Ìjọba ẹ má wòran, àjà ilé Aṣòfin tó ń jò le wó lé wa lórí – Aṣòfin sọ̀rọ̀ ṣókè!

Omi to n jo

Oríṣun àwòrán, NAtional Assembly

Adari awọn ọmọ ile Aṣofin to kerejulo, Ndudi Elumelu ti kegbare pe ẹmi awọn wa ninu hila hilo pẹlu ile aṣofin to n jo le wọn lori ni gbogbo igba.

Elumelu to wa lati ẹgbẹ oṣelu PDP ni omi to n jo ni gbogbo igba le wọn lori fihan pe aja Ile Aṣofin ti baje, ti o si le wo nigba kugba.

O ni o lewu ki awọn aṣofin ma a ṣepade ijoko ile ni iru agbegbe bẹẹ lai naani ẹmi wọn to wa ninu ewu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Adari awọn ọmọ ile Aṣofin to kere julọ naa wa kesi awọn alaṣẹ Ile Igbimọ Aṣofin lati tete wa nkan ṣe si ọrọ naa ni wara n ṣesa.

”Ohun to n ṣẹlẹ ni Ile Igbimọ Aṣofin yin n kọ mi lominu lo jẹ ki n dide sọrọ ni asiko yii.”

”Olori ile, ti ẹ ba wo yika, ẹ o ri pe omi lo yi wa ka nitori aja ile Asọfin n jo, ti a si gbọdọ wa nkan ṣe si ni kiakia, nitori ko si ẹnikẹni to le e sọ nkan to le e ṣẹlẹ.”

Ile Igbimo Asofin to n jo

Oríṣun àwòrán, Others

”Ko si igba ti a wa si ibi yii ti awọn gbalẹ-gbalẹ ko si nibẹ, ti wọn n ko omi to n jo si inu ile aṣofin, eleyii si lewu pupọ ni oju mi.”

”Ko ṣeeṣe ki a ma a ṣiṣẹ wa lojoojumọ pẹlu ojo to n rọ le wa lori yii, Abẹnugan, ẹ wa nkan ṣe si ki ọrọ to bẹyin yọ.”

Abẹnugan Ile Aṣofin nigba, Femi Gbajabiamila lasiko to n fesi si ọrọ naa ni ohun ti wọn gbọdọ mu ni ọkunkundun ni adari ọmọ ile aṣofin to kerejulọ sọ.

Igba akọkọ kọ ni yii ti Ile Igbimọ Asofin ti ma n jo loore-koore paapaa nigba ti ojo ba rọ, gbogbo agbegbe naa ni yoo kun fọfọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ