Ilé-ẹjọ́ pàṣe kí Multichoice dáwọ́ àfikún owó orí DSTV àti Gotv dúró

Aworan ileeṣẹ Multichoice

Oríṣun àwòrán, Others

Ile-ẹjọ to n ri sọrọ ifigagbaga ati aabo araalu, iyẹn Competition and Consumer Protection Tribunal (CCPT) to wa niluu Abuja ti da ileeṣẹ Multichoice Nigeria Limited lọwọ kọ lati ṣafikun lori iye owo ti awọn onibara wọn yoo maa san.

Eyi ti wọn fẹẹ bẹrẹ lọjọ kinini, oṣu karun un, ọdun 2024.

Nibi igbẹjọ ọhun to waye lọjọ Aje to kọja ni igbimọ onidajọ ẹlẹni mẹta ti Saratu Shaffi lewaju rẹ ni wọn ti paṣẹ pe ki ileeṣẹ Multichoice ṣi gbagbe nipa wi pe wọn fẹẹ fi owo kun owo ti awọn onibara wọn n san lori awọn ikanni DStv ati Gotv wọn.

Ile-ẹjọ sọ pe o digba ti awọn ba pari igbẹjọ naa, ki awọn to le gbe idajọ kalẹ boya DStv yoo ṣafikun tabi gbagbe nipa fifi owo kun owo ori awọn ọja wọn.

Ta lo pe DSTV lẹ́jọ́?

Ẹnikan ti wọn pe orukọ rẹ ni Festus Onifade lo pe ẹjọ ọhun, ti Ejiro Awaritoma to jẹ agbẹjọro rẹ si gbe e lọ siwaju ile-ẹjọ, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.

Bakan naa ni ile-ẹjọ tun sọ pe ki olupẹjọ ati olujẹjọ yọju siwaju ile-ẹjọ lọjọ keje, oṣu karun-un ni deedee agogo mẹwaa owurọ lati gbọ ẹjọ ọhun siwaju, ko to di pe wọn mọ igbesẹ to kan.

Bi ẹ ko ba gbagbe, lọjọ kinni, oṣu kẹrin, ọdun 2022 ni ileeṣẹ naa kede afikun lori awọn itakun wọn, ti wọn si ti ṣe bẹẹ fun bii igba mẹta ọtọọtọ ko to to asiko yii.

Ninu ẹjọ ti Onifade pe lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu karun-un, o n beere fun pe ki ile-ẹjọ da ileeṣẹ naa lọwọ kọ lati ma ṣe tẹsiwaju ninu afikun owo ori awọn ikanni wọn naa, eyi ti yoo bẹrẹ lọjọ kinni, oṣu karun-un, titi digba ti igbẹjọ yoo fi waye.

Kí ló kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn?

Multichoice kéde àfikún owó orí DStv, GOtv

Aworan

Oríṣun àwòrán, other

Ileeṣẹ Multichoice ti kede ẹkunwo awọn ileeṣẹ mohunmaworan agbelewo DSTV ati Gotv.

Ninu atẹjade kan ti wọn fi sita pẹlu akọle ‘Atunto owo ori DStv ati Gotv’, Multichoice ni bi iye owo ori awọn ohun ti wọn n lo fun iṣẹ wọn ṣe n gbowo lori sii lo mu ki awọn pẹlu ṣe afikun owo ori awọn mohunmaworan agbelewo naa.

Gẹgẹ bi wọn ṣe sọ, ẹkunwo naa yoo bẹrẹ ni ọjọ kini oṣu karun ọdun 2024.

Aworan owo tuntun naa

Oríṣun àwòrán, bbc

Eto Premium ori DStv to jẹ ẹgbẹrun mọkandinlọgbọn ati ẹẹdẹgbẹta Naira tẹlẹ yoo di ẹgbẹrun mẹtadinlogoji Naira (N37, 000).

Compact plus to jẹ ẹgbẹrun mọkandinlogun ati ẹgbẹrin Naira (N19, 800) ti gbowolori di ẹgbẹrun marundinlọgbọn Naira (N25, 000) bayii.