Wo àwọn tí kò ní san owó orí tuntun 0.5% táwọn báńkì fẹ́ máa yọ lórí àwọn oníbàárà wọn

Aworan owo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ni ọjọ Aje ọjọ kẹfa oṣu karun un yii ni banki apapọ Naijiria, CBN kede pe awọn ile ifowopamọsi jakejado Naijiria yoo bẹrẹ si nii gba owo ida ninu ida ọgọrun gẹgẹ bi owo abo ori ayelujara fun gbogbo isanwo ori ayelujara ti ẹnikẹni ba ṣe lorilẹede Naijiria.

Lati igba ti CBN ti ṣe ikede yii lawọn eeyan ti n fi aidunnu wọn han lori igbesẹ ijọba yii.

Bi ọsẹ meji si akoko yii ni awọn ni banki apapọ CBN sọ pe awọn ile ifowopamọ yoo bẹrẹ si ni yọ owo yii lori awọn onibara wọn.

Amọ, banki papọ Naijiria ti ṣalaye pe awọn kan wa ti sisan owo ori tuntun yii ko ni kan rara.

Wọnyi ni awọn ti ko ni san owo ori tuntun 0.5% ti banki fẹ maa yọ lori awọn onibara

  • Awọn ile ifowopamọ ko ni yọ owo ori tuntun 0.5% yii ninu akaunti ti wọn fi ya owo tabi ti eeyan fi n san gbese pada.
  • Banki apapọ CBN tun sọ pe awọn ko ni yọ owo ori yii ninu owo oṣu awọn eeyan.
  • Ti o ba n fi owo ranṣẹ lati akaunti rẹ kan si omiran yala ni banki kan naa tabi si banki mii, ile ifowopamọ ko ni yọ owo rẹ.
  • Awọn to n fi owo ranṣẹ si ara wọn ni banki kan naa ko ni maa san owo ori tuntun yii.
  • Ijọba ko ni yọ owo ori yii ninu owo ti awọn banki ba fi ranṣẹ si banki apapọ CBN tabi owo ti CBN ba fi ranṣẹ si awọn ile ifowopamọ.
  • Fifi owo ranṣẹ lati banki kan si omiran naa ko ni ṣe pẹlu sisan owo ori tuntun yii bakan naa.
  • Ijọba ko ni yọ owo ori tuntun yii ninu akaunti ti o ba kowo pamọ si tabi akaunti ti o ba fi dokowo bi eto adojutofo.
  • CBN ko tun ni maa yọ owo ori yii ninu akaunti owo ifẹyinti awọn oṣiṣẹ.
  • Bakan naa, awọn ajọ to n ṣe iranwọ fun araalu ko ni maa san owo ori tuntun yii.
  • Awọn akẹkọọ ko ni maa san owo yii nigba ti wọn ba san owo ile iwe tabi owo mii lẹnu ẹkọ wọn.

Wo bí owó orí tuntun tí Báǹkì àpapọ̀ Nàìjíríà gbé kalẹ̀ fun gbígbógbunti ìwà ọdaràn orí ayélujára ṣe kàn ọ́

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn ile ifowopamọsi jakejado Naijiria yoo bẹrẹ si nii gba owo ida 0.5 ninu ọgọrun gẹgẹ bi owo abo ori ayelujara fun gbogbo isanwo ori ayelujara ti ẹnikẹni ba ṣe lorilẹede Naijiria.

Banki apapọ Naijiria, CBN lo gbe aṣẹ tuntun yii kalẹ lọjọ Aje ninu atẹjade kan ti oludari eto isanwo ni Banki apapọ naa, Chibuzor Efobi ati oludari amojuto ilana iṣuna, Haruna Mustapha fọwọsi.

Atẹjade naa sọ pe “yiyọ ati gbigba owo abo lọwọ fitina ori ayelujara naa wa ni ibamu pẹlu ofin to de gbigbogun ti iwa ipa ori ayelujara tọdun 2024”.

Banki apapọ Naijiria sọ pe ofin naa laa kalẹ ni ẹsẹ keji abala ikẹrinlelogoji rẹ pe “owo ori “yoo maa lọ sinu aṣuwọn ẹdawo fun gbigbogun ti iwa ipa ori ayelujara (NCF), eyi ti ọfiisi alamojuto eto abo lorilẹede Naijiria, (ONSA) yoo maa mojuto.”

Banki apapọ CBN ṣalaye pe kii ṣe pe aṣẹ yii ṣẹṣẹ jade, wọn ti kọkọ kọ iwe kan sita ni ọjọ karundinlọgbọn oṣu kẹfa ọdun 2018 ati ọjọ karun un oṣu kẹwaa ọdun 2018 lori titẹle ilakalẹ ofin to gbogun ti iwa ipa ori ayelujara ti ọdun 2015.

Bawo ni yiyọ owo yii yoo ṣe kan ọ lara si?

Pẹlu owo ori tuntun yii, o fihan pe bi eeyan ba fi ẹgbẹrun kan Naira ranṣẹ lori ayelujara, naira marun un ni wọn yoo yọ ninu rẹ.

Bi o ba fi ẹgbẹrun mẹwa Naira ranṣẹ, aadọta Naira ni wọn yoo yọ.

Bi o ba fi ẹgbẹrun lọna ọgọrun Naira ranṣẹ, ẹẹdẹgbẹta Naira ni wọn yoo yọ.

Bi eeyan ba fi miliọnu kan naira ranṣẹ, ẹgbẹrun marun ni wọn yoo yọ marun un naira ni wọn yoo yọ gẹgẹbi owo ori fun gbigbogun ti iwa ipa ori ayelujara ati bẹẹbẹẹlọ.

Skip Twitter post

Allow Twitter content?

This article contains content provided by Twitter. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Twitter cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose ‘accept and continue’.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Twitter post

Content is not available

View content on TwitterBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

Ki ni awọn ilana ifoworanṣẹ to bọ lọwọ owo ori tuntun yii?

Owo ori tuntun yii ko kan owo owo ti eniyan ba ya tabi bi eeyan ba fẹ san owo yiya pada. Bi banki ya ọ lowo, wọn ko lẹtọ lati yọ owo ori tuntun yii.

Owo oṣu sisan: Owo ori yii ko kan sisan owo oṣu oṣiṣẹ.

Bi o ba n san owo lati aṣuwọn kan si ikeji ninu banki kan naa, wọn ko le yọ owo ori tuntun yii.

Bakan naa to ba jẹ pe lati aṣuwọn banki kan si aṣuwọn miran to wa labẹ banki yii kan naa, wọn ko le yọ owo ori yii.

Ki ni ijọba fẹ fi owo yii ṣe?

Gẹgẹ bi atẹjade ti banki apapọ Naijiria, CBN fi sita, gbogbo awọn banki ni yoo wa san owo yii lodindi si aṣuwọn ẹdawo fun gbigbogun ti iwa ipa ori ayelujara, (NCF) to wa ni Banki apapọ Naijiria.

Ni ọjọ Ẹti to ba jẹ ọjọ karun un ọjọ iṣẹ oṣu to ba tẹle ti oṣu ti wọn ti gba ni wọn yoo maa san owo yii sinu aṣuwọn naa.