Tinubu gbé ìgbìmọ̀ tí yóò mójútó ètò ọrọ̀ ajé Nàìjíríà dìde

Aworan aarẹ Tinubu

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK/BOLA TINUBU

Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Bola Tinubu ti gbé ìgbìmọ̀ kan dìde láti wá ojútùú sí ètò ọrọ̀ ajé Nàìjíríà tó dẹnu kọlẹ̀.

Níṣe ni gbogbo nǹkan ń gbówó lórí pàápàá oúnjẹ àti èpò, bẹ́ẹ̀ ọ̀pọ̀ òṣìṣẹ́ ń tiraka nítorí owó oṣù wọn kò ká nǹkan tí wọ́n ń fowó rà.

Ètò ọrọ̀ ajé to dẹnu kọlẹ̀ yìí ti mú kí ìgbé ayé nira fún ọ̀pọ̀ mẹ̀kúnnù tí àwọn ènìyàn sì ń ké sí Ààrẹ láti wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi ṣàdá lórí ìṣòro náà.

Lára ohun tí àwọn èèyàn ń tọ́ka sí pé ó fa ìṣòro yìí ni bí ìjọba ṣe yọ ìrànwọ́ orí epo bẹntiróòlù àti bi owó náírà ṣe ń já wálẹ̀ sí owó dọ́là.

Àmọ́ àwọn aláṣẹ ní ṣíṣe àtúntò ètò ọrọ̀ ajé jẹ́ ọ̀nà kan gbòógì láti mú kí ètò ọrọ̀ ajé Nàìjíríà gbòòrò si lọ́jọ́ iwájú.

Èyí ló mú kí Ààrẹ gbé ìgbìmọ̀ dìde láti wá ojútùú sí ìṣòro náà àti pé wọ́n gbọ́dọ̀ jábọ̀ fún òun lórí àwọn ìgbésẹ̀ tó bá yẹ láàárín ọ̀sẹ̀ méjì.

Ààrẹ ní ohun tí ìjábọ̀ wọn bá dá lé lórí ni àwọn fi máa ṣe ìgbésẹ̀ ọrọ̀ ajé fún oṣù mẹ́fà.

Lára ìgbìmọ̀ náà ni èyí tí wọ́n pè ní Presidential Economic Coordination Council tí Ààrẹ jẹ́ alága rẹ̀.

Lára àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ náà ni igbákejì Ààrẹ, Kashim Shettima, ààrẹ ilé aṣòfin àgbà, Godswill Akpabio, alága àwọn gómìnà Nàìjíríà àtàwọn mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n míì.

Àtẹ̀jáde kan tí Agbẹnusọ Ààrẹ, Ajuri Ngelale fi léde ní ìgbésẹ̀ Ààrẹ náà wáyé láti ṣe àtúntò ètò ajé Nàìjíríà.

Ìgbìmọ̀ tí wọ́n gbé dìde náà tún ní àfikún èèyàn mọ́kàndínlógún lẹ́ka aládàni tí wọ́n máa ṣiṣẹ́ fún ọdún kan.

Ìgbìmọ̀ àwọn ẹ̀ka aládàni tí wọ́n pè orúkọ rẹ̀ ní Economic Management Team Emergency Taskforce jẹ́ èyí tí ìgbìmọ̀ aláṣẹ ìjọba àpapọ̀ buwọ́lu lọ́jọ́ Ajé.

Lára àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ tí ẹ̀ka aládàni náà ni alága iléeṣẹ́ Dangote Group, Aliko Dangote, alága ilé ìfowópamọ́ UBA, Tony Elumelu, olùdásílẹ̀ iléeṣẹ́ BUA, Abdulsamad Rabiu àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.