Ọmọ ààrẹ nígbà kan di èrò ẹ̀wọ̀n l’Amerika fún gbígbé òògun olóró

Aworan Malam Bacai Sanha Jr

Oríṣun àwòrán, AFP

Ọmọ Aarẹ tẹlẹri lorilẹede Guinea-Bissau ni Ile ẹjọ kan lorilẹede Amẹrika ti ni ko lọ ma gba atẹgun lọgba ẹwọn fun ọdun mẹfa nitori ẹsun pe o jẹ olori ẹgbẹ to n gbe ogun oloro.

Malam Bacai Sanha Jr, ẹni ọdun mejileladọta lo n gbero lati lo owo to ba ri nibi gbigbe ogun oloro lati fi di Aarẹ Guinea- Bissau nipasẹ iditẹgbajọba.

Oun ni ọmọ Malam Bacia Sanha, ẹni to jẹ aarẹ orilẹede Guinea Bissau lati ọdun 2009 titi to fi jade laye ni ọdun 2012.

Sabha Jr ni wọn ni o lọwọ ninu iditẹgbajọba to foriṣanpọ́n ninu oṣu Keji, ọdun 2022.

Wọn gbe e lọ si Amẹrika ninu oṣu Kẹjọ ọdun 2022 lẹyin ti ọwọ tẹ ẹ ni Tanzania.

Igbẹjọ lori ẹsun naa bẹrẹ, to si sọ fun ile ẹjọ ninu oṣu kẹsan-an pe oun jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun.

“Malam Bacai Sanha ki ṣe eeyan lasan ti a ba n sọrọ nipa gbigbe ogun oloro.” Osisẹ ọtẹlẹmuyẹ, Douglas Williams sọ fun lọjọ Isẹgun.

“O jẹ ọmọ Aarẹ tẹlẹ lotilẹede Guinea Bissau, to si n gbe ogun oloro fun idi kan- lati le kowo jọ ṣe iditẹgbajọba eyi ti yoo sọ di Aarẹ orilẹede naa, nibi to fẹ fi ṣe ibudo ogun oloro.”

Sanha Jr ni wọn fẹsun kan pe oun gbe ogun oloro wọle lati orilẹede bi Portugal ati awọn ilẹ Yoroopu mii wọle si Amẹrika.

Awọn alasẹ Amẹrika ni awọn fi ransẹ pada si ile lẹyin to ba lo akoko rẹ lọgba ẹwọn nitori ko ki n ṣe ọmọ ilẹ wọn.

Ẹni ọdun mejilelaadọta yii ni ọpọ mọ si “Bacaizinho” ni Guinea Bissau, to si di ipo to lagbara mu ninu ijọba, to fi mọ, olubadamọran nipa ọrọ aje fun Baba rẹ.

Sanha jẹwọ fun awọn osisẹ DEA to n ri si ogun oloro ni Amẹrika pe oun n lo owo ti oun ba ri nibi okowo ogun oloro lati kun ọwọ awọn ti yoo ranlọwọ lati ditẹgbajọba