Iléẹjọ́ ní kí Dókítà Femi Olaleye máa gbà àtẹ̀gùn ni ọgbà ẹ̀wọ̀n lórí ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀

Dokita Femi Olaleye

Oríṣun àwòrán, Other

Ileẹjọ giga to n joko nipinlẹ Eko ti ni kí Dokita Femi Olaleye tí Optimal Cancer Care Foundation lọ máa gba atẹgun ni ọgba ẹwọn Ikoyi titi yoo fi le ṣe oun to tọ lati gba beeli.

Olaleye tí wọn fi ẹsun ifipabanilopọ ati jija ibale ọmọde kan to si ni oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun.

Ileeṣẹ ofin ijọba ipinlẹ Eko lo gbe dokita naa lọ sile ẹjọ, fun pe o fi ipa ba ọmọde lopọ fun bi oṣu mọkandinlogun, titi iyawo rẹ fi mọ, to si fi ẹjọ rẹ sun ijọba.

Olaleye sọ fun ileẹjọ pe oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun rara.

Irọ́ pátápátá ni gbogbo ẹ̀sùn ìfapábánilòpọ̀ tí wọ́n kà sí mi lọ́rùn o! – Dr Olaleye

Dókítà Femi Olaleye tí wọ́n fi ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀ àti jíjá ìbálé ọmọdé kan ti ní òun kò jẹ̀bi gbogbo ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan òun.

Dókítà Olaleye ló ń fi ọ̀rọ̀ yìí léde lẹ́yìn tó kọ̀ láti yọjú sílé ẹjọ́ láti jẹ́jọ́ lórí ẹ̀sùn náà.

Ó ní pé irọ́ tó jìnà sí òótọ́ ni gbogbo àwọn ìròyìn àti àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan òun àti pé ọ̀rọ̀ náà fẹ́ dàbí wí pé wọ́n fẹ́ mọ̀-ọ́n-mọ̀ kóbá òun ni.

Ẹ̀sùn wí pé Dókítà Olaleye fi tipátipá bá ọmọdé tó jẹ́ ọmọ ẹbí ìyàwó rẹ̀, tó sì tún gba ìbálé ọmọ náà ni dókítà ń kojú ni ó fèsì sí.

Nínú àtẹ̀jáde kan tó fi síta, ó ní àwọn ènìyàn ń gbé ìròyìn tí kì í ṣe òótọ̀ nípa òun àti ilé iṣẹ́ òun síta lórí ayélujára fún ìdí tí kò dára rárá.

Ó ní ojú kékeré ni òun fi ń wo ọ̀rọ̀ náà tẹ́lẹ̀ tí òun sì rò wí pé ọ̀rọ̀ kékeré tí òun àti ìyàwó òun kàn máa parí ní yàrá ni ọ̀rọ̀ náà ṣùgbọ́n ó dàbí wí pé àwọn fẹ́ lo ìyàwó òun láti da ilé àwọn rú.

Dókítà Olaleye fi kun pé láti inú oṣù Kọkànlá ọdún 2021 ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti bẹ̀rẹ̀ àmọ́ òun kò mọ̀ wí pé òun tí yóò padà lágbára báyìí ni.

Ó ní ní báyìí tí ìròyìn náà ti wà lórí ayélujára àti àwọn ẹ̀ka ìròyìn mìíràn, iṣẹ́ òun àti àwọn iléeṣẹ́ tí òun ń bá ní àjọṣepọ̀ ní ìròyìn náà ti ṣe àkóbá fún.

Onímọ̀ ìṣègùn òyìnbó náà láti ìgbà tí ọ̀rọ̀ náà ti ń rúgbó ni òun ti ń wá ọ̀nà láti pa iná rẹ̀ kí ìgbéyàwó ọdún mọ́kànlá òun àti ìyàwó òun má bá a dàrú.

Bákan náà ló ní òun ti ṣetán láti ti ẹsẹ̀ òfin bọ ọ̀rọ̀ náà nítorí ó hàn wí pé wọ́n fẹ́ mọ̀-ọ́n-mọ̀ ba òunní orúkọ jẹ́ ni.

Ó tẹ̀síwájú pé òun ti fi ọ̀rọ̀ náà tó àwọn aláṣẹ létí àti pé òun kò ní jẹ́ kí etí àwọn ènìyàn di sí ààbọ̀ ìwádìí àwọn aláṣẹ.

Dókítà Olaleye ní òun yóò fara balẹ̀ láti lọ wẹ ara òun mọ́ ní ilé ẹjọ́ láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wí pé òun kò mọ nǹkankan nípa ẹ̀sùn tí wọ́n ń kà sí òun lọ́rùn.

Dókìtà Femi Olaleye tí wọ́n fi ẹ̀sùn ìfipá bánilòpọ̀ kàn kọ̀ láti yọjú sílé ẹjọ́

Ṣaaju ni a ti mu iroyin wa pe igbẹjọ dokita onimọ iṣegun oyinbo, Femi Olalaye, ti wọn fi ẹsun kan pe o fi ipa ba ọmọ aburo iyawo rẹ lopọ nipinlẹ eko, ko waye.

Ọjọ Aje, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kọkanla, lo yẹ ki Dokita Olaleye farahan niwaju Onidajo Rahmon Oshodi, ti ile ẹjọ to n gbọ ẹsun ifipabanilopọ, ni agbegbe Ikeja, amọ ko yju sile ẹjọ.

Ileeṣẹ ofin ijọba ipinlẹ Eko lo gbe dokita naa lọ sile ẹjọ, fun pe o fi ipa ba ọmọde lopọ fun bi oṣu mọkandinlogun, titi iyawo rẹ fi mọ, to si fi ẹjọ rẹ sun ijọba.

Agbẹjọro agba meji, Babatunde Ogala (SAN) ati Olusegun Fabunmi (SAN) si lo ṣoju rẹ nile ẹjọ.

Ọkan lara wọn, Babatunde Ogala sọ fun ile ẹjọ pe wọn ti gba beeli onibaara oun kuro ni ahamọ ọlọpaa, ati pe o ti rinrinajo.

Bakan naa lo sọ pe ko tii gba iwe ipẹjọ.

“Kii ṣe pe onibaara mi n gbiyanju lati salọ, tabi ko fẹ yọju si ile ẹjọ. O ti lọ si irinajo nigba ti wọn mu lẹta ipẹjọ lọ si ọfiisi rẹ.”

O bẹ ile ẹjọ lati da ọjọ miran fun igbẹjọ rẹ, o si tun ṣe ileri pe oun yoo rii daju pe Dokita Femi Olaleye yọju sile ẹjọ.

Onidajọ Ramon Oshodi ti sun igbẹjọ si ọgbọnjọ, oṣu Kọkanla, ọdun 2022.

Àṣírí tú! Ọwọ́ tẹ Dókítà tó ń bá ọmọ ọdún 15, ìbátan ìyàwó rẹ̀ lòpọ̀ l’Eko

Dokita Femi

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ẹka eto ofin ni ipinlẹ Eko yoo gbe arakunrin ẹni ọdun mẹtadinlọgọta kan to jẹ Dokita lọ sile ẹjọ lonii ọjọ Aje fun ẹsun ṣiṣe ọmọ ọdun mẹẹdogun kan to jẹ ọmọ ibatan iyawo rẹ baṣubaṣu.

̀Dokita Femi Olaleye ni iroyin ni o jẹ onimọ iṣegun oyinbo ni ile iwosan Optimal Cancer Care Fundation ni ipinlẹ eko ti wọn si ni yoo farahan ni ile ẹjọ to n gbọ ẹsun to ni ṣe pẹlu ibalopọ ati iwa ipa ninu ile eyi to wa ni agbegbe Ikeja nipinlẹ Eko.

Eyi hande ninu atẹjade ti adari ẹka ijọba ipinlẹ Eko to n ri si irufẹ iwa aburu yii ti Ọgbẹni Oluwagbenga Alagbe fọwọ si to si fi ṣọwọ si awọn oniroyin lọjọ Aiku.

Ile ẹjọ

Oríṣun àwòrán, OTHERS

O ni “Olaleye yoo maa koju ẹsun meji ọtọọtọ to ni ṣe pẹlu ṣiṣe eeyan baṣubaṣu ati ifipabanilopọ nipa kiki nkan ọmọkunrin wọ oju ara obinrin.

“O gbudọ foju ba ile ẹjọ ki oun naa si gba agbẹjọro to ba wu u fun ara rẹ,” alagbe sọ bẹẹ.

Bakan naa ni agbẹjọro ni wọn ti tẹ ẹda awọn iwe aridaju naa ti wọn si ti fi ṣọwọ si afurasi ọhun lati mọ pe o lẹjọ ro niwaju adajọ.

Ẹka ijọba ipinlẹ Eko to n moju to ẹjọ iwa ipa ninu ile tabi nipa ibalopọ ti tọwọ bọ igbẹjọ naa fun iwadii ẹkunrẹrẹ ati pe lẹyin iwadii naa, ẹka ile iṣẹ ijọba naa tun fẹnu sii pẹlu imọran pe wọn gbudọ fi dokita naa jofin.