Níbo ni Mukaila Lamidi ‘Auxiliary’, alága ẹgbẹ́ awakọ̀ èrò tẹ́lẹ̀ nípínlẹ̀ Oyo wà?

Aworan Auxiliary

Oríṣun àwòrán, THE PARK MANAGEMENT OYO STATE

Iroyin nipa alaga igbimọ alamojuto awọn gareeji ọkọ, PMS, tẹlẹri nipinlẹ Oyo, Mukaila Lamidi, ti ọpọ mọ si ‘Auxiliary’ ti lu ori ayelujara pa lati ana ọjọ Iṣẹgun ọjọ keje oṣu Karun-un.

Ti ẹ o ba gbagbe, ni bi oṣu meloo kan sẹyin ni ileeṣẹ ọlọpaa kede wi pe awọn n wa Auxiliary.

Eleyii ṣẹlẹ lẹyin to kuro ni ipo alaga igbimọ to n mojuto awọn ibudokọ nipinlẹ Oyo.

Iroyin kan fidi rẹ mulẹ pe ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS ti gbe alaga igbimọ alamojuto awọn gareeji ọkọ, PMS, tẹlẹri l’Oyo, Auxiliary.

Gẹgẹ bi iroyin naa ṣe sọ, ni nnkan bi ago mẹrin irọlẹ ọjọ Iṣẹgun ọjọ keje oṣu Karun un ọdun 2024 yii ni DSS gbe Auxiliary ni ile rẹ to wa kagbegbe Olodo niluu Ibadan ni nnkan bii agogo mẹrin irọlẹ ọjọ Iṣẹgun.

A ko mọ ni pato idi ti wọn fi gbe Auxiliary titi di akoko yii tori ajọ DSS gan an ko tii fi ọrọ kankan lede nipa alaga awọn awakọ nipinlẹ Oyo tẹlẹri.

Amọ, awọn kan n sọ wi pe o ṣeeṣe ko jẹ pe nitori ifọrọwanilẹnuwo kan ti o ṣe eyi to wa lori ẹrọ igbọrọkaye YouTube ni wọn fi gbe e.

Ohun ti a gbọ ni pe Auxiliary sọ oriṣiriṣii ọrọ to taba Gọmina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ati awọn eekan mii to wa ni ijọba.

Ki lawọn to sun mọ ọ n sọ?

Ọpọ akitiyan ti BBC News Yoruba lati le ba awọn to sun mọọ sọrọ nipa ohun to ṣẹlẹ gan ati idi ti wọn fi wa gbe e lo ja si pabo pẹlu bi ọpọ awọn ti a le pe ni ekurọ lalabaku ẹwa rẹ ti ṣe n ọ pe awọn ko fẹ sọrọ.

Bẹẹni ọpọ iroyin ti a n gbọ n sọ pe ọpọ awọn to sun mọ aṣiwaju ẹgbẹ awakọ ero tẹlẹ ri naa ni wọn ti sun sẹyin lọdọ rẹ lati igba ti awọn agbofinro ti kede rẹ gẹgẹ bi ẹni ti wọn n wa.

Bawo ni wahala ‘Auxillary’ ṣe bẹrẹ?

Ni oṣu kẹfa ọdun 2023 ni awọn ọlọpaa ti kede Auxillary gẹgẹ bi ẹni ti wọn n wa.

Ikede wọn yii ko pẹ pupọ si asiko ti gomina ipinlẹ Ọyọ, Gomina Ṣeyi Makinde yọ Ọgbẹni Mukaila Lamidi kuro nipo gẹgẹ bi alaga ajọ amojuto gareeji ọkọ nipinlẹ Ọyọ, PMS nigba naa.

Awọn ọlọpaa ṣe ayẹwo ile rẹ, gẹgẹ bi alukoror ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ọyọ, Adewale Oṣifẹsọ ṣe sọ, nigba naa nibi ti wọn ti ba awọn ibọn ati ọta ibọn pẹlawọn ohun ija oloro miran pẹlawọn janduku ni ile rẹ.

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọyọ ni awọn n wa Auxillary nigba naa fun awọn ẹsun “igbimọran lati gbẹmi eniyan, ṣiṣe eniyan leṣe, katakara ibọn, ipaniyan, idigunjale ni ipinlẹ yii ati ijinigbe lagbegbe Oke Ogun ati Ibarapa.”

Lati igba naa wa ko si ẹnikẹni to gbọ ohunkohun mọ nipa ọrọ naa ki eyi to ṣẹlẹ.

Awọn ti wọn ko ni ile Auxillary lọdun 2023

Oríṣun àwòrán, Others

Ki lawọn eeyan n sọ nipa igbesẹ yii?

Nigba ti iroyin yii kọkọ jade lori ayelujara, ọpọ lo ṣe ni iyalẹnu nitori kii ṣe oṣu kan tabi meji sẹyin ni awọn agbofinro ti kọkọ kede pe wọn n wa a ti ko si si ohunkohun to ṣẹlẹ.

Bẹẹ ni adari ẹgbẹ awakọ ero nigbakan ri naa n ṣe awọn ifọrọwerọ pẹlawọn ileeṣẹ iroyin gbogbo kiri, paapaajulọ lati sọ ohun to ṣẹlẹ to mu ki tirela gba aarin oun ati gomina ipinlẹ Ọyọ, Gomina Ṣeyi Makinde, ti ọpọ mọ gẹgẹ bi korikosun rẹ tẹlẹ.

Eyi lo mu ki ọpọ maa ṣalaye pe o ṣeeṣe ko jẹ awọn ọrọ ti ‘Auxillary’sọ ninu awọn ifọrọwerọ wọnyii lo ti fi ẹnu kọ. Awọn kan tilẹ n tọka si ifọrọwerọ kan to ṣẹsẹ ṣe to jade lọjọ diẹ sẹyin nibi to ti sọrọ to si darukọ awọn eeyan kan lẹnu akoso ijọba ipinlẹ Ọyọ gẹgẹ bi ohun to ṣeeṣe ko mu ki aago ẹṣẹ rẹ kun akunwọsilẹ.

Bakan naa lawọn miran n woye pe “boya n ṣe ni wọn fẹ fi pamọ di ẹyin iodibo ọdun 2027.”

Kinni ajọ DSS ati ileeṣẹ ọlọpaa sọ lori ọrọ Auxiliary?

Lamidi Mukaila 'Auxillary'

Oríṣun àwòrán, others

Nigba ti a gbọ iroyin pe wọn ti gbe Auxiliary, BBC Yoruba kan si ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo lati fidi iroyin naa mulẹ.

Ṣugbọn igbiyanju wa lati jẹ ki wọn sọrọ pabo lo jasi, nitori alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ti a kan si ko gbe foonu rẹ, bẹẹ si ni ko fesi si atẹjiṣẹ ti a fi ṣọwọ si i.

BBC Yoruba tun kan si agbẹnusọ ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS, Ọmọwe Peter Afunaya lori ọrọ naa.

Bo tilẹ jẹ pe Ọmọwe Afunaya gbe ipe rẹ, ko sọ ohun kan ni pato lori ọrọ naa ti o fi pa ipe ọhun.

Ọmọwe Afunaya ko tun fesi si atẹjiṣẹ ti a fi ṣọwọ si oun naa lori foonu ati WhatsApp.

Bakan naa ni ọmọ ṣori pẹlu awọn to sun mọ Auxiliary ti a kan si.

Ko si ẹnikankan ninu wọn to ba wa sọrọ.