Wo ìgbésẹ̀ tí Toyin Abraham gbé bí ìjà láti di ẹni àkọ́kọ́ lágbo tíátà ṣe ń wáyé láàrín àwọn òṣèré

Aworan Funke Akindele, Toyin Abraham ati Mercy Aigbe

Oríṣun àwòrán, Instagram /Toyin Abraham

Gbajugbaja oṣere tiata, Toyin Abraham bọ sori ayelujara lati kan awọn akẹgbẹ rẹ meji, Funke Akindele ati Mercy Aigbe, to si pe fun ajọsepọ alaafia ninu agbo Nollywood.

Abraham ni asiko ti to fun awọn lati gbe ara wọn larugẹ, ki wọn si yago fun ikorira ara wọn tabi fifi ẹgbẹkẹgbẹ ni ọna ti ko ni alaafia.

“A nilo lati gbe ilana lati se iwuri fun ara wa eyi ti yoo fun wa ni anfani lati ni ọpọlọpọ awọn olorire eeyan.”

Bakan naa, Abraham ni otitọ ni pe asiko kan ti ikorira wa laarin oun ati Funke Akindele eyi to fa iyapa laarin awọn ololufẹ wọn.

“Ti ẹ ba mọ ija to wa ninu pe a fẹ di ẹni akọkọ lagbo ere sinima, o fa ọta, oniruuru igun ati ọpọlọpọ ofofo”

Ninu ọrọ rẹ, o ranti awọn iriri to ni nigba to bẹrẹ si ni ṣe sinima, to si ni ọpọlọpọ ọrọ ẹyin, ofofo lo pọju lagbo ere sinima nigba naa.

“Ti ẹ ba mọ ija to wa ninu pe a fẹ di ẹni akọkọ lagbo ere sinima. Ija yii fa ọta, igun ati ọpọlọpọ ofofo.

“Nigba naa, Funke Akindele ni ẹni akọkọ lẹyin awọn eeyan bi Aunty Bukky ati Aunty Faithia.

Mo wa lori ila naa. Idije naa pọ pẹlu ofofo ati ọrọ ẹyin, ti a si di ọta ara wa.”

“Aṣeyọri Funke Akindele jẹ ohun iwuri fun mi pupọ”

Ninu alaye rẹ, Toyin Abraham kan sara si aṣeyọri ti fimmu Funke Akindele ṣe eyi to fi pa apapọ owo toto N1B.

O ni aṣeyọri yii jẹ ki oun naa ni erongba lati pinnu pe oun fẹ ṣe irufẹ orire naa.

Toyin Abraham ni o se koko kí awọn ṣe iranlọwọ fun ara wọn pẹlu bi idije ṣe wa laarin wọn.

“Pẹlu bi ọlaju ṣe gbode, mo ti wa ri pe a le ran ara wa lọwọ lai ro pe idije wa laarin wa. Aunty Funke, mo kan sara si yin bi ẹ ṣe fi ọna ran wa. Olubori ni yín. O ta sinima to le ni 1BN, o jẹ ko ṣeeṣe fun awọn obinrin lati le gbero nla.

“A dupẹ fun awọn sinima ti o n gbe síta, ti ẹ si n ta bi pe oun ni ẹmi yin. Ẹ kọ awọn obinrin lati ma ṣeeṣe ọlẹ.

“Emi naa ni awọn aṣeyọri lori Box Office sugbọn gbogbo ẹ ní Aunty tí fidi mi hàn ẹ; lonii, inu mi dun nitori o jẹ ki sun sokoto mi lati tun gbinyanju.”

Skip Instagram post, 1

Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose ‘accept and continue’.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post, 1

Content is not available

View content on InstagramBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

“Mercy Aigbe jẹ ẹni iwuri fun gbogbo obìnrin”

Bakan naa ni Toyin Abraham tun kan sara si Mercy Aigbe fun bí o ṣe awokọse rere fun gbogbo obìnrin lagbo Nollywood.

“Ọpọlọpọ obìnrin lo jẹ ohun iwuri fun. O ṣeun fun bí o ṣe n kọ itan nla fun awọn obinrin nigba ti agbaye n kọ itan miiran.

Nigba to fesi pada, Funke Akindele ati Mercy Aigbe fi ifẹ han si Toyin Abraham ti wọn si dupẹ lọwọ fun ifẹ to fihan si wọn.

Skip Instagram post, 2

Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose ‘accept and continue’.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post, 2

Content is not available

View content on InstagramBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.