Ọwọ́ Biola Fowosere tẹ afurasí olè tó kó fóònù àti owó rẹ̀

Biola Fowosere

Ọjọ gbogbo ni ti ole amọ ọjọ kan soso pere ni ti olohun.

Biola Fowosere, osere tiata ti ọpọ ènìyàn tun mọ̀ sí Ewatomilola Asake, ti safihan oju afurasi ole kan to wọ inu sọọbu rẹ lati gbe owo ati foonu.

Laipẹ yii ni Fowosere da omi loju lori oju opo ikansiraeni Instagram rẹ lati sọ ẹdun ọkan rẹ nipa awọn to n ja lole lati igba de igba.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gẹgẹ bi Biola ti wi ninu fidio naa to fi omije se, o ni ti oun ba ti ko ọja sinu sọọbu naa, to kun de ẹnu, ni awọn kan yoo wa ja sọọbu naa, ti wọn yoo si ko ọja inu rẹ lọ.

O fikun pe eyi ti sọ oun di onigbese, ti wọn ko si fẹ ki oun ba ẹgbẹ pe.

Amọ ọwọ palaba ọkan ninu awọn to n gbe okunkun sisẹ ibi naa ti ṣegi, ti ọwọ si ba a nibi ti o ti n ji apo owo osere tiata naa ati foonu rẹ ninu sọọbu itaja rẹ.

O salaye pe ko pe isẹju meji ti oun lọ sile igbọsẹ lati sẹyọ, ni wọn ti gbe apo oun ti ọpọ owo ati foonu wa ninu rẹ.

Osere tiata naa wa rọ awọn eniyan ti wọn sa wa sibẹ lati wa lu ole naa pa, pe ki wọn jẹ ko fi oju wina ofin ni, ki wọn si mase se idajọ lọwọ ara wọn.

Bakan naa lo fikun pe ole naa ko wa ra nkankan ninu ṣọọbu rẹ, n ṣe lo wa ji awọn ẹru to wa ninu ṣọọbu oun.

”Ẹ jọwọ ẹ ma lu u pa o, ẹ fi silẹ nitori ole lo wa ja ni ṣọọbu mi.”

”Baagi owo mi lo gbe, to si ko gbogbo foonu mi laarin iṣẹju meji ti mo sare lọ gbọnṣẹ lẹyinkule.”

Laipẹ yii lo ke gbajare si gbogbo ọmọ Naijiria lati gba oun lọwọ awọn ole to n ja ṣọọbu oun ni gbogbo igba.

Fowosere salaye nigba naa pe, igba kẹta ni yii ti wọn n ja ṣọọbu oun laarin ọdun kan.

” Ní ọdún tó kọjá, wọ́n ji aṣọ tó tó Mílíọ̀nù kan àbọ̀ náírà sùgbọ́n títí dí òní mí o rí nǹkan kan”

Amọ o fikun nigba naa pe awọn kan ko gbagbọ wi pe otitọ ni wọn ja oun lole, ko to di pe o fi fidio yii sita.

Gbajugbaja oṣere naa dupẹ lọwọ awọn eniyan to ran an lọwọ to si duro tii, bi o tilẹ jẹpe awọn ọlọpaa kọ lati ṣe ohunkohun si ọrọ ole ojoojumọ naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ