Gómìnà àná Kwara, Abdulfatah Ahmed fojú ba ilé ẹjọ́ lórí ẹ̀sùn ṣíṣe owó ìlú kúmọkùmọ

Abdulfatah Ahmed

Oríṣun àwòrán, Abbdulfatahahmed/INSTAGRAM

Ile ẹjọ giga ti ijọba apapọ to kalẹ si ilu Ilọrin, olu ilu ipinlẹ Kwara N tẹsiwaju lori ẹjọ gomina tẹlẹ ri ni ipinlẹ Kwara, Abdulfatah Ahmed.

Abdulfatah Ahmed ti ọpọ mo si Maigida lo n jejọ lori ẹsun sisowo ilu to to billionu mewaa Naira mokumoku ni asiko rẹ gẹgẹ bii gomina ipinlẹ naa laarin ọdun 2011 si 2019.

Tẹ o ba gbagbe, ajọ to n gbogun ti iwa, ajẹbanu ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku, (Economic and Financial Crime Commission EFCC) lo wọ ọ lọ si ile ẹjọ lati wi tẹnu rẹ ki ofin baa le gbe igbesẹ to tọ.

Igbẹjọ lori ẹsun onigba mejila ti wọn fi kan gomina ana ọhun ti bẹrẹ lati ọjọ kẹtalelogun osu keji, ọdun 2024 sugbọn ti adajọ, Evelyn Anyadike gba beeli rẹ lodiwọn N50 million.

Àlàyé lórí bí ìgbéjó ṣe lọ

Aworan iwaju ile ẹjọ giga

Oríṣun àwòrán, Others

Nibi igbẹjọ to waye lọjọ Aje, ọjọ Kọkandinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun 20244 ni Abdulfatah Ahmed yọju sile ẹjọ pẹlu Kọmisanna fun eto isuna ni saa rẹ gẹgẹ bi gomina, Ọgbẹni Ademola Banu.

Awọn mejeeji ni wọn jọ pe lẹjọ onibeji fun sise owo ilu mokumoku.

Ademola Banu ti kọkọ kọ lati yọju sile ẹjọ nibi igbẹjọ akọkọ ti ile ejọ si kede ki ọlọpaa nawọ gan-an fun titapa sofin ile ẹjọ.

Sugbọn ile ẹjọ ti wọgile ikede naa nitori pe o pada yọju lati jẹ ẹjọ rẹ.

Gẹgẹ bi Maigida ti ṣe saaju, Banu naa sọ pe oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan ohun lẹyin naa ni ile ẹjọ gba beeli rẹ ni odiwọn milionu marun-un Naira.

Lẹyin eyi ni ile ẹjọ sun igbẹjọ si ọjọ kẹẹdọgbọn osu kẹfa