Wo Aláàfin tó bí ọmọ 1,460, ayaba mẹ́sàn-án bí ìbejì lọ́jọ́ kan ṣoṣo ní ìgbà mẹ́ta

Ade Alaafin

Oríṣun àwòrán, Alaafin

Ilu Oyo jẹ ìlú ńlá tó gbajugbaja nilẹ Yoruba, to si tun jẹ Olu ilu fun isejọba iran Yoruba laye atijọ.

Ọ̀pọ̀ Alaafin lo ti ṣe akoso ilu Oyo, ti itan ko le gbagbe wọn nitori àwọn ipa ribiribi tí wọn ko si agbega ilẹ̀ Yorùbá naa.

Ọkàn ninu awọn Alaafin yii ni Oluaso, ẹni to pẹ pupọ lori itẹ, to si ni Ayaba ati ọmọ rẹpẹtẹ.

Gẹ́gẹ́ bi iwe itan nipa Yorùbá ti Alufa Samuel Johnson kọ ti salaye, arẹwà pupọ ni Alaafin Oluaso, ti isejọba rẹ si tu àwọn èèyàn ilu Oyo lara.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Itan ni Alaafin Oluaso pẹ laye, tí iye ọdun to lo loke eepẹ yoo si to okoolelọọdunrun eyiun 320

Gẹ́gẹ́ bi a ṣe ka a ninu itan Yoruba ti Alufa Samuel Johnson kọ naa, ọmọ bibi Alaafin Kori, to wa lori itẹ laarin saa onka ọdun 1400 si 1457 sẹ́ńtúrì ni Oluaso jẹ.

Lẹyin tí Alaafin Kori waja, ni arẹmọ rẹ, Oluaso gun itẹ Alaafin laarin sáà onka ọdun 1457 si 1,500 sẹ́ńtúrì.

Ìtàn fi yẹ wa pe Alaafin Oluaso gbọn pupọ, tí isejọba rẹ si tú ni lara.

Kódà, ìtàn atẹnu-dẹnu ti ẹnikẹ́ni ko le fi idi rẹ mulẹ salaye pe Alaafin Oluaso yii pẹ laye, tí iye ọdun to lo loke eepẹ yoo si to okoolelọọdunrun eyiun 320.

Bákan naa ni àkọsílẹ̀ sọ pe Alaafin Oluaso ni aya pupọ eyi ti ko ni onka, ti àpapọ̀ iye ọmọ to bi si jẹ ẹgbẹ̀rún kan ati ọtalenirinwo (1,460).

Koda, a ri ka pe igba mẹta ni mẹsan ninu awọn Ayaba rẹ mẹsan bi ibeji ọkùnrin ní ọjọ́ kan ṣoṣo.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Alaafin Oluaso tun kọ ààfin fun ikọọkan arẹmọ rẹ mẹrinlelaadọta, tí gbogbo wọn si laami laaka lasiko rẹ.

Awọn isọri àkọ́kọ́ ibeji naa lo pe ni Ọmọla nígbà to pe awọn isọri kejì ibeji rẹ ni Ọna-aka, ti isọri kẹta si n jẹ Ọna-Isokun.

Laarin awọn isọri ibeji mẹtẹẹta Alaafin Oluaso yii, isọri kẹta, tii ṣe Ọna-Isokun lo jẹ gbajúmọ̀ julọ.

Idi si ree ti wọn ṣe n yan Alaafin laarin wọn ati iru ọmọ wọn, ṣugbọn orúkọ yii ti di oye ajẹwọ nilu Oyo lode òní.

A kà á wipe Alaafin Oluaso tun kọ ààfin fun ikọọkan arẹmọ rẹ mẹrinlelaadọta, tí gbogbo wọn si laami laaka lasiko rẹ.

Bakan naa ni Alaafin Oluaso kọ ọgọ́fà Kọ̀bì fún ìgbà àkọ́kọ́ ni ààfin Oyo.

Kabiyesi yii fi ọwọ́ pá ewú, ó fi èrìgì jẹ obì, tí irukẹrẹ si di okinni mọ lọwọ. Ó dagba, ó sì darugbo ko to waja.

Idi ree ti wọn ṣe maa n pa owe pe “O ní kí o gbó ogbó Oluaso, o kò sì le jìyà Oluaso?”

Lẹ́yìn tí Alaafin Oluaso tẹrí gba aṣọ, arẹmọ rẹ, Onigbogi lo jọba lẹ́yìn rẹ, tòun náà sì dárí ìlú Ọ̀yọ́ laarin sáà onka ọdún 1500 sí 1537 sẹ́ńturì.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ