Ọ̀run yóò ya bọ́ tí ààrẹ kò bá wá láti ẹ̀kùn gúúsù Nàíjíríà – Joe Igbokwe

Awọn agbaagba Arewa

Oríṣun àwòrán, State House

Eekan kan ninu ẹgbẹ oselu APC, Joe Igbokwe ti tutọ soke, fi oju gba a lori ikede kan ti awọn agbaagba lẹkun ariwa naijiria fisita lori ẹni ti yoo rọpo aarẹ Muhammadu Buhari.

Ẹgbẹ awọn agbaagba ni Ariwa ilẹ yii lo kede ni Ọjọru pe ko si ohun to buru ninu ki aarẹ ti yoo rọpo Buhari tun wa lati ẹkun ariwa orilẹede yii.

Baba Ahmed, tii se agbẹnusọ fun ẹgbẹ awọn agbaagba naa fikun pe ẹkun ariwa Naijiria ko tii setan lati gbe ipo agbara silẹ lọdun 2023.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O wa gba awọn eeyan ti igbesẹ naa ko ba tẹ lọrun niyanju lati fi Naijiria fun awọn.

Amọ nigba to n fesi lori ọrọ yii, Igbokwe ni ọrun yoo ya bọ silẹ, ti ohun buruku yoo si maa ja lu ohun buruku, ti eeyan miran lati apa ariwa Naijiria ba tun rọpo aarẹ Buhari.

Igbokwe, ẹni to fi ọrọ naa lede loju opo ayelujara rẹ ni oun gbọ ohun ti Baba Ahmed sọ o amọ ọrun yoo bọ silẹ o.

Ọpọ ọmọ Naijiria si lo ti dara pọ lati maa tako ohun ti ẹgbẹ awọn agbagba Arewa sọ naa, tawọn gomina ẹkun guusu Naijiria naa si ti fun lesi pada pe awada akọ lasan lo n se.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Amin iyasọtọ kan

UK gba 8,737 Dókítà láti Nàíjíríà síṣẹ́ láàrin ọdún kan

Awọn dokita to n sisẹ

Oríṣun àwòrán, UCH

O kere tan, awọn dokita onisegun oyinbo bii ọtalelọọdunrun o din meje (253) ni wọn ti fi orukọ silẹ laarin ọgọrun ọjọ lati sisẹ pẹlu ijọba ilẹ United Kingdom.

Gẹgẹ bi oju opo itakun agbaye fun ajọ to n se akoso isẹ isegun nilẹ UK, to maa n fawọn dokita niwe asẹ lati sisẹ ti kede rẹ.

Laarin ọjọ Kẹwa osu Kẹfa si ogunjọ osu Kẹsan ọdun 2021, dokita ọmọ Naijiria bii ọtalelọọdunrun o din meje lo ti gba iwe asẹ lati sisẹ nilẹ naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bakan naa, gẹgẹ bi iwe Punch ti salaye, laarin osu keje ọdun 2020 si osu Kẹsan ọdun 2021, awọn dokita to to ọtalelẹgbẹrin ati meji (862) lo ti gba iwe asẹ lati sisẹ ni UK lai naani arun Coronavirus to gbilẹ nibẹ nigba naa.

Lọwọ lọwọ bayii, dokita bii ẹgbẹrun mẹjọ ati ọrinlelẹẹdẹgbẹrin o din mẹta (8,737) ti wọn gba idanilẹkọ nipa isẹ dokita lorilẹede Naijiria, lo ti n sisẹ nilẹ UK.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Nigba to n ba iwe iroyin naa sọrọ, igbakeji aarẹ ẹgbẹ awọn dokita to n gba imọ kun imọ ni Naijiria, Julian Ojebo ni o seese ki alekun ba bi awọn dokita se n lọ soke okun laarin ọsẹ melo kan si.

Ojebo ni ti ijọba ko ba san owo osu ati ajẹmọnu to yẹ fawọn onisegun oyinbo naa, o seese ki iye awọn ti yoo gba orilẹede Saudi Arabia lọ gan ju ti UK lọ.

O fikun pe o se ni laanu pe ijọba kuna lati wa ojutu si ohun tawọn dokita naa n beere fun lati ọjọ Kinni osu Kẹjọ ọdun 2021 ti wọn ti bẹrẹ iyansẹlodi.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ