Ọ̀pọ̀ àwọn tó fẹ́ ràn mí lọ́wọ́ ló fi ìlọ̀kulọ̀ lọ̀ mí, àyàfi Dudu Heritage nìkan

Sola Allyson

Oríṣun àwòrán, thesolaallyson

Gbajugbaja akọrin ẹmi, Sola Allyson ti darapọ mọ awọn ọmọ Naijiria to n ṣe idaro iku ọkọ Bimbo Oshin, iyẹn Ola Ibironke, ti ọpọ eeyan mọ si Dudu Heritage.

Ninu atẹjade kan to fi lede loju opo Instagram rẹ lo ti ṣedaro oloogbe ọhun.

Sola sọ pe ọpẹlọpẹ Dudu Heritage ninu aye oun, ko ba si ẹni to n jẹ Sola Allyson lonii.

Akọrin ẹmi naa ṣalaye pe Dudu Heriage lo sọ ohun di gbajumọ lẹyin to gbe awo orin oun, “Eji Ewuro” jade lọdun naa lọhun.

O ni “Lẹyin ti mo wo ẹyin wo, o han gbangba pe eto Ọlọrun ni bi mo ṣe pade oloogbe naa.”

Ọrọ idaro ti Sola Allyson sọ nipa Dudu Heritage

Oríṣun àwòrán, thesolaallyson/Instagram

“Lootọ ni mo ti n kọrin nigba naa fun nnkan bii ọdun marundinlogun, ṣugbọn aye ti su mi, nitori nnkan ko lọ bo ṣe yẹ ko maa lọ.”

“Mo pade Lanre to n ṣiṣẹ fun oloogbe nigba naa ninu ọkọ akero lati agbegbe Obalende si Ogba… wọn si fun ni iṣẹ lati kọ orin to wa ninu fiimu agbelewo Eji Ewuro, eyi ti Bimbo Oshin gbe jade.”

Lootọ o wu mi ki n kopa ninu fiimu naa gẹgẹ bii oṣere, ṣugbọn wọn ni orin ni mo maa kọ.

Lẹyin ti mo kọ orin naa, ni Dudu Heritage sọ pe mo gbọdọ ṣe orin ọhun sinu awo ti awọn eeyan yoo maa gbọ laaye ara wọn.

Lati igba naa wa ni irawọ mi ti tan.”

Sola sọ siwaju si pe, bo tilẹ jẹ pe awọn alabaṣiṣẹ Dudu Heritage ko fọwọ si igbesẹ naa, ṣugbọn o kọ si wọn lẹnu, o si ti oun lẹyin titi ti oun fi di ẹni ti aye n gbọ lonii.

Ọrọ idaro ti Sola Allyson sọ nipa Dudu Heritage

Oríṣun àwòrán, thesolaallyson/Instagram

Gẹgẹ bii ohun ti Sola sọ, ọpọ awọn to gbiyanju lati ran oun lọwọ lasiko naa lo n fi ilọkulọ lọ oun, ṣugbọn ti Dudu Hertiage yatọ.

O ni “Ẹyin nikan ni ko fi ilọkulọ lọ mi bi awọn akẹgbẹ yin miran ṣe n ṣe, eyi to mu ki n yago fun wọn, eyi si jẹ ki n bu iyi fun yin pupọ.”

“Ọlọrun lo yin lati jẹ ki irawọ mi buyọ, ti ọpọ eeyan si mọ mi si Sola Allyson, Eji Owuro lonii… mi o le gbagbe yin lailai.”

Sola Allyson pari idaro naa pẹlu adura pe, ki Ọlọrun jẹ ki oloogbe naa ri aanu gba, lẹyin naa lo ni oun ko ni gbagbe oore ti Dudu Heritage se ninu aye oun titi lai.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ