Tinubu, àkókò tó fún Yoruba láti kúrò lára Naijiria – Igboho, Akintoye

Igboho and Akintoye

Oríṣun àwòrán, Igboho/Akintoye

Awọn aṣaaju ẹgbẹ Yoruba Nation, Ọjọgbọn Banji Akintoye ati Oloye Sunday ‘Igboho’ Adeyemo ti kọ lẹta si Aarẹ Bola Tinubu pe ko gba ilẹ Yoruba laaye lati yapa kuro lara Naijiria.

Lẹta ọhun, ti wọn kọ lọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii ni Akintoye, Igboho ati Ola Ademola buwọlu.

Wọn ke si Tinubu pe ko gbe igbimọ kan kalẹ ti yoo jiroro lori bi Yoruba yoo ṣe fi Naijiria silẹ.

Iwe atẹjiṣe yii lo n jade lẹyin ọsẹ kan ti awọn kan ti wọn pe ara wọn naa ni ọmọ ẹgbẹ Yoruba Nation kọlu ọọfisi ijọba ipinlẹ Oyo, ki ọwọ awọn agbofinro to tẹ wọn.

Awọn ajijagbara naa, ti iye wọn to mọkandinlọgbọn ti foju bale ẹjọ ti adajọ si ni ki wọn ṣi maa lọ gba atẹgun ninu ẹwọn fun akoko diẹ na.

Ki lo wa ninu lẹta Akintoye ati Igboho?

Ninu lẹta ọhun ni awọn ajijagbara fun ominira ilẹ Yoruba naa ti sọ pe awọn ko fẹ atunto Naijiria, bi ko ṣe ki Yoiruba yapa.

Wọn ni “Ọlọla julọ, inu wa dun lati kọ lẹta yii lorukọ ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu ọmọ Yoruba kaakiri agbaye.

“A n fi lẹta yii sọwọ si yin lẹyin eyii ti a kọkọ fi ranṣe lọjọ kẹfa, oṣu Kẹjọ, ọdun 2022, eyii ti a fun aṣaaju yin, Aarẹ Muhammadu Buhari, to jẹ Aarẹ Naijiria nigba naa.

“Lati ọdun 2015 ni awọn darandaran ti n ṣekupa awọn eeyan ni Najiria, lara awọn ti wọn si n pa ni ipakupa ni awa Yoruba wa, wọn n ba ere oko jẹ, wọn n kọlu awọn abule wa, bẹẹ ni wọn n ji awọn obinrin atawọn ọmọ wẹwẹ gbe lati gba owo gọbọi, eyii ti wọn fi n sọ ilẹ Naijiria di ti ara wọn nikan.”

Lẹta naa tẹsiwaju pe awọn ọdaran darandaran ọhun ti ṣekupa ọpọ eeyan ni aringbungbun Naijiria, ti wọn si gba ilẹ awọn eeyan ọhun gẹgẹ bii tiwọn.

“Nilẹ Yoruba to jẹ tiwa, ojojumọ lawọn darandaran n paayan ti wọn si n ji awọn eeyan gbe, eyii to ti mu ki ọpọ araalu fi oko wọn silẹ to si n mu iyan ba awọn eeyna wa.

“Awọn iwa tawọn darandaran yii n wu jẹ eredi pataki fun wa lati sọ pe a fẹ yapa kuro lara Naijiria ki a si ni orilẹede tiwa to da duro.

“A ko fẹ atunto Naijiria”

“Ọpọ awọ ọmọ Yoruba ni ko ni ireti kankan ninu atunto ti awọn ọmọ Yoruba kan bii awọn baba wa ninu ẹgbẹ Afenifere n bere fun.

“Eredi ni pe a mọ pe atunto ko ni di awọn ọdaran darandaran lọwọ ninu ikọlu wọn si wa nitori ọmọ Naijiria ni wọn, wọn si ni ẹtọ lati lọ sibikibi to ba wu wọn lorilẹede wọn.

Akintoye ati Igboho sọ pe ko din ni ẹgbẹrun mọkandinlọgbọn ọmọ Yoruba ti awọn darandaran ti ṣekupa laitọjọ.

Akoko si ti to fun Aarẹ lati gbe igbimọ dide ti yoo jiroro lori bi Yoruba ṣe maa yapa kuro lara Naijria.