Ọ̀pọ̀ owó Naira tuntun ń bẹ lọ́wọ́ àwọn agbébọn, yẹ̀yẹ́ ni wọn ń fi Emefiele ṣe – Gumi

Owo Naira tuntun atawọn agbebọn

Oríṣun àwòrán, Screen shot

Àyípadà Naira kò tu irun kan lára àwọn agbébọn, wọ́n ti láǹfààní sí owó tuntun lọ́pọ̀ yanturu

Gbajugbaja onimọ nipa ẹsin Islam kan, ẹni ti ẹnu kii sin lara rẹ lori ibasepọ rẹ pẹlu awọn agbebọn, Sheik Ahmad Gumi ti sọrọ lori ayipada owo naira ilẹ wa tijọba apapọ se.

Gumi, lasiko to n ba iwe iroyin Punch fọrọ werọ salaye pe ofo ọjọ keji ọja ni aayan banki apapọ ilẹ wa lati sayipada owo naira si tuntun lọna ati dena iwa ijinigbe.

Bakan naa lo fikun pe awọn agbebọn yii ti ni anfaani to pọ si awọn owo naira tuntun yii, igbesẹ ijọba lati da wọn lẹkun lati ipasẹ atunse owo Naira ko si ni itumọ kankan si wọn.

“Awọn eeyan tẹ n pe ni agbesunmọ yii ni awọn ohun kan ti wọn n fi ẹhonu han le lori ni, bẹ se wa se ayipada owo naira nitori wọn, ko le mu eso rere kankan jade.”

Agbebọn ati owo Naira tuntun

Oríṣun àwòrán, CBN

“Buhari ti di ẹni ikorira lojiji tori atunse naira tuntun to se”

Gumi ni yẹyẹ lasan ni awọn agbebọn yii n fi gomina banki apapọ ilẹ wa, CBN, Godwin Emefiele se ninu fidio kan ti wọn gbe sita lori ayelujara, nibi ti wọn ti patẹ owo tuntun naa.

“Mo wa lara awọn eeyan to kọkọ tako gbedeke ipari osu January ti banki apapọ ilẹ wa kede lati paarọ owo naira atijọ si tuntun, mo si mọ pe wọn yoo sun siwaju.

Lootọ ni ijọba ni awọn eto to dara amọ ọna ti wọn n gba se amusẹ awn eto naa lo lọju pọ, wọn kii ronu jinlẹ ki wọn to kede awn eto naa.

Wahala nla ni ko ba waye ka ni CBN ko sun ọjọ pasipaarọ Naira atijọ si tuntun ni, ẹ wo bi Buhari se di ẹni ikorira lojiji ni Kano, tawọn eeyan si ti kẹyin si.

O jẹ ohun to ba ni ninujẹ pupọ nitori lorilẹede Sudan, afikun owo burẹdi lasan lo bi ijọba ibẹ wo nitori ounjẹ igbọkanle awọn araalu ni.

Nilẹ yii, ibẹru ati ibanujẹ ti gba ọkan awọn araalu, wọn yoo si kẹyin sijọba, nitori naa, ko yẹ kijọba maa fi ọwọ yẹpẹrẹ mu awọn araalu.”

Ki lo wa ninu fidio tawọn agbebọn ti tẹ pẹpẹ owo Naira tuntun?

Nigba to n se atupalẹ awọn ohun to wa ninu fidio tawọn agbebọn gbe sita, Gumi ni se ni awọn agbebọn naa tẹ pẹpẹ ọpọ owo tuntun silẹ ninu fidio naa.

“Wọ́n wa bẹrẹ si ni fi banki apapọ ilẹ wa se yẹyẹ, ti wọn si n ni owo tuntun yin ree o.

Awọn eeyan yii le gbe ẹnikẹni to ba wu wọn, ki wọn si gba owo naira tuntun lọwọ rẹ tabi ki wọn gba owo ilẹ okeere.

To ba wa jẹ pe nitori awọn agbebọn yii ni wọn se se ayipada owo Naira, asan lo ja si.”