Ìdí tí Ooni Ogunwusi fi gbé ọmọ rẹ̀ obìnrin tó ṣe ọjọ́ ìbí 28 sáyé àti bó ṣe tọ́ ọ dàgbà

Ooni Enitan, Olori Silekunola ati Ọmọ rẹ

Oríṣun àwòrán, Ooni of Ife

Ooni ti ilu Ile Ife, Adeyeye Enitan Ogunwusi ti ṣipaya lori iriri rẹ gẹgẹ bi obi.

Ooni fi eyi hande nigba to n yẹ ọmọ rẹ obinrin si lọjọ ibi rẹ to pe ẹni ọdun mejidinlọgbọn ti Ooni si jẹ ko di mimọ pe titọ ọmọ ko ṣee fi we ere ọmọde kan to n jẹ Squid Game.

Loju opo Instagram rẹ, Ooni kọ ọrọ rẹpẹtẹ pẹlu aworan ọmọ rẹ, Ọmọọba Adeola, o ni “jijẹ obi lee jẹ ala to tobi pẹlu ipenija ara ọtọ. Kii ṣe ere ọmọde rara”.

Ooni Enitan ati Ọmọ rẹ

Oríṣun àwòrán, Ooni of Ife

Ooni ni oun ti ni iriri gbigbadun pe oun jẹ baba si ọmọbinrin iyebiye ti oun bi ni ọmọ ọdun mọkandinlogun eyi to si jẹ iṣẹ nla fun oun amọ oun gbe ara le igbagbọ ati ipinu.

“Irinajo pẹlu ọmọ mi, Ọmọọba Adeola jẹ eyi to kun fun ọpọlọp nkan tuntun ti mi o mọ tẹlẹ gẹgẹ bi ọdọ to ti di baba amọṣa, mo pa ọkan mi mọ pẹlu iṣedeede”.

Ooni ni bi oun ba ranti atẹyinwa, bibi ọmọ ni ọjọ ori to kere jẹ ki oun gbe ninu ọpọlọpọ ilakọja eyi to pe iwa ire ati kikun oju osuwọn oun lẹjọ.

O ni oun tun rii pe jijẹ obi to n da nikan tọ ọmọbinrin lọna ti ko rin rilee mu ayipada ba iriri eeyan laye ti yoo si yi ọna rẹ pada tori o ni lati ran ọmọ rẹ lọwọ lati mọ ọna ti yoo tọ pẹlu gbogbo ohun ti aye n gbe ka iwaju rẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ooni Enitan ati Ọmọ rẹ

Oríṣun àwòrán, BellaNaija

“Lẹkunrẹrẹ, ile aye ti kọ mi lati maa ṣafihan ọpọ imumọra, ikaanu ati ipinu paapaa julọ bi ọmọbinrin mi ṣe n beere fun un. Emi ati rẹ wa di okun to yi gan ti ko lee ja.

A dijọ yọ ayọ wa papọ, a jọ la awọn ipenija wa kọja gẹgẹ bo ṣe di ọrẹ mi ati olubadamọran mi”.

Ooni ni Adeola jẹ yoo si tun jẹ orisun ibukun nla fun oun ati aṣeyọri oun laye tori oun ni ami agbara oun.

Ooni Enitan ati Ọmọ rẹ

Oríṣun àwòrán, Ooni of Ife

Ọba Adeyeye fi ironu akoko yii mọ riri awọn obi ti ko kuna ninu itẹsiwaju lati tọ awọn ọmọ wọn pẹlu gbogbo iwa daadaa ati lọna Ọlọrun.

O ni ki wn ma kan tọju ọmọ lasan amọ ki wọn ki wọn rii pe irẹp to dan mọran wa nipa ibaraẹnisọrọ. “Mu ọmọ rẹ ri ọna ati koju ipenija aye, kọ wọn lati ni inu didun si yiyanju iṣoro. Ba wọn pe ninu ohun ti wọn ba n ṣe ma si bẹru nigba ti wọn ba n fẹ lati da duro. Irẹpọ wa pẹlu awọn lee yala tun ọjọ ọla wọn ṣe tabi tu u ka”.