Ọ̀wọ́ngógó epo: Ìjọba Kwara bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti fi kélé òfin gbé àwọn alágbàtà tó n gbé epo pamọ́

Aworan gomina Kwara

Oríṣun àwòrán, Abdulrahman Abdulrazaq/Facebook

Ijọba ipinlẹ Kwara lọjọ Aje, ọsẹ yii ti lọ kaakiri gbogbo awọn ile-epo to wa niluu Ilọrin lati fi ọwọ ofin mu wọn, paapaa awọn ti wọn kọ lati ta epo f’awọn araalu, eyi to n fa ọwọngogo ati aisi epo rọbii.

Awọn alakoso ijọba ipinlẹ naa ṣe ikilọ fun awọn ile-epo kaakiri lati dẹkun titi ile-epo wọn pa, paapaa awọn ti wọn ni epo, ṣugbọn ti wọn kọ lati ta a sita fun araalu.

Igbimọ amuṣẹṣe ti Gomina AbdulRahman AbdulRazaq yan, eyi ti olori awọn oṣiṣẹ gomina, Ọmọọba Mahe Abdulkadir jẹ adari wọn, nigba to n sọrọ, jẹ ko di mimọ pe awọn ko le laju silẹ lati maa jẹ ki awọn elepo fiya jẹ araalu lai nidi.

Abdulkadir ni gomina n gbiyanju lati ma ṣe jẹ ki araalu jiya aimọdi, idi ree to fi gbe igbimọ dide lati ri si ọrọ ọwọngogo epo to n ṣẹlẹ kaakiri.

Ninu ọrọ rẹ, o ṣalaye pe “Ijọba to ba mọ ojuṣe rẹ ko tun nilo lati duro, ko si maa kawọ gbera lati maa wo ohun to n ṣẹlẹ niran. A ni lati rii daju pe awọn araalu jẹ mudunmudun eto iṣẹjọ awaarawa.

“A ṣakiyesi pe ọpọ awọn alagbata epo rọbii ni wọn n gbiyanju agbara wọn, nitori pe gbogbo ibi agba epo wọn la n yẹ wo lati mọ boya epo wa nibẹ.”

Bakan naa lo rawọ ẹbẹ si araalu lati ma ṣe bẹru, ati pe ki wọn ni suuru, ki wọn si ma ṣe foya lori rira epo lasiko yii, nitori pe ijọba apapọ ko ni erongba lati ṣafikun owo ori epo

Lara awọn ile-epo ti wọn lọ ṣayẹwo rẹ ni Total Energies to wa lagbegbe Post Office; Rainoil to wa lagbege Asa Dam; NNPC to wa ni Gerin Alimi; Total Energies ati NNPC to wa ni Surulere; ati MRS toun wa lagbegbe Ọja Ọba.

Nibẹ lo ti gba awọn alagbata epo lamọran lati ma ṣe gbe epo pamọ fun araalu, lojuna lati maa jẹ ki ijọba fi kele ofin gbe wọn.