Aṣírí tú! A ti mọ àwọn tó ń ṣagbátẹrù Sunday Igboho àti Nnamdi Kanu nínú ìjọba – Buhari

Aarẹ Buhari

Oríṣun àwòrán, Bayo Omoboriowo

Aarẹ orilẹede Naijira, Muhammadu Buhari ti tu kẹkẹ jagamu ọrọ silẹ nipa awọn to n ṣagbatẹru ajafẹtọ Yoruba Nation, Sunday Igboho ati ajafẹtọ Biafra, Nnamdi Kanu.

Buhari ni awọn eekan nlan nla lo wa nidi ọrọ Sunday Igboho ati Nnamdi Kanu ti wọn fi n ke bo ṣe wu wọn.

Koda ààrẹ ní ọ̀kan lára àwọn aṣòfin tó wà n’íjọba òun lọ́wọ́lọ́wọ́ wà lára àwọn tó ń kọ́ Sunday Igboho àti Nnamdi Kanu ní ìwà.

“Bi ọwọ ṣe tẹ Sunday Igboho ati Nnamdi Kanu ti tu aṣiri awọn to n ṣagbatẹru rogbodiyan ni Naijiria”

Gẹgẹ bo ṣe sọ, aarẹ ni gbogbo awọn to n ṣagbatẹru awọn to n ja fun iyapa Naijiria yii to si n sọ ọrọ alufanṣa kiri lawọn yoo fi jofin.

O ni awọn ẹni naa n fi ẹmi awọn ọdọ ṣofo nipa fifa wọn wọ inu erongba wọn ti ko mu ọpọlọ dani

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ba gbogbo awọn ọmọ orilẹede rẹ sọrọ gẹgẹ bi wọn ṣe n ṣe ayẹyẹ ọdun ominra ni ọjọ Ẹti ọjọ Kini oṣu Kẹwa ọdun 2021 pe ki wọn jẹ ololuf alafia.

Minisita fun ọrọ abẹnu, Ọgbẹni Rauf Aregbesola lo fi ikede naa sita lorukọ ijọba apapọ.

Ọ̀rọ̀ Ààrẹ Buhari

“Oṣu mejidinlogun to kẹyin lo buru ju lorilede Naijiria, erongba wa lati dun 2020 si ni lati yanju ipenija aabo”.

Aarẹ Buhari sọ ninu ọrọ to br ni ago meje owurọ pe ohun ti ajakal arun Covid 19 ti fi oju gbogbo m Naijiria ati agbaye ri ti k Naijiria ni kọ.

O ni o ti da gbogbo agbaye ru amọ “gbogbo ọmọ Naijiria pawọpọ lati doju ija kọ”

Iru iskan yii naa la o tẹsiwaju lati maa lo ni gbogbo irufẹ ajakalẹ arun to ba tun yọju lọjọ iwaju.

Buhari ni awọn uyoo tun gbaruku ti awọnh apoogun lati le ṣe abr ati ogun ti yoo koju Covid 19.

Aarẹ beere pe “bi ajakalẹ aarun mii ba ja lu wa laya lọjọ iwaju, ṣe Naijiria ti gbaradi?”.

Buhari ni kawọn eeyan ma tii fi ọwọ yẹpẹrẹ mu ọrọ Covid-19. “Kẹẹ ṣi maa fọ ọwọ yin ati pe kẹẹ ma lo ibomu yin”.

Lori ipenija aabo

Aarẹ Buhari ni ohun to ba gba lawọn yoo fun ọr abo lorilẹede Naijria.

“A ó gbé ìjà kojú àwọn ọ̀tá wa títí wọ inú ilé wọn a ó sì ṣẹ́gun”. Aarẹ Buhari tẹnu mọọ pe ijọba oun yoo ti ṣetan lati fi gbogbo ẹni to ba ru ofin jofin.

Aarẹ ni “a lee yanju ikusinu aarin ara wa lai ta ẹjẹ silẹ” o si n rọ awọn ọmọ Naijira lati fara mọ alafia ati bibara ẹni jiroro lai wo ikunsinu”.

“A o tunbọ gba awọn eeyan si iṣẹ́ ologun mo si ti paṣẹ pe ki wọn tun gba awọn eeyan si iṣẹ Ọlpaa jakejado Naijiria”.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ