Ta ni Aigboje Aig-Imoukhuede tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn sípò alága níléeṣẹ́ Access Holdings Limited?

Access Bank

Oríṣun àwòrán, Access Bank

Ileeṣẹ Acees Holdings PLC, to ni ile ifowopamọ Access Bank ti yan Aigboje Aig-Imoukhuede gẹgẹ bii alaga rẹ tuntun.

Aig-Imoukhuede lo gba ipo naa lẹyin Abubakar Jimoh to wa nipo naa tẹlẹ.

Ileeṣẹ Access Holdings PLC lo gbe igbesẹ yii lẹyin iku ọga agba rẹ tẹlẹ, Herbert Wigwe, to di oloogbe.

Akọwe ileẹṣẹ naa, Sunday Ekwochi sọ ninu atẹjade kan pe “Access Holdings PLC ti kede ipadabọ Aigboje Aig-Imoukhuede to jẹ ọga agba akọkọ ni ileeṣẹ naa lẹyin ọdun mẹwaa.”

Iyansipo Aigboje Aig-Imoukhuede yii ni iyansipopo pataki keji ti yoo waye nileeṣẹ naa lẹyin iku Wigwe.

Ṣaaju ni wọn ti kọkọ yan Bolaji Agbede, gẹgẹ bii ọkan pataki lara awọn alaṣẹ, iyẹn Group Chief Executive Officer, fun ileeṣẹ ọhun.

Ta ni Herbert Wigwe, ọga agba Access Bank to di oloogbe?

Lati alẹ ọjọ kẹsan an oṣu keji ọdun 2024, ni orukọ ọga agba Access Bank, Herbert Wigwe, ti n tan kalẹ, paapaa lori ayelujara

Amọ pupọ ni ko mọ ohunkohun nipa ọkunrin naa, ju pe o jẹ ọga agba ọkan lara awọn banki to tobi julọ ni Naijriia.

Wigwe to ti fi igba kan jẹ igbakeji ọga agba banki naa, pada di ọga lọdun 2014 lẹyin ti oludokowo pọ rẹ, Aigboje Aig-Imoukhuede fi ipo naa silẹ lọdun 2014.

Ọdun 1966 ni wọn bi Herbert Onyewumbu Wigwe, niluu Port Harcourt, nipinlẹ rivers.

O gba oye imọ ijinlẹ akọkọ ninu iṣiro owo lati University of Naijiria, to w ani Nsukka nipinlẹ Enugu lọdun 1987.

O gba iwe ẹri keji ninu imọ nipa eto ile ifowopamọ ati iṣuna lọdun 1991, ni University College of North Wales, nipasẹ ẹkọ ọfẹ ti ijọba ilẹ Britain.

Lẹyin naa lo kawe nipa akoso ọrọ aje ni Fasiti ilu London.

Wigwe bẹrẹ iṣẹ oluṣiri owo nileeṣẹ Coopers & Lybrand, ko to o darapọ mọ ile ifowopamọ Guaranty Trust Bank nibi to ti ṣiṣẹ fun ọpọlọpọ ọdun.

Lọdun 2002, Ọgbẹni Wigwe ati ẹni ti wọn jọ n dokowo pọ, Aigbpje Aig-Imoukhuede, ra Access Bank.

Laarin ọdun 2002 si 2017, banki naa kuro ni ipo karundinlaadọrin ni Naijiria, si ipo kẹrin laarin awọn banki to tobi julọ.

Orukọ iyawo Wigwe ni Chizoba, wọn si bi ọmọ mẹrin funra wọn.