Ìgbẹ́jọ́ Baba Ijesha forí sánpọ́n, agbẹjọ́rò rẹ̀ kò yọjú sílé ẹjọ́

Baba Ijesha nile ẹjọ lonii

Igbẹjọ gbajugbaja oserekunrin, Olanrewaju Omiyinka ti awọn ololufẹ rẹ mọ si Baba Ijesha ko lọ bo ṣe yẹ lonii.

Eyi ko ṣẹyin bi àwọn agbẹjọro to ti n soju rẹ tẹlẹ ko se wa sile ejọ.

Aago mọkanla kọja isẹju meji owurọ ni adajọ pe ejọ naa.

Ọjọ kẹrinla osu Kejila, ọdun 2021 ni igbẹjọ waye kẹhin lori ẹ̀sùn fifi ipa ba ọmọde lo pọ ti wọn fi kan Baba Ijesha.

Nibi ijoko ile ejọ to waye lonii, ẹni to fi ẹ̀sùn kan Baba Ijesha, Arabinrin Damilola Adekoya, taa tun mọ si Princess Comedianne ko wa sile ẹjọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Agbẹjọro tuntun soju fun Baba Ijesha, o n rawọ ẹbẹ niwaju adajọ:

Nigba to n sọ̀rọ̀ niwaju ile ejọ, agbẹjọro tuntun to soju Baba Ijesha, Ogbẹni A. O Ajulọ bẹ ile ẹjọ lati tun sun igbẹjọ si ọjọ miran.

Alaye to ṣe ni pe oun ko mọ nkan pupọ nipa ẹjọ ti Baba Ijesha n jẹ lọwọ.

O ni awọn agbẹjọro rẹ lo ran oun lati soju rẹ nitori pe isẹ miran ko jẹ ki wọn o raaye wa.

Bakan naa lo sọ pe ko tii si ẹlẹri miran fun Baba Ijesha yatọ si olujẹjọ funra rẹ.

Adajọ koro oju si ẹbẹ agbẹjọro Baba Ijesha lati sun ẹjọ siwaju:

Adajọ to n gbọ ejọ naa, Onidajọ Oluwatoyin Taiwo sọ pe nkan to buru jai ni bi Agbẹjọro Ajulo ṣe fẹ ki oun sun ejọ siwaju.

O ni “pe o jẹ ajoji ninu ejọ yii kii ṣe awawi to nitumọ.”

O ni igbẹjọ naa yoo si tẹsiwaju, nitori awọn ko le tẹsiwaju lati ma a fi ejọ naa falẹ.

Ṣugbọn lẹyin o rẹyin, o ni ki awọn agbẹjọro mejeeji fi ori kori.

Lẹyin apero ti Amofin Ajulọ ṣe pẹlu agbẹjọro ijọba, ti awọn mejeeji si faramọ pe ki adajọ sun igbẹjọ siwaju, adajọ Oluwatoyin Taiwo sun igbẹjọ Baba Ijesha si ọjọ kẹtadinlogun ati ọjọ Kejidinlogun, oṣu Keji.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ki lo ti ṣẹlẹ siwaju?

Ọjọ́, oṣu Kẹrin, ọdun 2021 ni ọwọ tẹ Olanrewaju Omiyinka ni ile gbajugbaja apanilẹrin, Arabinrin Damilola Adekoya ti awọn eeyan mọ si Princess Comedian.

Ẹ̀sùn ti wọn fi kan Omiyinka ni pe o fi ipa ba ọmọdebinrin kan, ọmọ ọdún mẹrinla lopọ ninu ile naa.

Alagbatọ ni Princess jẹ fun ọmọ naa.

Princess sọ pe Baba Ijesha ti kọkọ ni ibalopọ pẹlu ọmọ naa nigba to wa ni ọmọ ọdun meje.

Eyi si lo mu ki wọn o dẹ panpẹ fun un pẹlu ẹ̀rọ ayaworan CCTV, ni oṣù Kẹrin, ọdun 2021.

Ẹ̀rọ ayaworan ọhun lo safihan bi Ijesha ṣe n gbiyanju lati ni ibalopọ pẹlu ọmọde naa.

Awuyewuye ati iwọde waye lori ọrọ naa, ti awọn kan fi n ṣe atilẹyin fun Baba Ijesha. Bẹẹ ni awọn kan naa ṣe ti wọn pe idajọ ododo gbọdọ waye.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Bawo ni igbẹjọ ṣe bẹ̀rẹ̀?

Ile ejọ Majisireti kan ni adugbo Yaba ni wọn kọ́kọ́ gbe Ọgbẹni Omiyinka lọ.

Lẹyin naa ni wọn gbe ejọ ẹ̀sùn naa lọ si ile ejọ akanse fun awọn ẹ̀sùn ara ọtọ, Special Offences Court, to wa ni Ikeja.

Ọjọ́ kẹrinla, osu Karun-un, ọdun 2021 ni ile ejọ gba beeli Baba Ijesha pe ko ma a gba ile rẹ wa jẹjọ. Sugbọn ko kuro ni ahamọ titi di ọjọ kẹrinlelogun, oṣù Kẹfà, nitori ko tete yanju awọn nkan ti ile ejọ n fẹ.

Àwọn agbẹjọro ijọba lo rojọ tako Baba Ijesha ni gbogbo igba ti igbẹjọ fi waye lọdun 2021.

Wọn pari awijare wọn ni osu Kejila.

Lara awọn to jẹri tako o ni onimọ ilera ọpọlọ to fi ọ̀rọ̀ wa ọmọdebinrin naa lẹnu wo, ọlọpaa to rojọ mu Baba Ijesha, ati dokita to ṣe ayẹwo oju ara ọmọ naa.

Iwa ifipabanilopọ lagbara pupọ ni abẹ ofin orilẹ-ede Naijiria.

Àwọn ipinlẹ bi Ekiti tilẹ ṣe ofin to ma n mu ki wọn o fi aworan ẹni to ba fi ipa ba eeyan lopọ han gbogbo ayé.