Ọba tó wà lára àwọn afurasí tí wọ́n n wa lórí ikú àwọn sọ́jà nípìnlẹ̀ Delta fa ara rẹ̀ kalẹ̀

CLEMENT IKOLO

Oríṣun àwòrán, FREDRICKNWABUFO/CLEMENT IKOLO/FACEBOOK

Kabiyesi ilu Ewu, nipinlẹ Delta, Ọba Clement Ikolo tawọn ṣọja kede rẹ pe awọn n wa lori iku ọmọ ogun mẹtadinlogun to waye ni Okuama, ti lọọ fa ara rẹ kalẹ fawọn ọlọpaa bayii.

Nnkan bii aago meje alẹ́ ku iṣẹju mọkandinlogun l’Ọjọbọ, ọjọ kejidinlọgbọn oṣu Kẹta, 2024, ni ọba Ikolo, wọ olu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Delta.

Kọmiṣanna ọlọpaa Delta, Olufẹmi Abaniwọnda ni Ọba Clement Ikolo wọle tọ, to si ṣalaye fun un pe oun tawọn ṣọja n wa ree.

Ṣaaju ko too jọ̀wọ́ ara rẹ f’’ọlọpaa ni Kabiyesi ilu Ewu ti kọkọ ba awọn akọroyin sọrọ.

O tẹpẹlẹ mọ ọn pe oun ko mọwọ-mẹsẹ nipa iku awọn ologun mẹtadinlogun naa.

Bright Edafe, Alukoro ọlọpaa Delta, fidi rẹ mulẹ pe, Clement Ikolo, ti wa ni akata ọlọpaa ipinlẹ Delta.

Tẹ o ba gbagbe, owurọ Ọjọbọ naa ni ileeṣẹ ologun Naijiria kede eeyan mẹjọ ti wọn n wa lori iku awọn ṣọja mẹtadinlogun ọhun. Wọn ni wọn mọ nipa rẹ.

Lara wọn ni ọba to fa ara rẹ fọlọpaa yii, awọn meje yooku ni : Ọjọgbọn Ekpekpo Arthur, Andaowei Dennis Bakriri, Akevwru Daniel Omotegbo ati Akata Malawa David.

Awọn yooku ni Sinclear Oliki; Oghenerukeywe; Reuben Baru, ati Igoli Ebi.