Arìnrìnàjò 45 tó ń lọ sí ilẹ̀ mímọ pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìjàmbá ọkọ̀

Aworan awọn ọkọ lori afara ti ijamba ti waye

Oríṣun àwòrán, Heidi Giokos

Arinrinajo marundinlaadọta lo ti padanu ẹmi wọn nibi ijamba ọkọ kan to waye ni orilẹede South Africa.

Ọkọ akero bọọsi to n gbe awọn arin irinajo naa lo re bọ lati ori afara, to si lọ sori apata.

Ọdọmọbinrin, ọmọ ọdun mẹjọ nikan lo ye ninu ijamba ọkọ naa sugbọn o farapa púpọ̀.

Awọn arinrinajọ ilẹ mimọ yii lo n bọ lati Gbaorone, to jẹ olu ilu Botswana fun ajọdun ajinde kan ni ilu Moria.

Ọkọ bọọsi akero ọhun lo ju wọnu, to si ya kuro lori afara lori oke Mmamatlakala to wa laarin Mokopane ati Marken ni ariwa Johannesburg gẹgẹ bii ileeṣẹ iroyin abẹle SABC ṣe gbe sita.

Igbiyanju lati doola awọn eeyan yii lo ja si ofo, ti ọpọ wọn si ti ku ki iranlọwọ to o de.

Minisita fun eto irinna, Sindisiwe Chkunga lo si ibi ti isẹlẹ naa ti waye, to si ransẹ ibanikẹdun si awọn mọlẹbi to padanu eeyan wọn.

O ni Ijọba South Africa yoo pese iranlọwọ lati yọ awọn oku naa, ti wọn yoo si ṣe iwadii lori ohun to sokunfa ijamba ọ̀hún.

“A n fi adura ransẹ si awọn mọlẹbi yii lasiko ti wọn wa yii, bakan naa ni a n rọ awọn awakọ lati dẹkun ere sisa lasiko yii niori ọpọ eeyan lo n gba opopona yii.