Wo ìdí tí wọ́n fi n pé ayájọ́ ọjọ́ ‘Good Friday’ ní orúkọ náà

Ere bi wọn se kan Jesu mọ igi agbelebu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọdún Ajinde yìí ni àwon ọmọlẹyìn Kristi jakejado àgbáyé máa n ṣe ìrántí ikú ati ajinde Jesu Kristi.

Ni ibẹrẹ pẹpẹ ẹṣin Kristẹni, awọn onigbagbọ máa n ya ọjọ náà sọtọ gẹgẹ bíi ọjọ ibanujẹ, ọjọ ọfọ, ọjọ ironupiwada ati ọjọ awẹ.

Ọjọ yii si ni wọn maa n pe ni ọjọ Ẹ́ti rere lode oni, koda, ọpọ Kristiẹni kii jẹ ohun abẹmi to jẹ ẹlẹjẹ ni iru ayajọ oni lati sami ati iya nla iku Jesu lori igi agbelebu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Fun ọdun 2021, oni yii, tíì ṣe ọjọ Keji, oṣù Kẹrin ni ọjọ Ẹti rere fun ọdun yii bọ si, ti wọn n pe ni Good Friday.

Ere bi wọn se kan Jesu mọ igi agbelebu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Bó tilẹ jẹ pé ọjọ ọfọ ati ìbànújẹ ni ọjọ náà jẹ ninu itan ẹṣin onígbàgbọ, amọ ọjọ náà ló jẹ òpin ọsẹ to se pataki julọ ninu itan Kristẹni.

Ọsẹ yii ni wọn maa n pe ni ọsẹ ikaanu fun ijiya ati iku Jesu Kristi.

Ìgbàgbọ àwọn Kristẹni ni pé, ọjọ Ẹtì náà ni Jesu ku lórí igi agbelebu, to sí ko ẹsẹ gbogbo araye lọ, ko to di pe o ji dide pada ni ọjọ kẹta.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ki lo de ti wọn se n pe ayajọ oni ni Good Friday?

Ṣugbọn ki lo de ti wọn fi n pé ọjọ náà ni Good Friday, ìyẹn ọjọ Ẹtì rere, dipo ọjọ ibanujẹ ti ọjọ náà jẹ?

Àlùfáà Mike Schmitz ni lootọ lo jẹ ọjọ ibanujẹ, ṣugbọn ni ida keji ẹwẹ, ọjọ ayọ ni ọjọ náà nítorí pé ọjọ ọhun gan ni Jésù ko ẹsẹ arayé lọ lori igi agbelebu.

O ni awọn onígbàgbọ́ máa n ri ọjọ náà bíi ọjọ ti Ọlọrun ko ẹsẹ arayé lọ, to si dari ẹsẹ jin gbogbo èèyàn labẹ ore ọfẹ Jesu.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Àlùfáà náà parí ọrọ rẹ pé, agbelebu nìkan ni idahun sí gbogbo ìbéèrè awọn Kristẹni lórí gbogbo ìṣòro tí wọn bá gbé tọ Ọlọrun wa.

Eredi ree ti ọjọ Good Friday yii se jẹ ọjọ ayọ fun onígbàgbọ bo tilẹ jẹ pé ọjọ burúkú ni ọjọ náà nínú ìtàn ẹṣin Kristẹni káàkiri àgbáyé.

BBC Yoruba wa n ki awọn ọmọlẹyin Kristi lagbaye ku ọdun ọjọ Ẹti rere, ta si n gbadura pe a se pupọ rẹ nile aye.