinnu nipa idasilẹ ẹgbẹ oselu tuntun naa ni ka ni oun bawọn peju sibi ipade naa ni, ero toun ko ba tako erongba wọn naa.

O ní dídá ẹgbẹ́ òṣèlú sílẹ̀ yóò fa àbùkù fún Afenifere nitori ipa tí ẹgbẹ́ náà ń kó lori agbelarugẹ asa, ìṣe àti àwọn ìwà tó le mu kí ìlọsíwájú bá àwùjọ ko kere.

Ó fi kun pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí nǹkankan tí òun le ṣe sí ìpinu adarí ẹgbẹ́ náà ṣùgbọ́n kò dùn mọ́ òun pé Afenifere fẹ́ dá ẹgbẹ́ òṣèlú sílẹ̀.

“Èmi ò rò pé ó le kó ipa kankan lórí ètò ìdibò tó ń bọ̀ nítorí gbogbo ènìyàn ló mọ Afenifere mọ́ Yorùbá bí wọ́n ṣe mọ Ohaneze mọ́ Igbo.”

“Kò sí ènìyàn tó le fi ipa mú ẹnì kan pé ibí ni kó dìbò sì í”

Bákan náà ló ti pẹ́ jù pẹ̀lú bí ó ṣe ku ọdún kan sí ètò ìdìbò tí wọn kò sì tíì mọ orúkọ tí wọ́n fẹ́ sọ ẹgbẹ́.

Àwọn adarí ẹgbẹ́ Afenifere káàkiri ilẹ̀ Yorùbá tó fi mọ́ ìpínlẹ̀ Delta, Kwara àti Kogi ló kópa níbi ìpàdé náà.