Bí ìbò 2023 ṣe ṣúnmọ́lé, wo ohun tó yeͅ kó o mòͅ nípa rẹ̀

Aworan

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Osu to n boͅ ni awoͅn oͅmoͅ Naijiria yoo tu yaya jade lati loͅ dibo fun eͅni ti woͅn yan laayo geͅgeͅ bi aareͅ tuntun lorileͅede Naijiria.

Eyi n waye lasiko tie to aabo deͅnukoͅleͅ ti oͅroͅ aje ko sig be peͅeͅli soke ti awoͅn eniyan si n pariwo ilu ko roͅgboͅ.

Ibeere ti awoͅn eniyan n beere ni pe se awoͅn oludije yii yoo le mu igba oͅtun de ba orileͅede Niajiria bayii?

Bi o tileͅ jeͅ pe aareͅ Muhammadu Buhari to ti wa lori aleefa fun oͅdun meje salaye fun awoͅn oͅmoͅ Naijiria wi pe oun ti sa gbogbo ipa oun, ti oun si ti se iwoͅn ti oun le sͅe.

Bakan naa ni awoͅn alatileͅyin reͅ ni o mu igba oͅtun de ba awoͅn ileesͅe nla nla lorileͅede Naijiria, to si fi opin si iwa igbesunmoͅmi ikoͅ Boko Haram lasiko rwͅ

Amoͅ iyawo aareͅ, Aisha Buhari fun ara reͅ gbagboͅ wi pe nkan nira fun awoͅn oͅmoͅ Naijiria to si toͅroͅ aforiji ni oͅwoͅ woͅn.

Nitori naa afojusun wa wi pe eͅnikeͅni to ba bori ninu idibo naa yoo ni isͅeͅ pupoͅ lati se

Igba wo ni eto idibo yoo waye?

Oͅjͅoͅ  Karundinloͅgboͅn, osu keji, oͅdun 2023 ni idibo sipo aareͅ yoo waye.

 Amoͅ ti ko ba si eͅni to jawe olubori to lamilaaka  laarin gbogbo awoͅn oludije, o sͅeese ki atundi idibo waye laarin oͅseͅ meͅta.

Bakan naa ni idibo sipo gomina yoo maa waye ni Oͅjoͅ Koͅkanla, Osͅu Keͅta, oͅdun 2023.

Eͅweͅ, Ajoͅ eleto idibo, INEC ti kede pe mimi kan ko le yeͅ awoͅn oͅjoͅ idibo naa bio tileͅ jeͅpe eto aabo meͅheͅ ni awoͅn apa ibi kan.

Awoͅn wo lo n dije du ipo aareͅ?

Aworan

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Awoͅn oludije mejidinlogun lo n dije du ipo aareͅ lorileͅede Naijiria.

Amoͅ afojusun wa wi pe awoͅn  meͅta ni woͅn datoͅ ninu awoͅn oludije naa.

Bola Ahmed Tinubu

Bola Ahmed Tinubu to jeͅ eni odun aadoͅrin lo n dije labeͅ eͅgbeͅ oselu APC. Oͅpoͅloͅpoͅ lo moͅ geͅgeͅ bi baba isaleͅ fun awoͅn olosͅelu ni iha iwoͅ oorun orileͅede Naijiria.

Tinubu ni woͅn ti fi eͅsun kan titi di oni pe o wu iwa ajeͅbanu ati pe ilera reͅ deͅnu koͅleͅ, ti ko si yeͅ lati dije du ipo aareͅ.

Bakan naa ni woͅn tun bu eͅnu ateͅ lu bi o se soͅ pe ‘’Emi lokan’’ eleyii ti awoͅn eniyan kan ni o soͅ ipo aareͅ di oye idile reͅ.

Atiku Abubakar

Atiku Abubakar to jeͅ eͅni oͅdun meͅrindinloͅgoͅrin ni oun dije labeͅ eͅgbeͅ osͅelu PDP.

Eͅleͅkarun ree ti yoo dije du ipo aareͅ lorileͅede Naijiria to si kuna ni gbogbo igba marun un naa.

Atiku ti fi gbogbo aye reͅ wa nipo agbara lati ileesͅeͅ to n risi oͅroͅ ibode ni Niajiria, to fi di igbakeji aarͅ orileͅede Niajiria labeͅ Oluseͅgun Obasanjo to fi di ogbontagiri onisͅowo.

Bi Tinubu, woͅn ti fi eͅsun iwa magomago ati ajeͅbanu kan an ni oͅpoͅ igba.

Peter Obi

Peter Obi to jeͅ eͅni oͅdun moͅkanleloͅgoͅta lo n dije du ipo aareͅ labeͅ eͅgbeͅ oselu Labour Party.

Eͅrongba reͅ ni lati ri pe opin de ba eͅgbeͅ oselu mejeeji to ti n dari orileͅede Naijiria lati oͅdun ba oͅdun sͅeͅyin.

Bio tileͅ jeͅpe eͅgbeͅ oselu PDP lo wa titi di oͅdun to koͅja, oun ni awoͅn eniyan ri geͅgeͅ bi olugbala woͅn ninu eto idibo to n boͅ naa.

O ti fi igba kan jeͅ gomina ipinleͅ Anambra laarin oͅdun 2006 si 2014, ti awoͅn alatileͅyin reͅ si n pe ara woͅn ni ‘Obidient’.

Awoͅn alatileͅyin reͅ ri geͅgeͅ bi eͅni kan to yatoͅ laarin awoͅn olosͅelu naa, amoͅ awoͅn alatako reͅ ni ko le de ibi Kankan.

Talo sͅeesͅe ko jawe olubori ninu eto idibo to n boͅ?

Awoͅn onwoye ni o see ki aareͅ tuntun lorileͅede Naijiria wa lati inu eͅgbeͅ oselu APC tabi PDP.

Amoͅ awoͅn oͅdoͅ to feͅran Obi ni ti awoͅn oͅdoͅ ba sͅe atileͅyin fun daradara, o sͅeesͅe ko jawe olubori.

Bawo ni idibo naa yoo sͅe loͅ?

Eͅni ti yoo jawe olubori geͅgeͅ bi aareͅ gboͅdoͅ naa peͅlu ida meji ninu ida meͅta idibo awoͅn araalu kaakiri orileͅede Naijiria.

Ti ko ba si eͅni to jawe olubori to lamilaaka bayoii, woͅn gboͅdoͅ tun ibo naa di laarin awoͅn oludije meji to le tente ninu eto idibo naa laaarin oͅjoͅ moͅkanlelogun.

Ki ni awon ipenija to wa nileͅ loͅwoͅloͅwoͅ?

Lara ipenija to n koju awoͅn oͅmoͅ Naijiria ni eto aabo to meͅheͅ kaakiri lai fi apa ibi kan sileͅ.

Paapaa ijinigbe ti da ohun to n sͅeͅleͅ lemoͅlemoͅ kaakiri ilu, ti awoͅn ikoͅ Boko Haram naa sͅI n sͅoͅsͅeͅ ni ariwa orileͅede Naijiria.

Lara awoͅn isͅeͅleͅ to waye ni oͅdun to koͅja ni ikoͅlu awoͅn agbeboͅn si ijͅ Catholic Mimoͅ ni ilu Owo, nipinleͅ Ondo.

Bakan naa ni awoͅn agbeboͅn sͅe ikoͅlu si oͅkoͅ oju irin Abuja si Kaduna ti woͅn si pa oͅpoͅloͅpoͅ awoͅn eniyan lasiko oͅhun.

Bio tileͅ jeͅpe aareͅ Buhari ni ohun ti gbiyanju lori eto aabo, amoͅ awoͅn oͅmoͅ Naijiria ni nkan ko I tii roͅgboͅ.

Ọrọ aje dẹnu kọlẹ, igbe aye nira fọmọ Naijiria

Ohun miran to tun n ba awoͅn oͅmoͅ Naijiria ninu jeͅ ni eto oͅroͅ aje to deͅnukoͅle, ti igbe aye nira fun awoͅn eniyan nitori oͅwoͅngogo ounjeͅ ati ile gbigbe.

Bakan naa ni ko si isͅeͅ to yanju fun awoͅn oͅmoͅ Naijiria nitori bi oͅpoͅloͅpoͅ tileͅ loͅ si ileeͅkoͅ, ko si isͅeͅ to yanju fun woͅn lati sͅe.

O kere tan eniyan meͅrin ninu meͅwaa awoͅn oͅmoͅ Naijiria ni ko ni anfaani si eto igbayegbadun to fi moͅ ina oͅba, ile gbigbe, omi to moͅ geere ati ayika to moͅ tonitoni.

Pupoͅ ninu awoͅn oludije yii ni woͅn ti sͅeleri lati bojuto awoͅn ipenija to n koju awoͅn oͅmoͅ Naijiria.

Aworan

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Se idibo naa ko ni ni magomago ninu?

Ni awoͅn idibo to koͅja lorileͅede Naijiria ni awoͅn oloselu ti  ma n se magomago lasiko idibo.

Ohun ti awoͅn oloselu yii ma n se nigba miran ni ki woͅn ji apoti idibo, tabi ki woͅn da rogbodiyan sileͅ lasiko idibo ti awoͅn oludibo yoo fi saloͅ.

Bakan naa ni awoͅn oloselu ma n ra ibo awoͅn eniyan, ti woͅn a si fun woͅn ni ibi ti woͅn ba ti n dibo, eleyii ti woͅn n pe ni dibo ki o se oͅbeͅ.

Amoͅ Ajoͅ Eleto idibo INEC ni awoͅn yoo lo oͅna igbalode lati ri pe ko si magomago ninu idibo ti yoo waye naa.

Bakan naa ni igbeseͅ ti banki apapoͅ Naijiria gbe lati mu atunsͅe bao wo Naira yoo kan an nipa fun awoͅn eniyan ti woͅn ba ko owo pamoͅ si ile lati ko jade.

Saaju idibo naa ni awoͅn kan ti sekoͅlu si ileesͅeͅ INEC koͅoͅkan, ti woͅn sapejuwe geͅgeͅ bi ohun to b ani ninu jeͅ.

Ajoͅ INEC tun kede e awoͅn miran n se magomago nipa lilo oͅmoͅde lati fi orukoͅ sileͅ fun eto idibo.

Bakan naa ni woͅn tun ri pe awoͅn miran fi orukoͅ sileͅ ju eͅeͅkan loͅ nipa yiyi oju woͅn pada ati asͅoͅ woͅn.

Amoͅ INEC kede ni Oͅjoͅ Koͅkanla, Osu Kini, oͅdun 2023 pe awoͅn ti sawari awoͅn to je iforukoͅ sileͅ loͅna eͅburu, ti woͅn si ni eͅnikeͅni ti oͅwoͅ ba teͅ yoo fi oju wina ofin.

Awoͅn idibo miran wo ni yoo waye?

Yatoͅ si idibo sipo aareͅ ti yoo maa waye, awoͅn idibo miran ti yoo maa waye ni idibo sipo asͅojusͅofin ni ile igbimoͅ asͅojusͅofin ati ile asͅofin labeͅle.

Awoͅn  asͅofin 469 ni woͅn yoo ma dibo  yan si ile asͅofin agba ati kekere.

Leͅyin oͅseͅ meji ni awoͅn oludibo yoo tun tuyaya jade lati dibo yan gomina ati awoͅn asͅojusofin si ipinleͅ medidinloͅgboͅn ninu meͅrindinloͅgoͅrin naa.