Ṣé lóòtọ́ọ́ ni Opay fẹ́ kógbá wọlé ní Nàìjíríà?

Aworan Opay

Oríṣun àwòrán, Opay/X

Iroyin kan to lu ori ayelujara pa lati ana ọjọ Iṣẹgun lo sọ pe ile ifowopamọ ori ayelujara Opay fẹ kogba wọle ni Naijiria.

Laipẹ yii ni banki apapọ Naijiria, CBN ransẹ pe awọn adari ile ifowopamọ naa si ilu Abuja lori ọrọ nini akọọlẹ awọn onibaara wọn.

Amọ, ileeṣẹ Opay ninu atẹjade to fi sori oju opo X rẹ ni awọn ko gba onibaara tuntun mọ lati fi ṣe atilẹyin fun ijọba lori iwadii ti wọn n ṣe.

Wọn ni gbogbo awọn to ti ni akaunti tẹlẹ pẹlu awọn ko ni iṣoro kankan bi banki CBN ṣe kede rẹ ati pe gbogbo akọọlẹ awọn onibaara awọn to ti wa tẹlẹ ni aabo to peye wa fun.

Lati igba ti banki apapọ CBN ti paṣẹ pe ki Opay atawọn ile ifowopamọ ori ayelujara mii dawọ gbigba onibaara tuntun duro ni ọpọ eeyan ti n gbe oriṣiiriṣii iroyin kiri nipa Opay.

Ẹwẹ, Opay ti wa sọrọ bayii loju opo X rẹ pe irọ to jina si ootọ ni pe awọn fẹ kogba wọle ni Naijiria.

Skip Twitter post

Allow Twitter content?

This article contains content provided by Twitter. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Twitter cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose ‘accept and continue’.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Twitter post

Content is not available

View content on TwitterBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

Ninu atẹjade ti Opay fi lede ọhun ni o ti sọ pe kawọn onibaara awọn kọ eti ikun si iroyin tawọn ka n pin kaakiri ori WhatsApp atawọn itakun ayelujara mii pe iroyin ofege lasan ni.

Ile ifowopamọ Opay sọ pe ‘’ọkan gboogi ni Opay jẹ ni ẹka ile ifowopamọ lorilẹede Naijiria lati ọdun 2018.

Lati ọdun 2018 yii ni a ti n tẹ awọn ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu onibaara wa lọrun ti awọn naa ṣi ni igboya ninu wa.

A ko ṣi ni dẹkun igbiyanju wa nipa lilo imọ ijinlẹ lati ri pe gbogbo eeyan ni anfani si ile ifowopamọ fun idagbasoke ọrọ-aje orilẹede Naijiria.

A n fi asiko yii rọ awọn araalu wi pe ki wọn kọ eti ikun si iroyin ofege tawọn eeyan kan n gbe kiri nipa ileeṣẹ Opay.’’

Mọ ìdí tí CBN fòfin de Opay, Palmpay àtàwọn míì láti yé ṣí akoto owó fáwọn oníbàárà tuntun

Níṣe ni àwọn oníbàárà àwọn ilé ìfowópamọ́ kan ń kó ọkàn sókè bí ilé ìfowópamọ́ àpapọ̀ Nàìjíríà, CBN, ṣe kéde pé kí àwọn ilé ìfowópamọ́ orí ayélujára má gba oníbàárà tuntun mọ́.

Àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìfowópamọ́ orí ayélujára kan tí wọn kò fẹ́ kí àwọn oníròyìn dárúkọ wọn fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ fún àwọn akọ̀ròyìn.

Àwọn ilé iṣẹ́ bíi Opay, Kuda Bank, Palmpay àti Moniepoint ni ọ̀rọ̀ náà kàn, tí wọn kò ní ní àǹfàní láti gba àwọn oníbàárà tuntun láàyè láti ṣí akoto owó pẹ̀lú wọn fún ìgbà kan ná.