“Màálù tó ya sójú pópó kọlu ọ̀kadà ọmọ mí, tó sì kú ní ìkómọ ọmọ rẹ ku ọ̀la”

Aya oloogbe

Iyalẹnu lo jẹ nigbati ọkunrin ẹni ọgbọn ọdun kan, Benjamin Oyelade, se alabapade iku ojiji nitori bi maa lu se ya soju popo lasiko to n gun ọkada kọja ni agbegbe Atapa Ogbomoso ni ijoba Surulere ni ipinlẹ Oyo.

Bamidele, tii se ẹni ọgbọn ọdun to n sisẹ Kafinta, lo se alabapade iku ojiji nigba to ku ọjọ kan pere ko se ikomọjade ọmọ tuntun ti iyawo rẹ sẹsẹ bi.

Ọkunrin yii ni wọn lo gun ọkada lati lọ ra epo bẹtiroolu, ko to se alabapade iku ojiji naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Isẹlẹ naa lo fa ki awọn ọdọ ilu Atapa fariga, ti wọn si sọ ina si abule tawọn Fulani tẹdo si lati gba ẹsan iku Oyelade, ti awọn agbofinro si ti dasi ọrọ naa.

Nigba ti BBC Yoruba gunlẹ si agbegbe naa lati tanna wadi ohun to sẹlẹ, baba ologbe, Babalola Solomon, to ba ikọ BBC News sọrọ ni ohun iyalẹnu lo jẹ fun oun tori ko pe ọgbọn isẹju ti ọmọ oun kuro ni ọdọ oun, ti isẹlẹ naa fi waye.

O tẹsiwaju pe ọmọ oun fẹ lọ epo pẹtiro si ẹrọ amunawa fun isọmọlorukọ ọmọ rẹ kẹrin lo pade iku ojiji lati ọwọ awọn maalu naa.

Nigba ti BBC kan si aya oloogbe, se lo n wa ẹkun mu pẹlu ara tutu, ti ko si le sọ ọrọ kankan nitori isẹlẹ naa ba lojiji.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ki ni ohun ti awọn Fulani darandaran sọ nipa isẹlẹ naa?

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ,adari awọn Fulani darandaran, Muhammad Umaru ni ko si nkan to jọ bẹẹ rara, ti awọn Fulani ko si mọ nipa isẹlẹ naa.

Umaru ni lootọ ni awọn ọdọ ilu se ikọlu si ibudo awọn, to si rawọ ẹbẹ si wọn lati gba alaafia laaye ninu ilu naa.

Alaga ijọba ibilẹ Surulere gbosuba fun aayan ọlọpaa ati Amotekun lari pa ina laasigbo naa:

Alaga ijọba ibilẹ Surulere, Adegbite Isaiah wa gbe osuba fun awọn agbofinro ati ikọ Amotekun lori bi wọn se fi pẹlẹ-putu yanju laasigbo naa.

Adegbite tun parọwa fun awọn araalu lati fi ifẹ ati alaafia ba ara wọn gbe papọ, ki wọn si ta kete si rogbodiyan.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ