Ibùdó mẹta tí obìnrín kò le wọ̀ yíká àgbáyé

Awọn obinrin

Eto irinajo dara pupọ lati maa lọ, ka le mọ awọn agbegbe ti a ko mọ tẹlẹ, paapaa lasiko ti a ba wa lẹnu isinmi.

Yatọ si pe eyi yoo mu ki ara wa lokun, irirnajo afẹ yii yoo tun jẹ ka mọ ohun to n lọ lawujọ agbaye, ise wọn, asa wọn ati ede wọn pẹlu.

Ta n se eyi, a ri pe odo ni awa eeyan, a kan n san pade ara wa ni, amọ ti yoo tun jẹ ka ni oye si nipa isẹ ọwọ Olodumare tii se awamaridi.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Sugbọn bi irinajo yii se wa yaayi si, awọn agbegbe mẹjọ kan wa jake-jado agbaye ti obinrin ko le de nitori asa ati ise awọn eeyan to wa ni agbegbe naa ko fi aye gba eyi.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ibudo mẹjọ ti ẹsẹ obinrin ko le tẹ jakejado agbaye:

Ibudo ijọsin Ayyappan Temple, Sabarimala nilẹ India:

Ibudo ijọsin Ayyappan Temple

Oríṣun àwòrán, India TV

Ibudo ijọsin Ayyappan Temple lo wa nilu Kerala lorilẹede India.

Ibi mimọ ati ibudo ọ̀wọ̀ ni ibudo ijọsin naa, awọn ẹlẹsin Hindu nikan si lo wa fun.

Ibudo Ayyappan yii tun ni wọn tun n da pe ni Sabrimala, bẹẹ si ni o di eewọ patapata fawọn obinrin lati wọ ibẹ.

Awọn obinriin ti ọjọ ori wọn wa laarin ọmọ ọdun mẹfa si ọgọta ọdun si ni ko gbọdọ fi ẹsẹ kan ibudo naa.

Ajaja, awọn obinrin to ba si n se nnkan osu lọwọ ni wọn ko gbọdọ de agbagbe ibi ti ibudo ijọsin Ayyappan naa wa.

Ibudo igbafẹ Burning Tree Club ni Bethesda:

Ibudo igbafẹ Burning Tree Club ni Bethesda

Oríṣun àwòrán, Golf Pass

Ibudo igbafẹ Burning Tree Club yii lo wa nilu Bethesda lorilẹede Amẹrika.

Kikida awọn oloselu lo n na ibẹ, tori wọn si ni wọn se da ibudo igbafẹ naa silẹ ki wọn le maa nara lati jiroro nipa oselu.

Amọ sa, awọn adajọ ile ẹjọ to ga julọ ati aarẹ wọn naa lanfaani lati lọ si ibudo igbafẹ yii.

Idi si niyi ti Sandra Day O’Cornor fi jẹ obinrin akọkọ ti yoo da ẹsẹ tẹ ibudo naa lọdun 1981.

Igbesẹ naa si waye lẹyin to di obinrin akọkọ ti yoo di adajọ ilẹẹjọ to ga julọ nilẹ Amẹrika.

Ibudo idibo nilẹ Saudi Arabia ati ilu Pope,Vatican City:

Eto idibo ni Saudi Arabia

Oríṣun àwòrán, Saudi Arabia TV

Gbogbo agbaye lo mọ pe iwọn ba ni ẹtọ awọn obinrin ni orilẹede Saudi Arabia ta ba fi wọn we awọn akẹẹgbẹ wọn yoku ja;kejado agbaye.

Ijọba orilẹede naa ko gba wọn laaye lati se awọn nnkan kan bii wiwa ọkọ loju popo, jijade sita gbangba lai jẹ pe ọkunrin kankan tẹle wọn.

Bakan naa ni ijọba orilẹede Saudi Arabia ati Vatican City nilu Pope, ko gba fawọn obinrin lati maa wa si agọ idibo lati wa dibo.

Haji Ali Dargah, Mumbai:

Haji Ali Dargah, Mumbai

Oríṣun àwòrán, Wikipedia

Ibudo yii wa lara awọn Mọṣalaṣi to wa nilu Mumbai lorilẹede India ti wọn ko gba awn obinrin laaye lati wọ.

Idudo yii ni wọn fi ojubọ mimọ si gẹgẹ bii igbagbọ awọn olujọsin ibẹ.

Tẹlẹ-tẹlẹ, wọn n gba awọn obinrin laaye lati wọ ibi ijọsin mimọ julọ ti wọn n pe ni Haji Aki Dargah.

Amọ lati ọdun 2012, wọn ko gba awọn obinrin laaye mọ lati wọ ibẹ lẹyin ti wọn tu awọn obinrin to nimọ nipa idajọ ofin nilana Islam silẹ.

Idije kẹkẹ gigun ti wọn n pe ni Tour De France:

Idije kẹkẹ gigun ti wọn n pe ni Tour De France

Lara awọn ibi ti obinrin ko gbọdọ de ni ibi idije ere idaraya Kẹ̀kẹ́ gigun ti wọn n pe ni Tour De France to maa n waye nilẹ Faranse.

Kikida awọn ọkunrin lo maa n kopa ninu ere idaraya kẹkẹ gigun ọlọdọọdun naa, ti wọn fi n gun kẹkẹ yika tibu-tooro orilẹede Faranse.w pictures in App save up to 80% data.

Awọn papa isere bọọlu kaakiri orilẹede Iran:

Papa isere ni Iran

Oríṣun àwòrán, Iran Press

Gẹgẹ ba se mọ pe awọn ọkunrin lo maa n se ere bọọlu tẹlẹ, ko to di pe awọn obinrin naa n gba bọọlu.

Amọ ni orilẹede Iran ti ẹlẹsin Islam pọ si julọ, eewọ nla ni lati fi oju gan ni awọn obinrin ni papa isere bọọlu.

Inu ile ni awọn obinrin maa n wa, ọkunrin nikan si lo ni ẹtọ labẹ ofin orilẹede Iran lati yọju si papa ere bọọlu, boya lati woran ni abi lati gba bọọlu.tures in App save up to 80% data.

Ori oke Omine ni Japan:

Ori oke Omine ni Japan:

Oríṣun àwòrán, Japan Visitor

Ori ioke Omine jẹ ibi ọwọ julọ nilu Nara lorilẹedeJapan.

Bakan naa lo si gbajumọ pupọ fun idanwo mẹta nipa Igboya to maa n se fawọn olujọsin nibẹ.

Amọ wọn kii fi aaye gba obinrin kankan ko yọju si ori oke yii lati wa jọsin, ọkunrin nikan lo maa n wa sibẹ.

Ori oke Athos nilẹ Greece:

Ori oke Athos nilẹ Greece

Oríṣun àwòrán, Britannica

Ori oke Atos to wa nilẹ Greece yii lo tun jẹ erekusu pataki ti ibudo awọn ọkunrin ẹlẹsin ti ko ni aya wa.

Kikida awọn ọkunrin nikan lo n gbe ori oke yii, ti wọn si ti ya ara wọn sọtọ fun isẹ isin lai mọ obinrin.

Idi ree ti wọn ko se gba obinrin laaye lati maa de ibudo yii.