Ènìyàn kan kú bí ìwọ́de lórí ọ̀wọ́n gógó owó Náírà ṣe tẹ̀síwájú nílùú Ibadan lónìí

Ibi ti ìfẹ̀hónùhàn ti wáyé

Ní òwúrọ̀ ọjọ́ Àbámẹ́ta ni ìròyìn tún gbòde pé agbègbè Apata ní ìlú Ibadan, ìpínlẹ̀ Oyo tún ń gbóná janjan bí àwọn kan ṣe tún tẹ̀síwájú pẹ̀lú ìfẹ̀hónúhàn lórí owó Náírà.

Ìròyìn tó gba orí ayélujára pẹ̀lú fídíò kan ni pé ènìyàn kan pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ tí àwọn mìíràn sì farapa níbi ìkọlù kan tó wáyé láàárín àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò àti àwọn tó ń fẹ̀hónúhàn.

Ìkọlù ọ̀hún ló ń wáyé lẹ́yìn ọjọ́ kan tí àwọn jàǹdùkú kan lọ ṣe ìkọlù sí àwọn ilé ìfowópamọ́ kan ní agbègbè Agodi, Iwo Road, Monatan, Olodo àti Iyana Church.

Àwọn óṣojúkòró tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú wọn ní àwọn ènìyàn Apata ló ń ṣe ìwọ́de ti wọn gẹ́gẹ́ bí àwọn akẹ́gbẹ́ wọn ṣe ṣe ní àná.

Wọ́n ní ṣàdédé ni àwọn rí ọkọ̀ àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò tí ó kọjá tí àwọn sì bẹ̀rẹ̀ sí ní gbọ́ ìró ìbọn tí oníkálùkù sì bẹ̀rẹ̀ sí ní sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ̀.

Wọ́n ní ìbọn yìí lọ ba ẹnìkan tí òn;itọ̀hún sì gbé ẹ̀mí mí lójú ẹsẹ̀.

Kí ni iléeṣẹ́ ọlọ́pàá sọ?

Òṣìṣẹ́ ààbò tó ń bu oni pa áyà tí àwọn tó ń fẹ̀hónúhàn sun kalẹ̀

Agbẹnusọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Oyo, Adewale Osifeso nínú àtẹ̀jáde kan tó fi síta ní látàrí ìfẹ̀hónúhàn tó gbalẹ̀ ní Ibadan láti ọjọ́ Ẹtì ni àpapọ̀ àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò ti ń lọ káàkiri ìpínlẹ̀ láti pèsè ààbò tó dájú fún àwọn ará ìlú.

Osifeso ní lásìkò tí àwọn ń ṣe ìwọ́de yìí ní nǹkan bíì aago mẹ́wàá kọjá ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀dógún ni àwọn kan àwọn jàǹdùkú kan ní agbègbè Apata níbi tí wọ́n ti ń gbèrò láti ṣe ìkọlù sí ṣọ́ọ̀bù àti àwọn ènìyàn agbègbè náà.

Ó ní bí àwọn jàǹdùkú ọ̀hún ṣe rí ọkọ̀ àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò yìí ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní da ìbọn bolẹ̀, ju òkúta àti àwọn nǹkan ìjà olóró mìíràn sí àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò yìí.

Ó fi kun pé àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò náà rò ó wí pé tí àwọn náà bá ní kí àwọn ṣe ìkọlù sí àwọn jàǹdùkú yìí, ó ṣeéṣe kí nǹkan tó máa bàjẹ́ pọ̀ púpọ̀ nítorí náà ni wọ́n ṣe gbìyànjú láti ri pé àwọn gba àkóso àdúgbò náà.

Osifefo tún ṣàlàyé pé lásìkò tí ìkọlù ọ̀hún ènìyàn kan tó jẹ́ òṣìṣẹ́ fijilanté paàdánù ẹ̀mí rẹ̀ tí wọ́n sì ti gbe lọ sí yàrá ìgbókùúpamọ́sí fún àyẹ̀wò.

Bákan náà ló fi kun pé gbogbo nǹkan ti padà bọ̀ sípò ní agbègbè náà tí àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò sì wà ní sẹpẹ́ láti ri pé ààbò tó péye wà ní agbègbè náà.

Ó ní kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ti wá darí ẹ̀ka tó ń mójútó ìwà ọ̀daràn láti ṣèwádìí ohun tó ṣelẹ̀ gan kí wọ́n sì jáb[ọ̀ ní kòpẹ́kòpẹ́.

Osifeso fi kun pé ní kété tí àwọn bá ti ní ohunkóhun tó yẹ kíará ìlú mọ̀ ni àwọn máa fi léde kíá.

Ìgboro dàrú nítorí ìwọ́de nílùú Ibadan lórí ọ̀wọ́ngógó owó Naira

Awọn eeyan n jo taya ọkọ

Ọgọrọ awọn ọdọ to n ṣe ifẹhonuhan lori ilu ti ko fi ara rọ lo bẹrẹ iwọde l’ọwurọ oni bẹrẹ lati agbegbe Iwo Road lọ si Gate titi ti o fi de Secretariat.

Ariwo ti wọn mu bọ ẹnu ni pe aisi owo ati ọwọngogo epo bẹntiro ti mu ọpọlọpọ inira ba awọn ara ilu. Bẹẹ sini wọn ke si ijọba ati awọn ẹni ọrọ kan lati wa ojutu si tita riro to n ba awọn ọmọ Naijiria finra.

Awọn oluwọde

Nigba ti awọn to n ṣe ifẹhonuhan naa yoo fi de agbegbe Gate ni awọn janduku to darapọ mọ wọn bẹrẹ sini sọṣẹ.

Wọn ṣe ikọlu si agọ Ọlọpaa ati ile ifowopamọ Wema to n bẹ ni Gate.

Bi wọn ṣe n ko ẹru ni agọ Ọlọpaa naa ni wọn fi ọwọ kọ awọn nnkan ti wọn le gbe ni ile ifowopamọ naa.

Awọn oluwọde kan

Lẹyin eyii ni wọn wọ lọ Secretariat ni ẹnu iloro ọfisi Gomina ipinlẹ Ọyọ ti wọn si dana tun taya nibẹ.

Gbogbo ọkọ to n lọ to n bọ ni awọn adugbo naa ni awọn to n fi ẹhonu han ja ewe si ni iwaju.

Aworan awọn akẹkọọ pẹlu ewe lori ọkada

Rogbodiyan yii si ti da ọpọlọpọ sun kẹrẹ fa kẹrẹ silẹ bẹrẹ lati agbegbe Gate titi ti o fi de ọna Mọkọla si Dugbẹ.

Nibayii, awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ologun ati ẹṣọ abo Amọtẹkun ti wa ni awọn ikorita ti iṣẹlẹ naa ti waye.