Ìjọba Ogun bẹ̀rẹ̀ fífún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti girama lẹ́gbẹ̀rún mẹ́wàá náírà

Kọmiṣanna lasiko to n ba awọn obi awọn akẹkọọ naa sọrọ

Oríṣun àwòrán, Ogun Govt

Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun ti bẹrẹ si i fun awọn akẹkọọ ileewe alakọọbẹrẹ ati girama to jẹ tijọba ni ẹgbẹrun mẹwaa naira.

Eto yii bẹrẹ l’Ọjọru, ọjọ kẹtala, oṣu kẹta ọdun 2024 yii, nigba ti awọn obi akẹkọọ ọgọrun-un kan (100 pupils) gba ẹbun owo ẹgbẹrun mẹwaa ẹnikọọkan.

Kaakiri ijọba ibilẹ ogun to wa nipinlẹ Ogun ni wọn ti mu awọn akẹkọọ naa, bẹrẹ lati alakọọbẹrẹ to fi de girama.

Nigba to n ṣalaye nipa eto naa lasiko ti wọn n pin owo ọhun, Kọmiṣanna eto ẹkọ, imọ ijinlẹ ati imọ ẹrọ nipinlẹ Ogun, Ọjọgbọn Abayọmi Arigbabu, sọ pe igbesẹ naa waye lati mu idẹra ba awọn obi, pẹlu bi nnkan ṣe lagbara lasiko yii ni Naijiria.

Arigbabu sọ pe awọn eeyan to ku diẹ kaato fun, ti nnkan ko dẹrun fun ninu awọn obi ni anfaani yii wa fun.

Pẹlu awọn ọmọ wọn ti wọn jẹ akẹkọọ nileewe alakọọbẹrẹ ati girama ijọba Ogun .

Bawo nijọba ṣe n da awọn ọmọ ti nnkan ko dẹrun fawọn obi wọn mọ?

Awọn obi awọn akẹkọọ ti wọn n fun lowo

Oríṣun àwòrán, Ogun govt

Awọn obi awọn akẹkọọ ti wọn n fun lowo

Oríṣun àwòrán, Ogun govt

Ọjọgbọn Arigbabu ṣalaye pe awọn olukọ to n kọ awọn akẹkọọ naa nileewe lo sunmọ wọn ju, wọn si mọ awọn ti irisi wọn ko wuyi rara.

O ni awọn akẹkọọ miran ko ni bata ti wọn le wọ wa sileewe, awọn mi-in ko niwee ti wọn yoo fi kọṣẹ, bẹẹ ni wọn o ni iwe kika.

Aṣọ ileewe awọn akẹkọọ mi-in ti gbo, awọn obi wọn ko rowo ra omi-in fun wọn.

Iru awọn wọnyi ni Arigbabu sọ pe o jẹ anfaani yii, pẹlu aṣayan awọn olukọ wọn.

Nipa bi wọn ṣe ri owo naa gba, Kọmiṣanna eto ẹkọ naa ṣalaye pe akanti awọn obi wọn nijọba sanwo si, nitori awọn akẹkọọ naa ṣi jẹ ọmọde ti ko lakanti .

‘’Gomina pinnu lati mu idẹkun ba awọn araalu nipa lilo ilana tuntun ni.

Dapọ Abiọdun gbagbọ pe ọna kan jẹ karaalu gbadun lasiko ti nnkan le yii ni lilo ẹka ẹkọ ati ilera.

Ko si si gomina to lo iru eyi ri’’

Bẹẹ l’Arigbabu wi.

Diẹ ninu awọn ileewe to janfaani yii ni, Baptist Boys High School (Junior),

Lisabi Grammar School, Idi-Aba, Ebenezer Baptist Nursery and Primary School, Saje, Abeokuta, Holy Prophets Primary School, Adedotun ati Agunbiade Victory High School, Magbon, Abẹokuta.

Awọn obi to janfaani naa fi idunnu wọn han, wọn dupẹ lọwọ Dapọ Abiọdun fun iranwọ ẹgbẹrun mẹwaa naira naa.

Tẹ o ba gbagbe, ọsẹ to kọja yii ni Gomina Abiọdun bẹrẹ si i fun awọn akẹkọọ ileewe giga nipinlẹ Ogun ni ẹgbẹrun lọna aadọta naira, ki nnkan le dẹrun fun wọn lasiko ọgbẹlẹ yii..