Ọmọge tó jẹ́ akọrin ṣọ́ọ̀ṣì kú nínú ìjàmbá ọkọ̀, àṣírí bá tú pé akọ tó ń ṣe bíi abo ni

“Emmanuella já fáfá lẹ́gbẹ́ akọrin láì mọ̀ pé láì mọ̀ pe akọ tó ń ṣe bíi abo ni”

Emmanuella Adolisa

Oríṣun àwòrán, Emanuella adolisa/instagram

Awọn ọmọ ijọ Katoliiki St. John’s Catholic Church, Rumuolumeni ni Iwofe ni ilu Port Harcourt nipinlẹ Rivers lẹkun gusu Naijiria, ṣi n yanu lẹyin isẹlẹ aramnda kan to waye ninu ijọ naa.

Ọmọ ijọ naa kan, ti wọn mọ si omidan Emmanuella Adaolisa, to jẹ ọmọ ijọ wọn, ni asiri tu pe kii ṣe obinrin ati pe ọkunrin to n ṣe iṣe obinrin ni.

Awọn oṣiṣẹ ile igbokusi lo tu aṣiri yii sita nigba ti wọn fẹ bẹrẹ si ni ṣe iṣẹ itọju lara oku rẹ nigba ti alufa ijọ naa atawọn ọmọ ijọ rẹ gbe oku rẹ wa gẹgẹ bi obinrin laimọ pe ọkunrin to n ṣe iṣe obinrin ni.

Gẹgẹ bi iroyin ti a gbọ ṣe sọ, akẹkọgboye imọ nipa ogun pipo ni Emmanuella Adaolisa, ile ẹkọ giga fasiti ilu Port Harcourt lo si ti kẹkọgboye, ṣugbọn obinrin lo n pe ara rẹ fun gbogbo eniyan.

“Lọjọ ti Alufa wa gbadura lẹyin aawẹ pe ki Ọlọrun tu asiri awọn eeyan to n doju ti ijọ Katoliki ni Emmanuella ni ijamba ọkọ, to si ku”

Awọn ọmọ ijọ rẹ ko mọ eyi rara. Obinrin ni wọn mọọ si laimọ pe ọkunrin to n ṣe iṣe obinrin ni.

Awọn ọmọ ijọ naa kan, ti wọn ko fẹ darukọ ara wọn sọ fun BBC pe oṣu kẹwaa ọdun 2022 ni Emmanuella darapọ mọ ijọ St. John’s Catholic Church, Rumuolumeni.

Bakan naa lo si darapọ mọ ẹgbẹ akọrin, to si ja fafa nibẹ gẹgẹbi akọrin soprano.

Koda, wọn sọ pe o fi afẹsọna rẹ han fun awọn alaṣẹ ijọ naa.

“A n gba aawẹ ọlọjọ mọkanlelogun lọwọ pẹlu ipade adura ọlọjọ marun un to pari ni ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu kini ọdun 2023.

Lọjọ naa, alufa wa gba adura alagbara kan pe ki Ọlọrun tu aṣiri ẹnikẹni to ba fẹ mu idojuti ba ijọ katoliki.

Gbogbo wa si pariwo amin, lai mọ pe nnkan bayii maa ṣẹlẹ nitori lọjọ naa gan an ni Emmanuella ni ijamba ọkọ nigba to n bọ lati ipade adura naa.”

Bi aṣiri ṣe tu si ijọ lọwọ ati bi Emmanuella ṣe padanu ẹmi rẹ ninu ijamba ọkọ

Emmanuella Adolisa

Oríṣun àwòrán, Emmanuella Adolisa/instagram

Emmanuella nikan lo ku ninu ijamba kẹkẹ Maruwa to wọ, eyi to ni ijamba

Ni ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu kini ọdun 2023, lẹyin ipade irọlẹ ni ile ijọsin naa, Emmanuella, ti oun pẹlu wa nibi ipade adura naa n pada lọ sile, lo ba ko agbako ijamba ọkọ, nibi to ti jabọ ninu kẹkẹ maruwa to wọ, bọ sinu gọta.

Ẹjẹ bẹrẹ si nii da lara rẹ, paapaa julọ oju rẹ. Ohun nikan si lo ku ninu ijamba naa.

Lẹyin asiko diẹ, iroyin kan awọn ọmọ ẹgbẹ akọrin ijọ lara pe ọkan lara awọn ọmọ ijọ wọn ni ijamba, eleyi lo si mu ki alufa ijọ naa sare tete lọ sibẹ, ti wọn si gbe e lọ si ile iwosan.

Ileewosan akọkọ ti wọn gbe e de kọ lati gba a wọle, ni wọn fi gbe e lọ si ile iwosan awọn ologun to wa ni opopona Aba road, nibi ti awọn dokita ti fidi rẹ mulẹ pe o ti ku, ki o to de ọdọ awọn.

Wọn gbe oku rẹ lọ si ile igbokupamọ si nibi ti awọn oṣiṣẹ ibẹ ti jẹ ko di mimọ pe ọkunrin to n ṣe iṣe obinrin, ti awọn oloyinbo n pe ni ‘transgender’ ni Emmanuella to ku naa.

Emmanuella Adolisa

Oríṣun àwòrán, Emmanuella Adolisa/instagram

“Wọn bọ awọn awọtẹlẹ mẹrin ti Emmanuella wọ ni Mọsuari, asiri ba tu pe ọkunrin ni, kii se obinrin”

“Ko pẹ ti wọn gbe oku rẹ de ile igbokupamọsi ti awọn oṣiṣẹ ibẹ fi pe alufa ijọ wa, nitori pe ko tii rin jinna nigba naa, lati beere boya akọ tabi abo ni ẹni ti a gbe wa, ti alufa si sọ fun wọn pe obinrin ni.

Ṣugbọn nigba ti olori oṣiṣẹ mọṣuari atawọn oṣiṣẹ rẹ ṣe ifidimulẹ ohun ti alufaa sọ, ni wọn rii pe ọkunrin ni ẹni ti a n pe ni obinrin o.”

Ọmọ ijọ naa kan to n ṣalaye eyi fun BBC tun tẹsiwaju lati jẹ ko di mimọ fun wa pe awọn oṣiṣẹ mọṣuari ṣe awari eyi lẹyin ti wọn bọ gbogbo aṣọ ara rẹ.

Awọn osisẹ mọsuari naa ri pe ṣokoto awọtẹlẹ boxer mẹrin lo wọ.

Nigba ti wọn si bọ wọn tan ni wọn ri pe obinrin kọ ni ẹni ti wọn gbe wa, ọkunrin ni.

Ileeṣẹ iroyin BBC News kan si ajọ kan ti kii ṣe tijọba, Initiative for Advancement of Humanity, ti Emmanuella sọ fun awọn eeyan pe oun ti n ṣiṣẹ amọṣa wọn ko dahun.