Wo èèwọ̀ mẹ́wàá to fi lè bọ́ lọ́wọ́ ewu iná gáàsì

Obinrin to n da ina gaasi

Oríṣun àwòrán, Shutterstock

Fífi afẹfẹ gaasi dana ko fi akoko ṣofo rara, o ya ju dida ina igi tabi sitoofu lọ, kii si jẹ kí ikoko idana dudu.

Bi fifi afẹfẹ gaasi dana ṣe ni anfani to pọ yii naa lo ni ewu ninu.

Ọpọ eeyan ni afẹfẹ gaasi idana ti ṣe leṣe, ti ara wọn bo yanna yanna, nigba ti awọn miran dero ọrun.

Nitori idi eyi, ọpọ eeyan ni ẹru maa n ba lati lo afẹfẹ idana naa, paapaa awọn eeyan to ba ni ọmọde ninu ile.

Amọ ọna abayọ ti wa lati dena ewu to wa ninu lilo afẹfẹ gaasi lati dana ninu ile, awọn ọna mẹwaa yii si le wulo fun ọ.

Eewọ mẹwa ti o gbọdọ sa fun to ba n lo afẹfẹ gaasi lati dana:

Dẹkun lilo foonu nile idana:

Lilo foonu ni yara idana le jẹ kí ounjẹ jona lori ina.

O sí tun léwu fún gaasi fun rẹ nitori ile le sẹ yọ mọ ọ lara ti foonu naa ba gbina.

Ma ṣe jẹ ki ẹrọ panapana rẹ jina sí ile idana rẹ:

Ri daju wí pé ẹrọ iyẹfun eroja panapana rẹ wà ninu ile idana rẹ nitori ijamba ina to le ṣẹlẹ nigba kugba.

Eyi ni yoo tete dena ijamba ina ko to pẹ ju tabi ran mọ inu ile, eyi to le mu ofo ẹmi ati dukia wa.

Ma ṣe jẹ kí gaasi rẹ kun ju bo ti yẹ lọ:

Ewu wa ninu ki gaasi ku ju bo ti yẹ lọ nitori o le bẹrẹ sí ní jo.

Ti o ba si ti n jo, ijamba ina le ṣẹlẹ nigba kugba.

Ma ṣe mi silinda gaasi wo:

Ọpọ eeyan lo máa n mi silinda gaasi wọn wo lati mọ boya gaasi ṣi ku níbẹ.

Mimi silinda gaasi le jẹ ko bù gbamu eleyii to mu ewu lọwọ, to si le tun mu ẹmi lọ pẹlu.

Bakan naa ta ba lọ ra gaasi, ẹ ma gbe silinda yin si ẹyin ọkọ amọ ẹ gbe sinu ọkọ, ko maa baa maa yi kiri, eyi to le mu ewu lọwọ.

Rii wi pe o wọ aṣọ sara ti o ba n lo gaasi idana:

Nigba kugba ti o ba n lo gaasi, ri pe o wọ aṣọ ti o bo gbogbo ara rẹ tan.

Eyi jẹ ọna lati bọ lọwọ ewu ina aibaamọ gaasi naa le gbina, ti onitọun yoo si tete bọ asọ danu to ba gba mọ eeyan lara.

Ma se duro pẹ nile idana:

Awọn kẹmika to lagbara kan máa jade lati ara gaasi idana ti ko yẹ ko máa wọ inu ara eeyan.

Nitori naa, maṣe duro pẹ ju ni yara idana.

Kẹ́míkà gaasi le fa ẹfọri, ooyi kikọ ati èébì fún ọ.

Ma ṣe yin gaasi rẹ soke patapata:

Ni ọpọ igba láwọn eeyan máa n yin gaasi idana soke patapata.

Eleyii ni ewu ninu, ko yẹ ki ina gaasi jó kọja idi ikoko idana.

Ma ṣe dagunla sí gaasi to n jò:

Ti o bá ṣe akiyesi pe “cylinder” gaasi n jo, yara ṣi ilẹkùn ati ferese ile idana silẹ ni kiakia.

Ti oorun gaasi naa ba n pọ si, kuro nilu ile ki o sí kepè awọn tó mọ nipa gaasi fún iranwọ.

Ma gbe oriṣiriṣi nkan sun mọ “cylinder” gaasi:

Awọn nnkan eelo idana atawon nkan mii ko gbọdọ wa lori gaasi ni yara idana.

Ma se di ọpọ ẹru sori awọn silinda naa nitori o lewu.

Ma lo gaasi idana rẹ ti erunrun ounjẹ ba ti da sori rẹ:

Ki o to bẹrẹ sí ní maa lo gaasi idana rẹ, ríi pe kò sì idọti ounjẹ kankan lori gaasi.

Bi bẹẹ kọ, iru nkan yii ni yóò máa jo, ti yóò sì bẹrẹ sí ní maa run.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: