Níbo lẹran màálú onímájèlé 50 kángun sí ní Ilorin lẹ́yìn tí ìjọba gbé ọjà ẹran Mandate tìpa?

Aworan maalu ni Ilorin

Lowurọ ọjọ Aiku ọjọ kọkanlelogun oṣu kinni yii ni iroyin gba igboro ilu Ilọrin ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Kwara kan pe, ẹran màlúù to ni majele ti wa ninu ọja Mandate ni Ilọrin.

Iroyin naa tun sọ pe kawọn èèyàn yago fun rira ẹran màlúù lọja naa.

Lasiko ti o n ba BBC Yoruba sọrọ lori Iṣẹlẹ náà, alaga ẹgbẹ awọn alapata ẹran màlúù lọja Mandate ní Ilọrin, Alhaji Anafi Teteji sọ pe, maluu awọn Fulani to n ta ẹran lo ku lojiji ti wọn si gbe mẹta wa sọdọ awọn nítori pe ọja Mandate kan naa lawọn jọ wa.

O fikun ọrọ rẹ pe ile isẹ ijọba to n ri si eto ilera ati ile isẹ ijọba to n ri si ọrọ ayika nipinlẹ Kwara ti wa gbe awọn maluu mẹtẹẹta naa ni ọdọ awọn laarọ ọjọ Aiku fun ayẹwo to peye.

Ninu ọrọ tiẹ, alaga ẹgbẹ awọn to n ta màlúù lọja Mandate, Abduraseed Ọlatunji ṣalaye pe, màlúù awọn mẹtalelaadọta lo ku lasiko ti awọn da wọn lọ jẹ oko.

O fikun pe, ṣe lo dabi pe, wọn jẹ majele nibi ti wọn ti n jẹ koríko.

Ọgbẹni Olatunji sọ pe awọn gbe diẹ lọ ọdọ awọn alapata lati ba awọn ta ninu awọn maalu naa nítori pe awọn osisẹ ile isẹ eto ọgbin to n mojuto ohun ọsin ti wa wo ẹran náà, wọn si ni o ṣee jẹ.

Ẹwẹ, Kọmisona feto ọgbin ni ipinlẹ Kwara, Arabirin Thomas Adebayo ṣalaye pe, awọn ti lọ inu ọja naa lati ko awon ẹran naa.

Ninu ọrọ tiẹ Kọmisona feto ìlera, Dokita Aminat El-Imam ni ijọba ti gbe ọja ẹran naa tipa títí di Ọjọru pẹlu alaye pe iwadii ti bẹrẹ lori Iṣẹlẹ náà.

Kọmisona ni ijọba ti ko awọn ẹran naa lọ si ibudo ayẹwo fun iwadi lẹkunrẹrẹ.