Ọwọ́ agbófinró tẹ bàbá tó fipá bá ọmọ rẹ, ọmọ ọdún mọ́kànlá lòpọ̀ nílùú Ibadan

Aworan

Oríṣun àwòrán, NSCDC

Awọn afurasi afipabanilopọ meji lo n bẹ ni atimọle ajọ ẹṣọ aabo ara ẹni l’aabo ilu, NSCDC, ẹka ti ipinlẹ Ọyọ lọwọlọwọ bayii, lori ẹsun wi pe wọn fi ipa ba awọn ọmọdebinrin meji lopọ.

Alukoro ajọ NSCDC n’ipinlẹ Ọyọ, DSC Oyindamola Okuneye pe orukọ awọn afurasi naa ni, Tunde Kareem ti o jẹ ẹni ọdun mẹtalelọgbọn, ati Amos Micheal tii ṣe ẹni ọdun mẹrindinlaadọta.

Gẹgẹ bi Okuneye ṣe sọ, Tunde Kareem ni wọn fi ẹsun kan wi pe o fi ipa ba ọmọbinrin rẹ, ọmọ ọdun mọkanla lopọ, ti o si jẹwọ wi pe ẹẹkan pere ni oun ṣe aṣemaṣe naa ki kele ofin to gbee lọjọ kẹtadinlogun oṣu kini ọdun yii.

Afurasi keji, Amos Micheal ni wọn fi ẹsun kan wi pe o fi ipa ba ọmọ ọdun mẹwaa kan lopọ lọjọ kẹẹdogun oṣu kini ọdun yii, lẹyin ti o fi alupupu tan an lọ si ọna ti awọn eeyan kii fi bẹẹ rin ni agbegbe kan, ti o si fi ika ja ibale ọmọ naa.

Amos ni wọn sọ pe o jẹ oju ti ọpọ eeyan damọ ni ṣọọbu ti iya ọmọ ọdun mẹwaa naa ti n ta agbo, ti o si gba ibẹ sunmọ ọmọbinrin naa.

Ni bayii, awọn afurasi mejeeji ti jẹwọ wi pe awọn jẹbi ẹsun naa. Bẹẹ sini ajọ NSCDC ti ṣe alaye wi pe awọn afurasi naa yoo mu oju ba ile ẹjọ lẹyin ti wọn ba pari iṣẹ iwadii wọn.

Saaju ni adari ajọ naa n’ipinlẹ Ọyọ, Michael Adaralewa fi ọrọ lede wi pe ajọ naa ko ni fi aye gba aṣilo awọn ọmọde, gẹgẹ bi o ṣe n fi aabo to peye bo awọn ọmọbinrin.