Alága ìjọba ìbílẹ̀ fi ògún búra fún àwọn èèyàn tó yàn sípò

Aworan eto ibura naa

Oríṣun àwòrán, screenshot

Alaga ijọba ibilẹ Ikẹrẹ Ekiti ni ipinlẹ Ekiti lẹkun iwọ oorun gusu Naijiria, Ọgbẹni Olu Adamọlẹkun ti ṣeto ibura fun awọn oṣiṣẹ to yan si ipo alamojuto ati olubadamọran, amọ ohun to jẹ iyalẹnu kọ ni eto ibura yii bi ko ṣe irufẹ ọna ti ibura naa gba waye.

Ninu fidio kan to n lọ kaakiri lori ayelujara, a ri awọn eeyan ti wọn yan sipo naa pẹlu ada, to jẹ ami oriṣa ogun ni ilẹ Yoruba) lọwọ kan pẹlu yala Bibeli tabi Kurani ni ọwọ keji.

Ogun jẹ oriṣa kan to jẹ gbajugbaja lawujọ ẹsin abalaye ni ilẹ Yoruba. Ogun ni wọn n pe ni ọriṣa to ni irin.

Eto iburawọle sipo naa, gẹgẹ bi a ṣe gbọ, waye ni gbọngan ọfiisi alaga ijọba ibilẹ naa ni ileeṣẹ ijọba ibilẹ Ikẹrẹ nilu Ikẹrẹ Ekiti ni ọjọ keji oṣu karun un ọdun 2024.

Nigba to n ṣe eto ibura naa fun wọn, ọgbẹni Adamọlẹkunto jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC rọ awọn to yan sipo naa lati maa wi tẹlẹ oun ni ede Yoruba pe, “, “Lati oni lọ, maa jẹ olotitọ si BAO (ẹni to jẹ gomina ipinlẹ Ekiti bayii) ati Monisade (Igbakeji gomina ipinlẹ naa), ati ẹgbẹ wa ( iyẹn ẹgbẹ oṣelu APC) atawọn ọga wa titi digba ti wọn maa fi pa aṣẹ mii fun mi.

“Bi mo ba ti yago lọna yii, ki ogun pa mi, tabi ki Kurani (tabi Bibeli) yii pa mi. Fun idi eyi, mo maa jẹ olootọ.”

Eto ibura naa

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Alaga ijọba ibilẹ naa ki awọn olubadamọran ati adari ẹka iṣẹ ijọba ibilẹ naa kú oriire to si rọ wọn lati ṣe iṣẹ takuntakun fun idagbasoke ijọba ibilẹ naa ati ipinlẹ Ekiti.

Lorilẹede Naijiria ko wọpọ lati ri ki awọn oloṣelu to fi awọn nnkan abalaye bura ki wọn to de ipo, ohun ti wọn maa n lo lọpọ igba ni Bibeli ati Kurani.