Ọmọ ilé ẹ̀kọ́ UI méjì fórí kó ọta ìbọn lọ́jọ́ kan ṣoṣo, wọ́n pàdánù ẹ̀mí wọn lọ́jọ́ kan náà

Fasiti UI

Oríṣun àwòrán, UI

Awọn akẹkọọ fasiti ilẹ Ibadan, UI pe fun adura lẹyin ti wọn padanu eeyan meji laarin ọjọ kan

Awọn akẹkọọ ati oṣiṣẹ fasiti ilẹ Ibadan ti n karibọnu lati ṣọfọ meji ninu awọn akẹkọọ naa to padanu ẹmi wọn laarin wakati mẹrinlelogun.

Ọkan ninu awọn oloogbe naa, Adegoke Adedayọ ti o wa ni opin ẹkọ ni ẹka ti a ti n kọ nipa itan ni wọn yinbọn pa lowurọ ọjọ Aiku lasiko ti idigunjale kan n waye lopopona UI si Bodija.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Bakan naa ni akẹkọọ kan to wa ni ipele ikeji ni ẹka ti a ti n kọ nipa imọ sayẹnsi ohun ọgbin ati ẹranko, Ayọmide Adeyẹmọ padanu ẹmi rẹ sọwọ ijamba ọkọ lasiko ti o fẹ ọda ni ẹnu ọna abawọle ile ẹkọ giga naa.

Adari ikansiraẹni ni fasiti ilẹ Ibadan, Tunji Ọladẹjọ ti o fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ fi kun ọrọ rẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa ti bẹrẹ iṣẹ iwadii idigunjale to waye.

Aarẹ ẹgbẹ awọn akẹkọọ ni fasiti naa, Yinka Adewọle gbogbo igbiyanju lati doola ẹmi awọn akẹkọọ naa lo jasi pabo.

O ni igbimọ to n ṣe akoso awọn akẹkọọ ti n gbero lati ṣe agbekale eto adura ati ilanilọyẹ fun awọn akẹkọọ ki aabo to peye le wa lori wọn.