Fídíò, Ìyà ń jẹ wá nílé ìwé mi, orí ilẹ̀ là ń ti jókòó ṣe ìdánwò – Akẹ́kọ̀ọ́, Duration 3,35

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ẹyin lo n di akukọ, awọn ọmọde oni ni yoo dagba to ba di ọla nitori awọn ni asaaju lọjọ ọla.

Amọ o seni laanu pe ọpọ awọn ogo wẹẹrẹ yii lo n la ipọnju nla kọja nidi ilakaka wọn lati kawe, di eeyan pataki, ki wọn si jẹ asaaju rere lọjọ ọla.

Apẹẹrẹ ni ti ile ẹkọ alakọbẹrẹ LA to wa nilu Bolowo, ni ijọba ibilẹ Ese-Odo, nipinlẹ Ondo nibi ti awọn akẹkọọ ti n sun tabi joko sori ilẹ lasan lati kọ ẹkọ.

Koda nibi ti nnkan buru de, ko aga, tabili, olukọ to to atawọn eroja ikẹkọọ to yẹ, koda, awọn pako ti wọn fi kọ ileẹkọ naa lo ti ja.

Nigba ti BBC Yoruba se abẹwo sile ẹkọ naa, a ri ba awọn olukọ, akẹkọọ, ọga ileẹkọ ati oriade to wa nilu naa sọrọ, ti gbogbo wọn si n fi tẹdun-tẹdun sọ iya nla to n jẹ ile ẹkọ naa ati awọn akẹkọọ rẹ.

Bakan naa la kan si ileesẹ to wa fun eto ẹkọ nileesẹ ijọba ibilẹ Ondo lati mọ boya wọn mọ ipo ẹyin ti ile ẹkọ alakọbẹrẹ naa wa, ati ewu nla to n rọ lori awọn akẹkọọ ibẹ.

Oludari kan to ba wa sọrọ ni ijọba ti n gbe igbesẹ lati ri si atunse ile ẹkọ naa, laipẹ si ni isẹ atunse naa yoo bẹrk.