Fá irungbọ̀n rẹ, kòó forí kó ìyà lọ́wọ́ ìjọba Afghnistan – Taliban

Ile gẹri-gẹri ni Aghanistan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

O ti di ewọ bayii lati maa fa irugbọn lorilẹede Afghanistan, ijọba Taliban lo sọ bẹẹ.

Ijọba Taliban ti kilọ fawọn gẹrigẹri lẹkun Helmand pe wọn ko gbọdọ fa irugbọn fun ẹnikan kan mọ.

Taliban sọ pe eyi ṣe ilodi si ilana ofin Islam, ati pe ijiya to tọ ti wa fun ẹnikẹni to ba tapa si ikede ijọba yii.

Awọn ọlọpaa Taliban ti wa nilẹ lati maa da ṣeria fun ẹnikẹni to ba tapa si ofin ti ijọba gbe kalẹ yii.

Awọn gẹri-gẹri kan to wa ni olu ilu Afghanistan, Kabul naa ti sọ pe awọn ti gba aṣẹ yii lati ọdọ ijọba.

Igbesẹ yii tọka si pipa si ọna ti awọn Taliban fi ṣe ijọba wọn tẹlẹ lorilẹede naa bo tilẹ jẹ pe wọn ṣeleri lati ma mu aye le fawọn eeyan.

Ijọba Taliban ti bẹrẹ si ni fi ọwọ lile mawọn alatako lẹyin ti wọn gba ijọba loṣu to lọ.

Ileeṣẹ gẹri-gẹri ni Afghanistan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lọjọ Abamẹta ni wọn pa awọn afurasi ajinigbe mẹrin ti wọn si so oku wọn rọ lopopona Herat.

Awọn ọlọpaa ijọba Taliban ti lẹ ikilọ si awọn ile gẹri-gẹri ni ẹkun Helmand pe wọn gbọdọ maa tẹle ofin Sharia lori irun gigẹ ati irugbọn fifa.

Wọn sọ ninu ikilọ pe ko si aye fun awawi kankan lati ọdọ awọn gẹri-gẹri lori ọrọ yii.

Baba kan niluu Kabul sọ pe niṣe lawọn ọlọpaa Taliban n ṣọ awọn lọwọ lẹsẹ lati ti pe awọn tẹle ofin ti wọn ṣe agbekalẹ rẹ ni tipa tipa.

Lasiko ijọba Taliban laarin ọfdun 1996 si 2001, ijọba ko faye gba kawọn eeyan maa ṣe irun to ba wu wọn.

Ẹnikẹni ko gbọdọ ge irugbọn rẹ tabi rẹẹ silẹ rara lasiko ijọba Taliban nigba naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ