Ǹjẹ́ o mọ ìdí tí gbẹ̀rẹ̀bí fi má n jáde sí ara, àti pé ṣé ó ṣeéṣe láti dènà rẹ̀?

Gbẹ̀rẹ̀bí

Oríṣun àwòrán, THINKSTOCK

Ara tó dán, tó jọ̀lọ̀ wà lára ohun tí àwọn èèyàn fi máa ń ṣe ìwúrí, tí wọ́n sì fi máa ń yangàn.

Lára àwọn ohun tí àwọn èèyàn pàápàá àwọn obìnrin máa ń kà kún àbàwọ́n sí ara ni gbẹ̀rẹ̀bí jẹ́.

Ọ̀pọ̀ ló máa ń ná owó ribiribi láti ri dájú pé gbẹ̀rẹ̀bí ara wọn parẹ́ tàbí láti má ri mọ́ pátápátá.

Kí ni gbẹ̀rẹ̀bí gan-an àti pé kí ló máa ń fà á sí ara? Ta ni ó lè ní gbẹ̀rẹ̀bí àti pé kí ni èèyàn lè ṣe láti fi tọ́jú rẹ̀? Èyí ni àwọn ìbéèrè tí a ó dáhùn nínú àpilẹ̀kọ yìí.

Kí ni gbẹ̀rẹ̀bí?

Gbẹ̀rẹ̀bí

Oríṣun àwòrán, THINKSTOCK

Dókítà Sweta Rai tó jẹ́ onímọ̀ nípa awọ ara ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ṣàlàyé pé, gbẹ̀rẹ̀bí jẹ́ ìlà tẹ́ẹ́rẹ́ tó máa ń jáde sí awọ ara nígbà tí àwọn àyípadà bá bá awọ ara.

Dókítà Rai ṣàlàyé pé gbẹ̀rẹ̀bí máa ń jáde sára ènìyàn nígbà tí ènìyàn bá sánra tàbí dínkù sí bí ó ṣe wà tẹ́lẹ̀.

Tí ènìyàn bá wà nínú oyún àti ti èèyàn bá ń dàgbà máa ń jẹ́ kí awọ ara ní gbẹ̀rẹ̀bí.

Gẹ́gẹ́ bí onímọ̀ náà ṣe sọ, tí awọ ara bá fẹ̀ tàbí dínkù, ó máa ń jẹ́ kí awọ tó wà nínú, èyí tí àwọn olóyìnbó ń pè ní “dermis” kó ya tó sì máa ń fa gbẹ̀rẹ̀bí.

Ẹgbẹ́ onímọ̀ nípa awọ ara ilẹ̀ Amẹ́ríkà “American Academy of Dermatology Association” nínú àtẹ̀jáde kan ní, fífi kẹ́míkà “corticosteroid” para le fa kí gbẹ̀rẹ̀bí jáde sára ènìyàn.

Bákan náà ni wọ́n ní àìsàn “Cushing tàbí Marfan” le fa kí èèyàn ní gbẹ̀rẹ̀bí.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé lára obìnrin ni gbẹ̀rẹ̀bí ti máa ń yọ jù, àwọn ọkùnrin náà máa ń ní gbẹ̀rẹ̀bí gẹ́gẹ́ bí àwọn onímọ̀ ṣe sọ.

Wọ́n ṣàlàyé pé ìdí tí àwọn obìnrin fi máa ń ní gbẹ̀rẹ̀bí ju ọkùnrin lọ ni pé ọ̀pọ̀ obìnrin ló máa ń ní gbẹ̀rẹ̀bí nínú oyún látàrí bí àyípadà ṣe máa ń bá awọ ara obìnrin nínú oyún.

Tí gbẹ̀rẹ̀bí bá kọ́kọ́ ń jáde sí ara níṣe ló máa ń pọ́n tàbí kó rọra dúdú fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́, tí yóò sì máa yún èèyàn.

Àwọn ẹ̀yà ara tí gbẹ̀rẹ̀bí tí sábà máa ń hàn ju ni ọyàn, ìdí, itan, apá àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ṣé ó ṣeéṣe láti dènà níní gbẹ̀rẹ̀bí?

Gbẹ̀rẹ̀bí

Oríṣun àwòrán, THINKSTOCK

Ìwádìí ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ó ṣòro láti dènà gbẹ̀rẹ̀bí láti má yọ sí ara èèyàn.

Ọ̀pọ̀ àwọn iléeṣẹ́ tó ń ṣe ìpara ni wọ́n máa ń polówó pé àwọn ní ìpara tó lè dènà gbẹ̀rẹ̀bí àmọ́ ìwádìí ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ọ̀pọ̀ àwọn ìpara náà kìí ṣiṣẹ́.

Bákan náà ni ó ṣòro láti dènà gbẹ̀rẹ̀bí nínú oyún nítorí ohun tó máa ń fa gbẹ̀rẹ̀bí nínú oyún kìí ṣe ohun tí èèyàn lè ṣe àyípadà rẹ̀.

Àwọn onímọ̀ ní tí èèyàn tó bá sánra bá fẹ́ mú àdínkù ba ara rẹ̀, ó máa ń dára kí wọ́n ṣe é díẹ̀ díẹ̀ nítorí àti dènà gbẹ̀rẹ̀bí.

Jíjẹ oúnjẹ tó dára, tó ní àwọn èròjà vitamin E àti C, zinc àti silicon dára fún awọ ara.

Ṣé ìwòsàn wà láti mú gbẹ̀rẹ̀bí parẹ́ lára?

Àwọn onímọ̀ gbàgbọ́ pé kò sí ìpara tàbí òògùn kan tó lè mú kí gbẹ̀rẹ̀bí parẹ́ lára pátápátá tí èèyàn bá ti ni.

Wọ́n ní ọ̀pọ̀ àwọn ìpara tí wọ́n máa ń tà ni kìí ṣiṣẹ́ àmọ́ wọ́n le mú àdínkù bá bí ó ṣe máa ń hàn tó.

Wọ́n ní àwọn ìpara lè wúlò tí gbẹ̀rẹ̀bí bá ṣẹ̀ṣẹ̀ ń jáde sí ara tó sì lè mú àdínkù bá bó ṣe máa tóbi tó.

Níná owó ribiribi láti fi ra àwọn ìpara yìí kìí ṣe ohun tí àwọn onímọ̀ gba ènìyàn lámọ̀ràn lé lórí.

Lára àwọn ọ̀nà tí àwọn onímọ̀ máa ń lo láti fi tọ́jú gbẹ̀rẹ̀bí ni iṣẹ́ abẹ èyí tí àwọn onímọ̀ ní ó léwu láti lò àti pé owó gọbọi ni wọ́n fi máa ń ṣe é.

Ohun mìíràn tí wọ́n máa ń lò ni wọ́n pè ní “laser therapy” tí wọ́n sì sọ pé ohun náà kìí pa gbẹ̀rẹ̀bí rẹ̀ pátápátá àmọ́ ó lè mú àdínkù bá bí yóò ṣe hàn tó.