Kí ló dé tí ológun ń yẹ àga ìjọba mọ́ alágbádá nídìí l‘Áfíríkà?

Nigeria Army

Oríṣun àwòrán, @DefenseNigeria

Asa ki awọn ologun maa ditẹ gba ijọba tun ti n pada si ilẹ adulawọ nitori o ti di orilẹede mẹrin nilẹ Afirika bayii tawọn ologun ti ditẹ gba ijọba laarin ọdun kan soso.

Orilẹede Sudan, Mali, Guinea ati Burkina Faso, ti gbogbo wọn wa nilẹ Afirika ni awọn ologun ti yẹ aga mọ awọn aarẹ wọn nidii, ti wọn si gba akoso ijọba nibẹ.

Irufẹ iwa yii ni ko sẹlẹ mọ rara ni awn orilẹede to ti goke agba ni agbaye nibi ti isejọba oselu awa ara wa ti n ri ẹsẹ walẹ.

Eyi si lo mu ki awọn eeyan kan maa beere pe ki lo de to se jẹ pe ilẹ Afirika nikan ni awn ologun tun ti n gbemu wọ inu akoso ijọba, ki lo fa, ẹbi ta ni ati pe ki ni ọna abayọ si iwa ailaju yii.

Idi ree ti BBC Yoruba fi kan si onimọ kan nipa eto oselu lati wa idahun si awọn ibeere naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ki lo de ti ologun se n yẹ aga akoso mọ awọn aarẹ alagbada nidi nilẹ Afirika?

Nigba to n dahun ibeere yii, agbẹjọro kan to tun jẹ ajafẹtọ ọmọniyan ati onwoye ohun to n lọ lagbaye, Dele Farotimi ni ẹnu awọn araalu ko ka awọn adari ijọba alagbada mọ, lo mu ko rọrun fun awọn ologun lati yọju.

Farotimi ni ọrọ yii naa lo tun jade lẹyin ti awọn ọmọ ogun ditẹgbajọba ni orilẹ-ede Burkina Faso, eyi ti awọn araalu n dunnu si.

Farotimi sọ pe ti ẹnu awọn araalu ko ba ka ijọba mọ, awọn ologun nikan ni wọn tun le gbọrọ si lẹnu.

O ni “Ti araalu ba n ba ijọba sọrọ ti wọn ko gbọ, awọn to n gbe ibọn naa le lo ba wọn sọrọ nitori alagidi naa lo le ṣe ọrẹ alagidi.

Farotimi fikun pe ede tawọn aarẹ alagbada gbọ ni wọn n ba ara wọn sọ amọ awọn araalu naa lo maa jẹ iya rẹ.”

Bi araalu ba fẹ ijọba kan lori oye, ko si ologun to le yẹaga nidi rẹ:

“Ti araalu ba fẹ ijọba kan lori oye, ko si ologun kankan to le rọ irufẹ ijọba bẹẹ loye, ti ologun ba rọ ijọba loye, awọn araalu yoo gba ijọba bẹẹ pada gẹgẹ bo ṣe ṣẹlẹ ni Turkey ni nnkan bii ọdun mẹjọ sẹyin.”

“Ṣugbọn nigba to ba di pe ọba ti tẹ niluu, to ti di ẹni ti wọn fẹ fi orò le lọ tẹlẹ, araalu ko le ja fun irufẹ ijọba bẹẹ, ti ijọba ko ba tii tẹ, iru rẹ ko le ṣẹlẹ.”

Nigba to n sọrọ lori awọn orilẹ-ede kan ti awọn ologun kii gbajọba nibẹ, Farotimi sọ pe ẹnu araalu rinlẹ lawọn irufẹ orilẹ-ede bẹẹ ni.

O ni o di dandan ki awọn ologun gbajọba to ba jẹ tipatipa ni wọn fi n gbe aarẹ alagbada kan le awọn araalu lori ni irufẹ orilẹ-ede bẹẹ.

Ọna lati dena iditẹ gbajọba:

Farotimi sọ pe ti awọn ijọba orilẹ-ede Afrika ba fẹ lati dena iditẹ jọba, wọn ni lati mọ pe nitori awọn araalu ni awọn ṣe wa ni ijọba.

O ni ti wọn ba ti gbagbe awọn araalu ni kete ti wọn ba ti de ori alefa tan, ilu bẹẹ ko ni toro.

O wa pari ọrọ rẹ pe “Ilu ti ẹ ba ti ri pe ologun n gbajọba, ilu bẹẹ jina si ilọsiwaju ni.”

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ