Wo ohun àràmàndà tí àwọn olósèlú máa ń ṣe lásìkò ìbò láti fa ojú olùdìbò mọ́ra

Aisha Buhari n din akara, Aregbesola wọ asọ ile ẹkọ, ti Rochas Okorocha si n yan agbado

Oríṣun àwòrán, Collage

Lati igba ti eto iṣejọba tiwantiwa ti de si Naijiria pada lọdun 1999, oniruuru ọna ẹrọ lawọn oloṣelu ti gba lati fa oju awọn oludibo si iha ọdọ wọn lasiko idibo.

Omiran ninu ọna wọnyii jẹ eyi to pa ni lẹrin pupọ, bẹẹ ni awọn miran fẹẹ gbomi loju ẹni.

Eto oselu lorilẹ-ede Naijiria jẹ ọkan gboogi ninu awọn ohun ti o ni i se pẹlu igbe aye awọn eniyan lawujọ.

Lọpọ igba, awọn oloṣelu máa n lo asiko idibo lati fi ara han awọn ara ilu gẹgẹ bi ẹni pe awọn naa jẹ ọkan naa pẹlu wọn nipa ṣiṣe ohun aramanda.

Bi o tilẹ jẹ wi pe oṣelu Amala jẹ eyi to gbilẹ nipinlẹ Ọyọ nigba aye eekan oloṣelu ni, Oloogbe Lamidi Adedibu, ireti ọpọ ni pe bi iṣejọba tiwantiwa ṣe n fidi mulẹ sii, o yẹ ki iru oṣelu bẹẹ ti di ohun igbagbe.

Amọṣa ọna ẹrọ nipa fifi ẹtan mu oludibo lati dibo fun oloselu kan, ṣi n lọ lorilẹede Naijiria.

Ọpọlọpọ oludije sipo oselu kan tabi omiran lorilẹ-ede Naijria ni wọn ti fi igba kan lọ si aarin ilu lati lọ ba awọn eniyan ṣiṣẹ tabi ran wọn lọwọ, tabi ki wọn jẹun pẹlu wọn ni ita gbangba.

Jijẹun loju popo:

Aisha Buhari

Oríṣun àwòrán, Aisha Buhari

IYIOLA OMISORE

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK

Ohun ti ọpọ mọ ni pe awọn mẹkunu ni n jẹ ounjẹ lẹsẹ opopona lorilẹede Naijiria, nitori naa ko si ẹni to ba ri awọn gbajumọ bii gomina ti wọn n jẹun lẹgbẹ oju popo. Agbado ni ounjẹ oju popo tawọn oloṣelu maa n doju kọ julọ lorilẹede Naijiria.

Gomina Godwin Obaseki pẹlu baba isalẹ rẹ nigbakan ri, ti oun pẹlu ti jẹ gomina ri nipinlẹ Edo lo kọkọ ṣide agbado jijẹ lasiko ipolongo ibo lọdun 2016.

Aworan kan pẹlu to ṣe afihan igbakeji gomina ipinlẹ Ọṣun tẹlẹ to ti wa di akọwe apapọ ẹgẹ oṣelu APC bayii, Ọtunba Iyiọla Omiṣore nibi ti oun naa ti n fi ọwọ mẹwẹwaa jẹ agbado.

Bakan naa ni gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu pẹlu darapọ mọ ọgbọ̀n ounjẹ oju ọna yii nigba ti aworan kan jade loṣu keji ọdun 2021 nibi to ti n ra bọọli loju popo.

OSHIOMOLE

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK

Awọn oloṣelu pẹlu iṣẹ ti awọn eeyan ko mọ wọn mọ ṣaaju ibo

Lasiko to fi n dije fun saa akọkọ rẹ nipo, aworan ṣe afihan Babajide Sanwo-Olu ati igbakeji rẹ, bafẹmi Hamzat ni agbegbe Computer village ni ikẹja nibi to ti n ba obinrin kan dirun.

Babajide Sanwo-Olu n ba obinrin kan di irun

Oríṣun àwòrán, Babajide Sanwo-Olu

Bakan naa ni aworan miran ṣe afihan ibi ti Sanwo-Olu ti n kọ bi eeyan ṣe n tu ẹrọ ibanisọrọ ṣe.

Sanwo-Olu n kọ nipa atunse foonu

Oríṣun àwòrán, Sanwo-Olu

Bakan naa ni Minisita fọrọ ibaraẹnisọrọ, Rotimi Amechi naa n ba obinrin kan di irun lasiko to fẹ du ipo gomina ipinlẹ Rivers.

Rotimi Amaechi n di irun

Oríṣun àwòrán, Rotimi Amaechi

Bi a ba tun kawọ akasẹyin pada si ọdun 2016, aworan kan jade eyi ti o ṣe afihan Sẹnetọ Dino Melaye nibi to ti gbe koto itaja sori to n kiri ẹpa gẹgẹbi mọ to n kiri loju titi. Laini ddena pẹnu, bi a ba n sọrọ awọn oloṣelu ti awuyewuye n wọ tọ lẹyin julọ ni Naijiria, oke tente tabili ni Dino Melaye wa.

RAJI FASHOLA

Oríṣun àwòrán, Facebook

Nigba ti awọn ọmọ orilẹede Naijiria kan sọrọ tako o pe n n gan awọn mẹkunu to n kiri, esi ti Sẹnetọ Melaye fi sita ni pe oun naa ti kiri ri nigba ewe oun.

Minisita fun irinna nigba kan ri to tun figba kan jẹ gomina nipinlẹ Rivers, Chibuike Rotimi Amaechi pẹlu figbakan wọ adugbo kan lọ ni ipinlẹ Rivers nibi to ti lọ n dirun fun arabinrin kan.

Rochas Okorocha n yan agbado, o tun gbe ọmọ iya alagbado lọwọ

Oríṣun àwòrán, Rochas Okorocha

Awọn aworan nibi ti awọn oloselu ti n e nkan aramanda:

Aworan to mi igboro titi ni aworan kan ninu eyi ti gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ, Ayọdele Fayoṣe wa nibi ti o ti n ṣe abọ amala leṣe ni buka kan nilu Abuja, lẹyin to tẹwọ gba fọmu idije fun ipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu PDP nigba naa.

FAYOSE

Oríṣun àwòrán, Facebook

Oludije si ipo sẹnetọ ni ipinlẹ Kaduna pin redio fun awọn eniyan bi o tilẹ je pe o ni ko ni i se pẹlu oselu, amọ fun Ayajọ Ọjọ Radio lagbaye.

SANI USMAN

Oríṣun àwòrán, Facebook

Gomina Rauf Arẹgbesọla ni ọdun 2014 wọ asọ ile iwe awọn alakọbẹrẹ lati polongo idibo fun saa keji gẹgẹ bi gomina Ọṣun.

Rauf Aregbesola ninu asọ ile ẹkọ

Oríṣun àwòrán, Rauf Aregbesola

Rauf Aregbesola laarin awọn akẹkọọ

Oríṣun àwòrán, Rauf Aregbesola

AREGBESOLA

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK

Gomina ipinlẹ Ondo pin burẹdi fun awọn eniyan saaju idibo sipo gomina ni ipinlẹ Ondo.

AKEREDOLU

Oríṣun àwòrán, Nairaland

Iṣana pẹlu awọn ohun ti ẹgbẹ oselu PDP pin fun awọn eniyan saaju idibo gbogboogbo lọdun 2015.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

GARRI ATI EPA

Oríṣun àwòrán, NAiraland

Ẹgbẹ oselu APC pin iwe pẹlu asia ẹgbẹ pẹlu aworan aarẹ Buhari ati igbakeji Osinbajo lasiko idibo gbogboogbo lọdun 2019.

Sugbọn lọdun 2023 taa wa yii, ko yẹ ki iru awọn ẹtan oloselu yii jẹ awọn oludibo mọ, se lo si yẹ ki gbogbo oludibo pinnu lọkan ara wọn lati dibo fun oludije to ba wu wọn lai gba ohunkohun bii ẹtan lọwọ wn.