Yahaya Bello mú $720,000 lápò ìjọba láti sanwó fásitì ọmọ rẹ̀ nílẹ̀ òkèèrè bó ṣe ku ọjọ́ díẹ̀ kó kúrò lórí àléfà – EFCC

Yahaya Bello

Oríṣun àwòrán, Alhaji Yahaya Bello

Ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ, EFCC, ti sọ pe gomina ipinlẹ Kogi tẹlẹ, Yahaya Bello gba owo ti iye rẹ to $720,000 lati fi san owo ile ẹkọ ọmọ rẹ lasiko to ku iwọnba ọjọ perete ko fi ipo gomina silẹ.

Ọga agba EFCC, Ola Olukoyede lo fi ọrọ naa lede ninu ifọrọwerọ kan pẹlu awọn akọroyin ni olu ọọfisi ajọ naa to wa niluu Abuja.

Olukoyede sọ pe Bello gba owo naa lapo ijọba, o si gbe lọ si apo awọn to n paarọ owo ‘Bureau de Change’ gẹgẹ bii asansilẹ owo ile ẹkọ ọmọ rẹ.

“Ṣe o yẹ ki irufẹ ajẹbanu bẹẹ maa ṣẹlẹ ni ipinlẹ to toṣi bii Kogi, Ẹ si ro pe mo maa dakẹ?”

O ni “Gẹgẹ bii gomina, o mọ pe oun ti fẹ fi ipo silẹ, o gbe owo lati inu apo ijọba si apo awọn Bureau de Change lati fi san owo ile ẹkọ ọmọ rẹ ti ko tii bẹrẹ.

“Owo naa jẹ nnkan bii $720,000 tabi ju bẹẹ lọ pẹlu imọtẹlẹ pe oun yoo fi ipo gomina silẹ laipẹ.

“Ṣe o yẹ ki irufẹ nnkan bẹẹ maa ṣẹlẹ ni ipinlẹ to toṣi bii Kogi? Ẹ si ro pe mo maa dakẹ?

“Awọn kan sọ pe awọn kan lo n lo mi lati gbogun tii, ṣe lọjọ ori mi yii ni ẹnikan yoo maa lo iru mi?

“Emi kọ ni mọ bẹrẹ ẹjọ rẹ, mo jogun ẹjọ naa ni, mo si bere fun faili rẹ lati tẹsiwaju ẹjọ naa latari awọn nnkan ti mo ri nibẹ.

“Mo maa ri daju pe Bello foju bale ẹjọ”

Alaga ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu naa sọ siwaju si pe oun yoo ri daju pe oun ṣe ẹjọ gomina ana ọhun, ati pe oun yoo kọwe fi ipo alaga EFCC silẹ ti ko ba foju bale ẹjọ.

O fi kun pe gbogbo awọn to dena EFCC lati mu Yahaya Bello naa yoo foju wina ofin.

Yahaya Bello

Oríṣun àwòrán, EFCC

Ki ni yahaya Bello ṣe?

Ẹsun mọkandinlogun ọtọtọ ni EFCC fi kan Bello, eyii to da lori kiko owo ijọba lọna aitọ ati lilu owo ilu ni ponpo, ti iye owo naa si le ni ọgọrin biliọnu naira.

Olukoyede ni oun atawọn oṣiṣẹ oun ti ṣetan lati fọ naijiria mọ lọwọ iwa ajẹbanu lai ro ti awọn alatako ati ajẹnilẹsẹ to n gbogun ti EFCC.

Yahaya Bello ni gomina ipinlẹ Kogi lati oṣu Kinni, ọdun 2016 si oṣu Kinni, ọdun 2024 yii ko to gbe ijọba kalẹ fun Usman Ododo lati inu ẹgbẹ rẹ, APC.

Lọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 ni EFCC yabo ile gomina ana ọhun niluu Abuja lati fi panpẹ ofin mu amọ o ti na papa bora.

Lẹyin naa ni wọn kede rẹ gẹgẹ bii ẹni ti wọn n wa lẹyin to sa fun ofin.