Ǹ jẹ́ o mọ àwọn èèyaǹ wọ̀nyí tó jà fún òmìnira Nàìjíríà?

Obafemi Awolowo, Unamdi Azikwe ati tafawa Balewa

Oríṣun àwòrán, others

E wo awọn oloṣelu meje to ja fitafita fun ominira Naijiria.

1. Oloye Obafemi Awolowo:

Oloye Obafemi Jeremiah Oyeniyi Awolowo jọ ọkan pataki lara awọn to ja fitafita fun ominira orilẹ-ede Naijiria.

Wọn bi Awolowo ni ọjọ kẹfa, oṣu kẹta, ọdun 1909 ni ilu Ikenne, ni ipinlẹ Ogun ni guusu Naijiria.

Baba to bi Awolowo jẹ agbẹ, sugbọn o doloogbe nigba ti Awolowo wa ni ọmọ ọdun mẹwaa pere.

Awolowo jẹ ẹni to nifẹ orilẹ-ede yii lọkan, to si ṣe aṣeyọri gẹgẹ bi olori ẹkun iwọ oorun orilẹ-ede Naijiria nipa ṣiṣeto ẹkọ ọfẹ ati ilera ọfẹ atawọn nkan miran.

Ni ọdun 1959 ni Awolowo da ileeṣẹ amohunmaworan Naijiria silẹ, eyi to jẹ akọkọ iru rẹ nilẹ Afirika.

Bẹẹ lo tun da ẹgbẹ “Oduduwa Group” silẹ lọdun kan naa.

Awolowo gbe apoti idibo lati wọ ile igbimọ aṣofin labẹ asai ẹgbẹ Action Group, sugbọn o kuna lọdun 1979 ati 1983.

O gbe Hannah Idowu Dideolu ni iyawo, wọn si bi ọmọ.

Awo, gẹgẹ bi ọpọlọpọ eeyan ṣe n pe e, jade laye lọjọ kẹsan an, oṣu karun un, ọdun 1987, ni ọmọ ọdun mejidinlọgọrin, ti wọn si sin in ni Ikenne to jẹ ilu rẹ.

Fasiti ijọba apapọ ti Obafemi Awolowọ ni Ile Ifẹ ni ipinlẹ Ọṣun ni wọn fi sọ orukọ Awo ki a le maa ranti rẹ.

2. Sir Ahmadu Bello:

Sir Ahmadu Bello

Oríṣun àwòrán, Ahmadubellofoundation.org

Wọn bi Sir Ahmadu Bello ni ọjọ kejila, oṣu kẹfa, ọdun 1910 ni Rabbah Sokoto.

O si jẹ ọkan gboogi lara awọn aṣaaju akọkọ ni orilẹ-ede Naijiria, bẹẹ si ni o tun jẹ adari ẹgbẹ Northern People’s Congress.

Ahmadu Bello ja fitafita lati ri i pe Naijiria gba ominira lọwọ oyinbo alawọ funfun leẹyin to pada de lati orilẹ-ede Gẹẹsi.

Fasiti Ahmadu Bello to wa ni Zaria ni wọn fi pe orukọ rẹ lati yẹ ẹ si.

Lara awọn ohun ti wọn fi n ranti Bello titi di akoko yii ni ni aktitiyan rẹ lati mu irẹpọ ba awọn eeyan oke ọya nilẹ Naijiria.

3. Anthony Enahoro:

Sir Anthony Enahoro

Oríṣun àwòrán, Wikipedia

Oloye Anthony Enahoro jẹ ọkan gboogi lara awọn to ja fun ominira Naijiria.

Nigba to wa ni ọmọ ọdun mọkanlelogun lo di olootu iwe iroyin Southern Nigerian Defender, eyi to mu ko jẹ olootu iwe iroyin to kere julọ ninu iwe itan Naijiria.

Enahoro ni ẹni akọkọ to pe fun ominira Naijiria ninu ile igbimọ aṣofin lọdun naa lọhun, eyi to mu ki awọn ojugba rẹ nigba naa maa pe e ni “Baba orilẹ-ede Naijiria.”

Enahoro jẹ ẹni to fẹran ẹkọ gidi, o si ja ija rere fun orilẹ-ede yii ki o to papoda ni ipari ọdun 2010.

4. Herbert Macaulay:

Olayinka Herbert Samuel Macaulay jẹ oloṣelu, onimọ-ẹrọ, ayaworan ile ati akọroyin.

Wọn bi i ni ọjọ kẹrinla, oṣu kọkanla, ọdun 1864. O si jẹ ẹni to tako iṣelu awọn ilẹ Gẹẹsi.

O wa lara awọn to da iwe iroyin Nigerian Daily News silẹ, lọna lati tẹsiwaju ninu ipo oṣelu.

Herbert Samuel Macaulay

Oríṣun àwòrán, @HistoryVille

Ni ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹfa, ọdun 1923, Macaulay da ẹgbẹ oṣelu Nigerian National Democratic Party (NNDP) silẹ, eyi to jẹ ẹgbẹ oṣelu akọkọ nilẹ Naijiria.

Macaulay rewalẹ aṣa lọdun 1946.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

5. Funmilayo Ransom Kuti:

O jẹ olukọ, ẹni to fẹran eto oṣelu ati ajijangbara fun ẹtọ awọn obinrin.

Wọn bi i ni ọjọ karundinlọgbọn, oṣu kẹwaa, ọdun 1900.

Oun ni ọmọ ile iwe akọkọ to jẹ obirin ni ile iwe Girama to wa ni Abeokuta, eyi ni Abeoktuta Grammar School, oun naa tun ni obinrin akọkọ to kọkọ wa ọkọ ayọkẹlẹ lorilẹ-ede Naijiria.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Funmilayo Ransome Kuti wa lara awọn to ja fitafita lati ri i pe awọn obinrin lẹtọ lati kopa ninu idibo lorilẹ-ede yii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Funmilayo ni iya to bi gbajugbagbja olorin ati ajijangbara, Fela Anikulapo Kuti, pẹlu Bẹẹko Ransome-Kuti ati ọjọgbọn Olikoye Ransome-Kuti to jẹ minisita fun eto ilera nigbakan ri ni Naijiria.

Funmilayo Ransom Kuti

Oríṣun àwòrán, @thefemifela

Ni ọdun 1978 ni awọn ọmọ ologun ti Funmilayọ lati aja kẹta ni ile ọmọ rẹ, Fela Anikulapo ti wọn pe ni Kalakuta Republic. To si ṣeṣe gidigidi.

Lẹyin naa lo jẹ Ọlọrun nipe ni ọjọ kẹtala, oṣu kẹrin, ọdun 1978 kan naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

6. Nnamdi Azikwe

Oloye Benjamin Nnamdi Azikwe ti gbogbo eeyan mọ si Zik, ni wọn bi ni ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kọkanla, ọdun 1904.

O jẹ gonima apapọ ni Naijiria laarin ọdun 1960 si ọdun 1963, lẹyin naa lo di aarẹ akọkọ ni orilẹ-ede Naijiria.

Azikwe kawe ni iiẹ Amẹrika ni Fasiti Columbia, Fasiti Pennsylvania ati Faisiti Howard. Lẹyin naa lo pada si ilẹ Afirika ni ọdun 1934 lati bẹrẹ iṣẹ akoroyin.

O da iwe iroyin Africann Pilot silẹ lọdun 1937, lẹyin naa lo tun da awọn iwe iroyin miran silẹ.

Lara awọn ohun manigbagbe ti wọn fi n ṣe iranti Nnamdi Azikwe ni awọn ibi ti wọn fi sọ orukọ rẹ bi; papakọ ofurufu to wa ni Abuja, Nnamdi Azikwe International Airport.

Bakan naa ni wọn sọ papa-iṣere bọọlu alafẹsẹgba ni Enugu, Fasiti Nnamdi Azikwe ni Awka, adugbo Nnamdi Azikwe ni orilẹ-ede Tanzania, ati bẹẹbẹẹ lọ.

Oloye Azikwe jẹ Ọlọrun nipe ni ọjọ kọkanla, oṣu karun un, ọdun 1996.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

7. Tafawa Balewa:

Wọn bi Alhaji Abubakar Tafawa Balewa ni oṣu kejila, ọdun 1912 ni ipinlẹ Bauchi.

Tafawa Balewa jẹ akinkanju oloṣelu ati adari igbimọ ijọba kan ṣoṣo ti Naijiria ni lẹyin ominira.

O jawe olubori ninu idibo sipo aṣofin lọdun 1946 ati 1947.

Gẹgẹ bi asọfin, o ja fun ẹtọ awọn ọmọ Naijiria to wa lati oke ọya ni ifọwọsowọpọ pẹlu ẹnikeji rẹ, Alhaji Ahmadu Bello. Lẹyin naa ni awọn mejeeji da ẹgbẹ oṣelu Northern People’s Congress (NPC) silẹ.

Ni ọjọ karundinlogun, oṣu kinni, ọdun 1966 ni awọn ologun kan to ditẹgbajọba ṣeku pa Balewa pẹlu awọn adari miran.

Lẹyin ọjọ mẹfa si i ni wọn ṣe awari oku rẹ lẹba ọna ni agbegbe ipinlẹ Eko.

Iroyin iku Alhaji da rogbodiyan silẹ ni oke ọya, eyi to yọri si iditẹgbajọba miran loṣu keje, ọdun kan naa.

Ijọba Naijiria yẹ ẹ si nipa fifi aworan rẹ si owo Naira marun un ati bi wọn ti yi orukọ Fasiti Bauchi pada si oruke rẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ