Sunday Igboho kò tíì bọ́ lọ́wọ́ wa, á fi ẹ̀sùn míì kàn-án – Malami

Abubakar Malami ati Sunday Igboho

Bi ina ko ba tan lasọ, ẹj ko le tan lori eekanna.

Afaimọ ki ijọba apapọ ma tun fi ẹsun mii kan ajijagbara ilẹ Yoruba, Oloye Sunday Adeyemo, ti ọpọ mọ si Sunday Igboho.

Lọsẹ to lọ ni ile ẹjọ paṣẹ pe ki ijọba apapọ san ogun biliọnu owo gba ma binu fún Igboho lori ikọlu ti ajọ DSS ṣe sí ile rẹ, nibi ti eeyan meji ti ku ti ọpọ dukia si ṣofo.

Àmọ́, agbẹjọro agba, to tun jẹ minisita eto ìdájọ, Abubakar Malami ti sọ pé ijoba lẹtọọ lati pe ẹjọ kotẹmilọrun lori ìdájọ náà.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bakan naa ni Malami sọ pe ijọba apapọ tun fi ẹsun tuntun kan Igboho.

Adájọ Ladiran Akintola paṣẹ pe kí agbẹjọro agba Malami ati ajọ DSS san owo gba ma binu naa lẹyin ikọlu lọjọ kinni oṣu keje.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Àmọ́, Malami ni kò sì ohun ti ijọba apapọ n ṣe ti o lodi sí ofin.

“Ijọba ni ẹtọ lati sọ fun ile ẹjọ miran lati yi idajọ ile ẹjọ giga ilu Ibadan danu.

O sí tun le wu ijoba ko tun wa awọn ẹsun mii sí Igboho lẹsẹ.

Nitori naa, a n ṣe ayẹwo ẹjọ náà lọwọ láti mọ iru igbesẹ ti a fẹ gbe bayii,” Malami lo sọ bẹẹ.

Ti ẹ ko ba gbagbe, Yomi Aliyu tó jẹ agbẹjọro Igboho lo pe Malami ati ajọ DSS lẹjọ lati san ẹẹdẹgbẹta biliọnu naira fún Igboho gẹgẹ bi owo gba ma binu lẹyin ikólu DSS sí ile rẹ lagbegbe Soka niluu Ibadan.

Igboho sí wa ni atimọle lorilede Benin nibi ti wọn ti mu ùn lọnà Irinajo rẹ si orilẹ ede Germany.

Aliyu ni ile ati awọn ọkọ bọginni bọginni olowo iyebiye ni wọn bajẹ nile Igboho nibi ti wọn tun ti pa eeyan meji.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ