Wo ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀bẹ́rẹ̀ nílùú Eko tó ń gba N42m lórí ọmọ kan lọ́dún

Aworan ile ẹkọ Charterhouse l'Eko

Oríṣun àwòrán, Charterhouse Lagos/X

Ṣe ẹyin ti gbọ nipa ile ẹkọ alakọbẹrẹ tawọn obi ti n san miliọnu mejilelogoji naira lori ọmọ kan ṣoṣo lọdun gẹgẹ bi owo ile iwe.

Ẹ maa laagun jina, ile ẹkọ Charterhouse to kalẹ si ilu lagbegbe Lekki ti kede pe N42m lawọn obi yoo maa san lori ọmọ kan ti ile ẹkọ naa ba di ṣiṣi loṣu Kẹsan an ọdun yii.

Ọpọ ọmọ Naijiria lo ti n fi ẹhonu wọn han lori ayelujara lori owo gọbọi tawọn obi yoo maa san nile ẹkọ naa.

Lẹyin N42m owo ile iwe, awọn obi yoo tun san miliọnu meji fun iforukọsilẹ, eleyii ti wọn o le rigba pada mọ.

Ọpọ eeyan lo sọ pe owo naa ti pọju fun ẹnikẹni lati maa san fun ọmọ kan ṣoṣo pẹlu bi nnkan ṣe ri lorilẹede Naijiria bayii.

Amọ, ninu ọrọ rẹ, Damilola Olatunbosun, to jẹ adari ẹka ibaraẹnisọrọ ati igbaniwọle sile ẹkọ Charterhouse ṣalaye pe ile ẹkọ naa kii kan an ṣe ile ẹkọ lasan.

Olatubosun ni ile ẹkọ to lamilaaka ti muṣemuṣe rẹ si da muṣemuṣe ni ile ẹkọ Charterhouse eyi to gbaju gbaja kaakiri agbaye.

Olatubosun sọ fun iwe iroyin Tribune pe ‘’ile ẹkọ Charterhouse jẹ ile ẹkọ tawọn obi to ba riri eto ẹkọ to muna doko maa fẹ lati mu ọmọ wọn lọ tori ọlọtọ ni toun ọtọ ni.

O ṣalaye pe ọpọ awọn obi lo ti gbe igbesẹ lati mu ọmọ wọn wa si ile ẹkọ naa tori wọn mọ pe ile ẹkọ to gbọrẹgẹjigẹ ni.

Koda, N42m yii gan an ko jọ wọn loju lati san tori owo ti wọn le san ni.

Awọn kan ninu awọn obi yii wa ni Naijiria, nigba tawọn mii n gbe loke okun.

Wọn mọ riri iru eto ẹkọ tawọn ọmọ wọn yoo jẹ anfani rẹ ni ile ẹkọ Charterhouse.

Ọrọ kii ṣe nipa bo ya owo ẹkọ naa wọn tabi ko wọn, ṣugbọn o nii ṣe pẹlu didara eto ẹkọ tawọn akẹkọọ yoo jẹ anfani rẹ.

Iru awọn obi to n mu ọmọ wọn wa si ile ẹkọ Charterhouse ti mọ pe owo tawọn maa na maa pọju N42m lọ ti wọn ba fẹ ran awọn ọmọ wọn lọ sile ẹkọ loke okun.

Bo tilẹ jẹ pe, a ko tii kọ gbogbo yara igbẹkọọ tan wa tan, mo le sọ pe ko si ile ẹkọ ni Naijiria to ni awọn ohun elo ikẹkọọ ati awọn ohun amayedẹrun to wa ni ile ẹkọ Charterhouse.

Ko si iyatọ laarin ile ẹkọ Charterhouse atawọn ile ẹkọ to lamilaaka lorilẹede Uk.