₦500 tí màá fi ra ‘Data’ láti fí ṣé Yahoo-yahoo ló mú mí yín ọlọ́kadà lọrùn pa

Aworan awọn afurasi ti o pa ọlọkada

Oríṣun àwòrán, Ogun State Police Command

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun ti ṣafihan awọn ọdọmkunrin mẹta kan ti wọn ṣa ọlọkada kan pa ki wọn to ji ọkada rẹ gba lọwọ rẹ.

Ọkan ninu wọn Samson Odunayo to jẹ ọmọ ọdun mejidinlogun sọ pe nitori owo data ẹẹdẹgbẹta Naira toun yoo ra si foonu lo mu ki oun ba wọn pa ọlọkada naa.

Lọjọ Ẹti to kọja yi ni Kọmisana ọlọpaa Ogun Lanre Bankole ṣe afihan wọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Awọn afurasi meji to ku ti wọn mu pẹlu Samson ni Sodiq Awokoya ati Jimoh Rilwan lagbegbe Ogere.

Gẹgẹ bi Odunayo ti ṣe sọ fun awọn akọroyin, o ni gbajuẹ ori ayelujara taa mọ si yahoo yahoo loun n ṣe.

O fi kun pe igba akọkọ toun yoo pa eeyan re ati pe oun nilo owo data ni kiakia lo mu ki oun bawọn pa Bashir Umaru to ni ọkada.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

”Sodiq lo fa mi wọ inu iṣẹ ọdaran.Igba ẹlẹẹkeji wa si re ki ọwọ to tẹ wa.”

”Iṣẹ alakọkọ taa ṣe, a o pa eeyan kankan. Ẹgbẹrun mẹta abọ Naira la gba lọwọ ẹni naa”

Ninu iroyin to tẹwa lọwọ nipa iṣẹlẹ naa, ọwọ tẹ awọn afurasi wọnyi nigba ti wọn fẹ lọ ta ọkada ti wọn ji gbe fun ẹnikan.

Ẹni naa gẹgẹ baa ṣe gbọ bẹrẹ si ni fura si awọn ọdọkunrin yi nigba ti wn ko le ṣalaye ibi ti wọn ti ri ọkada ti wọn fẹ ta.

Kia o ti ta awọn ọlọpaa lolobo ti wn si gbe wọn lọ si agọ ọlọpaa.

Ni agọ ọlọpaa lawọn mọlẹbi Bashir Umar to ni ọkada ti wọn fẹ ta ti ri ọkada Bashir nigba ti wọn lọ fẹjọ sun pe awọn ko ri Bashir mọ.

Nibẹ si ni awọn agbofinro ti tẹ awọn afurasi yi ninu ki wọn to mu wọn lọ sibi ti wọn pa Bashir si.

Awọn ọlọpaa baa ti wọn ge oku Bashir yannayanna ti wọn si fi ori rẹ kọ igi.

Kọmisana ọlọpaa ti ni ki wọn gbe awọn afurasi yi lọ si ẹka ọtẹlẹmuye ṣaaju ki wọn to ko wọn lọ si iwaju adajọ.