Èṣù ló gbọwọ́ mi ṣiṣẹ́, n kò mọ̀ọ́mọ̀ dáná sùn ìyàwó mì – Afurasí ọ̀daràn

Aworan Hassan Azeez

Oríṣun àwòrán, Police/Ogun

Ọwọ ṣikun ofin ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti tẹ arakunrin kan, Hassan Azeez, ẹni ọdun mẹrindinlaadọta fẹsun wi pe o dana sun iyawo rẹ.

Azeez lẹyin to dana sun iyawo rẹ nitori ko tete da ina ounjẹ fun-un salọ si orilẹ-ede Benin Republic lẹyin iṣẹlẹ naa.

Ni agbegbe Ibogun, ipinlẹ Ogun ni iṣẹlẹ naa ti waye ni ọjọ kejilelogun, Oṣu Kẹwa ọdun to kọja.

Ọjọ kejilelogun, oṣu Kiini ọdun 2023 ni ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa tẹ Azeez Afurasi ni orilẹede Benin Republic nibi to sapamọ si.

“Iyawo mi kọ jalẹ lati dana ounjẹ fun mi ni mo sebinu da epo si i lára”

Nigba ti wọn n fọrọ wa lẹnu wo, afurasi ọdaran naa ni iṣẹ ọwọ Esu ni ati wi pe oun ṣI inu bi lọjọ ti iṣẹlẹ naa waye ni.

Azeez ṣalaye pe ebi n pa oun lọjọ naa ti iyawo oun, Olayinka Hassan si kọ lati lati gbọrọ si oun lẹnu nigba ti o paṣẹ fun lati dana ounjẹ ti oun maa jẹ.

O ni iyawo oun kọ jale lati dana fun oun ti oun si binu da epo si i lára.

“Mi o mọ pe yoo di nnkan nla bayii, iṣẹ eṣu ni.”

Agbẹnusọ ile ise ọlọpaa nipinlẹ Ogun, SP Abimbola Oyeyemi to fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ ni ile iṣe ọlọpa lagbegbe Ibogun ni baba ẹni to farapa naa ti fẹjọ sun nigba ti iṣẹlẹ naa waye.

O fi kun ọrọ rẹ pe wọn sare gbe Olayinka Hassan lọ si ile iwosan kan niluu Ibadan, Ipinlẹ Oyo nibi to ti n gba itoju lọwọ.

Oyeyemi fi kun pe Kọmisọna ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun CP, Lanre Bankole ti paṣẹ pe ki wọn gbe afurasi naa lọ si ẹka to n ri si ipaniyan ati iwadii ọdaran ni ipinlẹ naa fun iwadii to peye.