Iléèṣẹ́ ọlọ́pàá ṣàwárí òkú ọkùnrin tí ọ̀rẹ́ rẹ̀ pa, tó tún bò mọ́lẹ̀ nípìnlẹ̀ Ondo

Àwọn ọlọ́pàá lásìkò tí wọ́n wù òkú olóògbé

Pansa o fura, pansa ja! Aja o fura, aja jin, Onile ti o ba fura Ole ni o ko lọ. Igi arọwa yii lo ṣẹ mọ Ọpeyemi lára, ẹni ti ọrẹminu rẹ yọwọ kilanko rẹ lawo ran lajo aremabọ.

Arakunrin kan, eni ọdun merinlelogbon, tí orúkọ rẹ n jẹ Opeyemi Oyelakin ti di ewure jẹlejẹle, o daguntan jẹmọjẹmọ bi ọrẹ rẹ ti ṣe ṣekupa ninu igbo oko ẹgẹ kan ni ilu Oke Igbo ni ipinle Ondo.

Ọjọ karundinlogun, oṣu Kẹta, ọdun 2024 ni oloogbé yii ti di awati, eleyii ti o mú kí àwọn arakunrin kan ati awọn mọlẹbi rẹ fi to ileeṣẹ ọlọpaa létí.

Lẹyin iwadii ti awọn ọlọpaa ṣe, ọwọ wọn tẹ ọkunrin kan, Dọlapọ Babalola, ẹni tí ó jé ọrẹ timọtimọ fun oloogbe yii fun ẹsun siseku pa a.

Lẹyin ti ọwọ tẹ ẹ, ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ṣe awari oku oloogbe naa ni ibi tí afurasi ti ọwọ tẹ naa bo o mọ.

Afunrasi ọhun to jẹ ẹni ọdun 39 jẹwọ ẹsẹ iseku pani yii, o si mu awọn ọlọpaa lọ si inu oko kan ni ilu Oke Igbo nibi ti wọn sin oku ọmọkùnrin naa si.

Akiyesi fi han pe oku oloogbe naa ti jẹra kan eegun kí ilé iṣẹ Ọlọpaa tó ṣe awari rẹ.

Bawo ni o ṣe ṣẹlẹ gaa an?

Ibi ti ara oloogbe jẹrà si

Babalola ṣalaye pe oun ati Opeyemi jẹ ọrẹ lati ọjọ to ti pẹ ṣugbọn fun ọpọlọpọ ọdun ni wọn ko fi rira nitori pe Opeyemi rin irin ajo lọ si ipinlẹ miiran.

O fi kun pe awọn mejeeji pada rira ni ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹta, ọdun 2024, ni ilu Ondo.

Afurasi ọdaran naa sọ pe bi ọdun mẹjo sẹyin ni wọn ti gburo ara kẹyin ko to di pe wọn tun pade.

Babalola ni ” Lẹyin ti a pade ni ọjọ kẹrinla oṣù Kẹta, ọjọ keji ni mo pe ọrẹ mi, Opeyemi ko wa gbemi lati agbegbe Oke Agunla ni ilu Ondo. Mo sọ fun pe ko gbemi de Sabo lati ri eeyan kan.

“Nigba ti a de Sabo ni ẹni ti mo lọ ba, Mufutau Sikiru sọ fun mi pe oun ma ṣalaye fun Opeyemi ko gbe wa lọ si oko ti eeyan kan fẹ ẹ fun lati dàko si ni ilu Oke Igbo. Opeyemi si gba lati gbewa lọ.

“Lẹyin ti a de inu oko, ni a gbiyanju lati gba ọkada lọwọ Opeyemi. Nibi ti awa mejeeji ti n gbiyanju yii ni mo ti mu okuta ti mo si laa mọ lori titi ẹmi fi bọ lara rẹ.”

Afurasi ọdanran naa sọ pe ẹgbẹrun lọnaa aadoje naira ni wọn ta ọkada ti wọn gba lọwọ Opeyemi fun onibaara wọn to wa ni ilu Ibadan.

” Lati ọdun 2021 ni mo ti n ji ọkada awọn eeyan gba, mo si ti gba ọkada to le ni marundinlogun.

“Awọn ilu bi Ondo, Akure, Ilesha, Ife ati Ipinlẹ Ekiti ni a ti ji ọkada gba sẹyin, ṣugbọn mi o ti pa ẹnikẹni ri ko to di eleyi ti a gba lọwọ Opeyemi ti ẹmi rẹ lọ si.”

Ọwọ ma tẹ gbogbo awọn ọdaran to lọwọ si iku Opeyemi Oyelakin- Oga Ọlọpaa

Kọmíṣánnà ọlọ́pàá ló dárí ikọ̀ tó lọọ wú òkú olóògbé

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti fi idaniloju wọn han lati foju gbogbo awọn to lọwọ ninu ṣiṣekupa Opeyemi Oyelakin, wina ofin.

Kọmisanna ọlọpaa ni ipinlẹ Ondo, Abayomi Oladipo jẹ ki o di mimọ pe iwadii n lọ lọwọ lati mu Mufutau Sikiru, arakunrin ti oun ati Dolapo Babalola jọ padi apo pọ lati ṣeku pa Opeyemi Oyelakin, to fi mọ jiji ọkada rẹ gbe lọ.

Kọmisanna naa lo dari ikọ awọn ọlọpaa tó lọ si ilu Oke-Igbo lati lọ ṣe awari ibi ti wọn jú oku oloogbe naa si.

Komisana naa ṣalaye pe lọjọ karundinlọgbọn, oṣu Kẹta ni eeyan kan wa si agọ ọlọpaa lati fi to awọn agbofinro leti pe arakunrin kan ti oun gbe ọkada fun ti di awati lati ọjọ karundinlogun.

“Ẹsun ti arakunrin yi fi to ọlọpaa leti lo mu ki a bẹrẹ iwadii. Iwadii ta ṣe lo mu ki a fi panpẹ ofin gbe Dolapo Babalola”.

Ọga ọlọọpa naa sọ pe “afẹ fi asiko yii sọ fun awọn araalu pe ti wọn ba ri awọn eeyan ton wọ igbo lọ, ẹbere nkan ti wọn fe lọ ṣe, ki ẹ tun sọ fun awọn ọlọọpa abi agbofinro ti o ba wa nitosi ki a le fi oju awọn asebi han. Ifọwọsowọpọ araalu pẹlu awọn agbofinro ni a tọrọ fun”

O parọwa fun awọn ọlọkada lati funra nigba ti ẹnikẹni ba ni ki wọn gbe wọn lọ si ibi to jina tabi to palọlọ.

Ikọ oṣiṣẹ eleto ilera nile iṣẹ Ọlọọpa naa ti pale oku naa mọ kuro ninu igbo to wa fun ọjọ mẹrinla.

Ẹbi oloogbe pe fun idajọ ododo

Pasito Taiwo Oyediran, to jẹ ọkan lara ẹbi oloogbe Opeyemi Oyelakin, sọ pe lati Ibadan ni oloogbe naa ti ko wa sì ilu Ondo lati wa ma a ṣiṣẹ, ki o to di àwátì ni ọjọ karundilogun, oṣù Kẹta, ọdún 2024.

Pasitọ naa ni ẹkọ ni iṣẹlẹ yii ma jẹ fún ọpọlọpọ awọn eeyan pe ki wọn kiyesiara fun eeyan ti wọn ba ti ri fún igba pipẹ.

Iyawo ati ọmọ kekere kan ni Opeyemi Oyelakin fi si lẹ saye.