Mo ní ìjàmbá ọkọ̀ nígbà mọ́kànlá, mo si ro ará mi pin láyé pé ó ti parí- Adeola Testimony

Ọdọmọkunrin olorin ẹmi ti orukọ n jẹ Adeola Adeleye ti ọpọ mọ si Adeola Testimony sọ fun BBC nipa irinajo aye rẹ ati bi o ṣe pinnu lati gba ẹmi ara rẹ lẹyin to ni ijamba ọkọ mọkanla.

O ni ọpọ igba ni oun ti pinnu pe oun fẹ gba ẹmi ara oun ki Ọlọrun to gbe kongẹ Iyawo rẹ.

Testimony lati inu oyun ni ohun ti ni ipenija ẹsẹ, ti oun ko si le rin fun ọpọ ọdun.

Aworan

Oríṣun àwòrán, BBC/Others

“Lati inu oyun ni wọn ti bi mi ti mo ri bayii, gẹgẹ bi nnkan ti awọn obi mi sọ fun mi pe lọgan ti wọn bi mi, ni wọn rii pe mo ri bi mo ṣe ri yii.

“Nigba naa ni mo bẹrẹ sini dagba, mi o le fi ẹsẹ yẹn rin gẹgẹ bi eniyan,

“Bi awọn eniyan ṣe n rin, ṣugbọn nigba ti o de ipele kan, emi naa bẹrẹ sini fi ẹsẹ rin pẹlu ogo Ọlọrun.

“Bi mo si ti n dagba nigba ti mo wa ni ọmọ ọdun kẹjọ, ni mo ni ijamba akọkọ ti mo ni.

“A dupẹ lọwọ Ọlọrun, ṣugbọn bi mo tun ṣe n tẹsiwaju, mo ni ijamba ọkọ ikeji, ikẹta, ikẹrin, titi ti o fi de ori mọkanla ti mo ni, ti o jẹ eleyii ti o yẹ ki o gba ẹmi mi patapata, ṣugbọn mo dupẹ lọwọ Ọlọrun mo ṣi wa laye titi di onii.

Àwọn mọ́lẹ̀bi kò kọ́kọ́ fẹ́ kí n fẹ́ ọkọ mi nítorí ó jẹ́ abarapá ṣùgbọ́n…. ìyàwó akọrin ẹ̀mí Adeola Testimony

Iyawo olorin ẹmi Adeola Adeleye, ti ọpọ mọ si Adeola Testimony, arabinrin Deborah Adeọla Adelẹyẹ ni awọn mọlẹbi kọkọ bu ẹnu atẹlu idi ti oun fi yan abarapa layo pe oun lo wu oun lati fẹ gẹgẹ bi ọkọ.

Deborah ni oun ko fi igba kankan kabamọ pe oun fẹ Adeola Testimony.

Irinajo ifẹ Adeola Testimony ati Iyawo rẹ lo bẹrẹ lati ori ayelujara ko to di pe wọn pinnu lati ṣe ọrẹ arawọn kalẹ.

Deborah ni, “O ni aworan kan ti mo ri lorii Facebook yẹn lọjọ yẹn.

“O wu mi gan an pe ẹni ti ẹsẹ rẹ ko pe lo n yin Ọlọrun bayii, pe emi ti ẹsẹ mi si pe mi o le yin Ọlọrun.

“O jẹ nnkan to ba mi lẹru gan an, ti mo si fi titobi Ọlọrun han lati ara rẹ pe ah, ọmọkunrin yii n yin Oluwa, bẹẹ mo kan fi atẹjiṣẹ ranṣẹ sii pe ah, pe ki oore ọfẹ yẹn maa pọ sii.

“Ki o to di pe mo mu wọn lọ ile, emi gan an ti daa ro lọkan mi pe wọn ko ni gba nile wa, nitori wi pe mo mọ awọn obi ti mo ni, wọn maa ni rara, ki ni mo gbe wale.”

Àwọn afíkun lórí ìròyìn yìí